Funke Akindele: Bukunmi Oluwasina ní ọ̀kan lára àlá òun ló wá sí ìmúṣẹ

Funke Akindele ati Bunmi Oluwasina

Oríṣun àwòrán, Instagram/funkejenifaakindele/bukunmioluwasina

Yoruba ni inu ẹnu kii dun, ka pa a mọra.

Idi ree ti gbajumọ osere tiata lobinrin kan, Bukunmi Oluwasina fi n se jaginni yodo si oore nla kan to wọle tọọ.

Bukunmi, ẹni ti inu rẹ dun dẹyin lori oore naa, ti ko si le e pa a mọra, lo bọ soju opo Instagram rẹ lati kede nipa ifa to wọle tọ ọ fun araye.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

Ki ni Funke Akindele se fun Bukunmi to fa ariwo?

Bukunmi kọ soju opo ayelujara rẹ naa pe gbju-gbaja osere tiata kan, Funke Akindele ti ransẹ si oun , eyi to mu ki inu oun dun kọja aala.

Bukunmi ni pẹlu isẹ ti Funke Akindele ke si oun yii, o daju pe oun ti se oriire nile aye oun.

Àkọlé fídíò, Ìjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

Osere tiata naa wa sọ fun awọn ololufẹ rẹ naa pe ko le ye wọn idi ti oun fi n fo fayọ lori isẹ toun gba latọdọ Funke Akindele, oloye ni ọrọ naa yoo ye.

Bukunmi tun fikun pe ọkan lara ala ọjọ pipẹ oun, lo wa si imusẹ wẹrẹ yii, to si seese ko jẹ pe osere-binrin naa ti n da ọfun tolo lati kopa ninu ere tiata pẹlu Funke Akindele tii se agba ọjẹ ninu isẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bukunmi Oluwasina, to sẹsẹ se igbeyawo laipẹ yii, wa ke sawọn ololufẹ rẹ, lati ba ke Halleluyah, nitori oun n jo kiri inu ile ni pẹlu isẹ ayọ ti oun gba naa lọdọ Funke.

Bi o tilẹ jẹ pe ko sẹni to le sọ iru isẹ ti Funkẹ ran si ọdọmọbinrin osere tiata naa to fi n fo fayọ, sibẹ, Bukunmi naa ko se alaye iru oore to jẹ ninu ọrọ rẹ.

Bukunmi Oluwasina

Oríṣun àwòrán, Instagram/bukunmioluwasina

Sugbọn ọpọ eeyan lo n kede pe, ifa to wọle tọ Bukunmi yii ko lee kọja pe Funke Akindele ke si lati wa kopa ninu isẹ tiata kan, eyi to le mu owo nla wọle fun.

Wayi o, awọn ololufẹ Bukunmi lo ti n ki ku oriire lori isẹ ti Funke Akindele, ti ọpọ eeyan mọ si Jenifa, ran si ọhun, ti wọn si tun n ba dupẹ lọwọ osere-binrin naa pe o ku ọmọ se.

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, Instagram/funkejenifaakindele

Ọpọ awọn eeyan to ba Bukunmi yọ si lo tun n ke si Jenifa lati ran isẹ ayọ si awọn naa, paapaa lasiko ọdun Keresimesi yii, kawọn pẹlu le maa jo kiri ka inu ile.