Bukunmi Oluwashina: Àlàyé rèé lórí ohun tó fàá tí òṣèrébìnrin yìí fi ń wa ẹkùn mu

Oríṣun àwòrán, Bukunmi Oluwashina
Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Bukunmi Oluwashina ti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lórí fídíò kan tó fi sórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ méjì sẹ́yìn.
Nínú fídíò ọ̀hún ni Bukunmi ti ń sunkún kíkorò pẹ̀lú àkọ́lé wí pé òun kò gbàgbọ́ wí pé "o ti yaa lọ náà nu."
Fídíò náà ló ti wá mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ òṣèré náà bẹ̀rẹ̀ sí ní pèé lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ohun tó ṣẹlẹ̀ si ní pàtó.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ènìyàn bá wo fídíò náà délẹ̀ yóò ri wí pé àwàdà lásán ni Bukunmi ń ṣe nínú fọ́nrán náà ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ni kò wo fídíò náà kì wọ́n tó máa kàn si nítorí wọ́n rò wí pé aburú kan ṣẹlẹ̀ si ni.
Nítorí charger fóònù tó bá fóònù Bukunmi wá tó bàjẹ́ mà ló fi ń sunkún lórí ayélujára o.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn lo ń kọminú wí pé irú eré bẹ́ẹ̀ ti lágbára jù fún òṣèré náà láti ṣe nítorí gbogbo àwọn nǹkan aburú to ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kọ ọ̀rọ̀ sábẹ́ fídíò náà kò ì tíì mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ tí omi ti ń jábọ́ lójú àwọn láì wí pé nítorí charger lọ fi ń sun ẹkún kíkorò bẹ́ẹ̀ àti wí pé kò dẹ́kun fífi ẹkún bẹ́ẹ̀ ṣe àwàdà mọ́.
Àwọn mìíràn tilẹ̀ ní àwọn ti fẹ́ máa ní ẹ̀jẹ̀ ríru nítorí àwọn ti rí ti òṣèré mìíràn náà tún ti gbé ọ̀rọ̀ ìdágbére sórí ayélujára rẹ̀ láì fi orúkọ ẹni tó papòdà síbẹ̀.
Bukunmi tọrọ àforíjì

Nínú àtẹ̀jáde mìíràn tí Bukunmi fi léde lálẹ́ ọjọ́rú, ogúnjọ́, oṣù kẹrin ló ti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ wí pé títí di àkókò náà ni àwọn ènìyàn ń pe òun láti bèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ si òun
Ó ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò dúró wo fídíò náà kí wọ́n tó máa tan ìròyìn náà ká wí pé òun la ìṣòro kọjá.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ló tilẹ̀ ń bú òun nígbà tí wọ́n mọ wí pé aburú kankan kò ṣe òun.
Bukunmi tẹ̀síwájú àwọn olólùfẹ́ òun mọ̀ wí pé òun máa ń ṣeré púpọ̀ àti wí pé tí òun bá ń ṣeré ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò ní mọ ìyàtọ̀ rẹ̀ sígbà tí òun kò bá ṣeré nítorí yóò jọ òótọ́, èyí sì fi hàn wí pé òṣèré gidi ni òun.

Oríṣun àwòrán, Bukunmi Oluwashina
Ó ní kí wọ́n foríji òun wí pé òun já wọn kulẹ̀.
Àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ náà sì ti fèsì wípé kò ṣọ́ra fún irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ló ti káyà sókè nítorí fọ́nrán náà tí àwọn sì ti fẹ́ ní ẹ̀jẹ̀ rúru.
Àti wí pé ìgbà àkọ́kọ́ kọ̀ nìyí tí àwọn òṣèré máa ń fi irúfẹ́ fídíò bẹ́ẹ̀ sórí ayélujára láti ṣàlàyé ìṣòro tí wọ́n bá ń kojú.
Wọ́n ni fífi irú nnkan bẹ́ẹ̀ ṣe àwàdà le mú kí ènìyàn má kọbi ara sí èyí tó bá jẹ́ òótọ́.

















