Death During Sex: Àwọn nǹkan mẹ́ta tó le ṣekú pa ọkùnrin lásìkò ìbálòpọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, © ROYALTY-FREE / CORBIS
Lọpọ igba la maa n gbọ iroyin pe ọkunrin tabi obinrin re sọda di ero ọrun lasiko ibalopọ.
Lara ohun to n fa iru iku yi la gbọ pe ailera wa, ailemidaada tabi awọn ipenija ara miran.
Ṣugbọn iwadii awọn onimọ ti n waye lati mọ ohun pato to le ṣokunfa ki eeyan ku lasiko ibalopọ.
Dokita Issa Dahabreh ti ile iwosanTufts Medical Center to wa ni Boston, Amẹrika ri ẹri pe irẹwẹsi ọkan a maa ṣe okunfa iku awọn eeyan lasiko ibalopọ.
O ni lasiko ibalopọ, ibalopọ dabi ere idaraya ti yoo mu ki ara eeyan ji pepe.Fawọn ti kii baa ṣe igbaradi tabi ere idaraya loore koore eyi le mu ki wọn maa kaju oṣunwọn to.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki lo le ṣekun pa ọkunrin lasiko ibalopọ?
1) Lilo oogun ṣaaju ibalopọ
Awọn oogun amarajipepe kan wa tawọn eeyan maa n ra lati lo fun ibalopọ.Ninu wọn ni Viagra wa.
Tohun ti pe awọn dokita sọ pe o le mu ki nkan ọmọ ọkunrin gbera daada, ko yẹ ki eeyan maa lo ni gbogbo igba to ba fẹ ni ibalopọ
Eyi lo mu ki ọpọ awọn ọkunrin to ba ni aisan ọkan (pupọ ni kii mọ pe awọn ni gaan) maa ni ipenija lasiko ibalopọ ti eyi a si maa fa iku fawọn miran ti ọkan wọn ko ba gbe agbara oogun naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun tawọn dokita sọ ni pe ki eeyan lo ẹyọ kan tabilẹti oogun yi ṣaaju ibalopọ ṣugbọn awọn mii maa n lo ju bẹ lọ.

2) Aisan ọkan:
Dr McGinger Ibeneme sọ fun BBC pe nitori ibalopọ a maa mu ki eeyan ṣiṣẹ agbara, eyi le ṣakoba fẹni ba ni aisan kan.
O ni bi kaṣan to n gbe ẹjẹ ko ba lagbara to, ti ẹjẹ baa n gba inu rẹ lasiko ibalopọ, o le dipọ ti eyi yoo si ṣakoba fẹni naa.
O tun fi kun pe isọwọ bi ẹjẹ ṣe n tu gba inu kaṣan lasiko ibalopọ ti wọn n pe ni ''adrenaline rush'' le mu inira wa lasiko ibalopọ.
Koko ọrọ ni pe bi ẹjẹ ba n tu yaya ninu ara pupọ, ti ko ba si atẹgun to n gba inu ẹjẹ naa bo ti ṣe yẹ, eeyan n kọ lẹta si iku ni yẹn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
3) Rọ lapa rọ lẹsẹ:
Dokita Ibeneme sọ pe ti eeyan ba n ni ibalopọ pupọ paapa ẹni to ba ni ifunpa to ga, o le ṣakoba fun un .
Awọn onimọ sọ pe o ṣoro ki eeyan to ba gba ọna yi rọ lapa ko ku ṣugbọn eeyan le rọ lapa nipa ibalopọ.
- Wo àwọn oúnjẹ márùn ún tó ń mú kí àtọ̀ ọkùnrin dára síi
- Wo ibi mẹ́rìnlá tí o kò gbọdọ̀ gbé ọkọ̀ rẹ sí lásìkò yìí...
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa akínkanjú obìnrin alága àjọ elétò ìdìbò Ghana 2020
- Aisha Buhari ké sí àwọn aya gómìnà pé kí wọ́n lọ paná ìdàrúdàpọ̀ lágbègbè yín
- Góòlù pọ̀ ní ìlú Madaka ṣùgbọ́n wọn kò ní ọ̀nà fún ọgọ́rùn ún ọdún





















