Ooni Ile Ife: Ooni Adeyeye Ogunwusi àti Olòrì Naomi gbé Àrẹ̀mọ tuntun wọ ṣọ́ọ̀ṣì

Idile Ooni ni Ṣọọṣi

Oríṣun àwòrán, Ooniadimula

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Latari ayẹyẹ iwuye ọdun marun lori itẹ ti Ọọni Adeyeye Enitan Ogunwusi n ṣe, Kabiyesi ti fi idupẹ kadi ayẹyẹ naa nilẹ pẹlu lilọ si ile ijọsin lọ dupẹ lọwọ Oluwa.

Pataki lara awọn to ba Ojaja II wọ ṣọọṣi ni Arẹmọ tuntun ti Eleduwa ṣẹṣẹ fi jinkii oun ati iyawo rẹ, wolii Naomi iyẹn Arẹmọ Tadenikawo Adesoji Aderemi Ogunwusi.

Idile Ooni ni Ṣọọṣi

Oríṣun àwòrán, Ooniadimula

Ṣe ni ile ijọsin kun amọ pẹlu ofin ijina sira ẹni laarin awọn oloye Ile Ife, awọn ọtọkulu ilu araali Ife ati tẹbi tara to wa ba Kabiyesi ṣe ajọyọ.

Ninu ile ijọsin St Paul's Anglican Church, Ayegbaju, Ile-Ife ni Ọọni ti lọ fi ẹmi imore rẹ han si Oluwa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

"Pẹlu gbogbo ogo si Ọlọrun to ga julọ to mu mi de ibi ti mo de yii lori it awọn baba mi. Mo ba wọn jọsin nile ijọsin atibẹrẹpẹpẹ ẹbi mi, St Paul's Anglican Church, Ayegbaju, Ile-Ife loni lati fi ọpẹ fun Oluwa ati lati kasẹ ayẹyẹ ọdun marun ti mo pe lori itẹ".

Ooni pẹlu olori rẹ ati arẹmọ wọn

Oríṣun àwòrán, adesola_ogunwusi

Laipẹ yii ni wọn gbe Arẹmọ Tadenikawo wọ inu aafin Ile Ife fun igba akọkọ ti wọn si fi oju rẹ han faraye fun igba akọkọ.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

Àrẹ̀mọ Ooni Adeyeye Ogunwusi ti wọ Ààfin Ile Ife fún ìgbà àkọ́kọ́

Ooni pẹlu olori rẹ ati arẹmọ wọn

Oríṣun àwòrán, Ooni Palace

Ọọni ti Ile Ife to tun jẹ Arole Oodua, Ọọni Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọjaja II ti fi oju ọmọ wọn han faraye fun igba akọkọ lọjọ Iṣẹgun ọsẹ.

Ọọni gbe Arẹmọ Tadenikawo Adesoji Aderemi Ogunwusi wọ inu aafin Ile Ife fun igba akọkó.

Awọn AGBA IFE ti Ile Ife lo tẹwọ gba a lati ki i kaabọ eyi ti Obalufẹ ti Ifẹ, Oba Idowu Adediwura, dari wọn.

Awọn oloye miran to wa nibẹ ni awọn MODEWA eyi ti Lowa, Adimula Ife, Oloye Adeola Adeyeye dari, to fi mọ awọn EMESE eyi ti Sarun Oriowo Oyeyemi dari.

Àkọlé fídíò, Ojú mi ti rí lọ́pọ̀ lọpọ̀, àmọ́ mo dúpẹ́ pé mo ti pé ọdún márùn ún lórí oyé- Ooni

Gbogbo wọn pata lo ki Arẹmọ ati iya rẹ, Olori ShilekunOla Ogunwusi (Yeyeluwa), ẹbi, ara ati ojulumọ kaabọ si aafin.

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ