Prophet Israel Oladele: Wo díẹ̀ lára àwọn ìwàásù mánigbàgbé tí wòlíì ìjọ CCC Genesis Global ti ṣe

Genesis Global

Oríṣun àwòrán, Facebook/Genesis Global

Ọpọ awọn eeyan kaakiri Naijiria lo ti n sọrọ lori iru iranṣẹ Ọlọrun ti wolii Israel Oladele Ogundipe jẹ Lẹyin ti ile ẹjọ kan ni ipinlẹ Eko ran lọ si ẹwọn ọdun meji lori ẹsun gbajuẹ.

Bi awọn kan ṣe n sọ nipa awọn ore to ti ṣe fun tile-toko, lawọn miran n sọ nipa awọn iwaasu manigbagbe to ti ṣe ati awọn to da lọla lori aga iwaasu.

Lara awọn iwaasu wolii Israel Oladele Ogundipe ree:

Ko yẹ ki ibalopọ ju iṣẹju marun un pere lọ

Oṣu kọkanla ọdun 2019 ni fidio iwaasu wolii Oladele kan fa oju ayelujara ye, nibi to ti sọ pe ko yẹ ki ibalopọ laarin lọkọlaya ju iṣeju marun un pere lọ.

Ninu iwaasu naa ni wolii ọhun ti sọ pe "ibalopọ to ba ti ju iṣeju marun lọ kii ṣe ibalopọ mọ, nitori ibalopọ aladun ko gbọdọ ju iṣeju marun un lọ."

Genesis Global

Oríṣun àwòrán, Facebook/Genesis Global

O tẹsiwaju pe "alalubarika ọkunrin to mọ pe ọna oun jin ko ni maa dunu pe oun lo ọgbọn iṣeju lori obinrin."

Oladele sọ pe aṣiwere ni ọkunrin to ba n dunnu pe oun lo nnkan bi ọgbọn iṣẹju lati fi ba oninrin ni ibalopọ.

Wolii naa ni ọgbọn iṣeju ti awọn kan fi wa lori obninrin ni awọn miran fi n ka owo gọbọi.

Maṣẹ gbe ọrọ ọlọrọ lori

Israel Oladele Ogundipe Genesis

Oríṣun àwòrán, Genesis Global

Lara awọn iwaasu manigbagbe ti wolii Oladele ti ṣe ni bo ṣe maa n kọ awọn ọmọ ijọ rẹ lati foju si iṣẹ wọn, ki wọn si ma sọrọ ẹnikeji lẹyin.

Ninu iwaasu rẹ kan to ṣe ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2020, Oladele ni "okoowo to lamilaaka julọ nile aye ni ki eeyan gbaju mọ iṣẹ rẹ."

Nibẹ lo ti sọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ pe, ki wọn ma ṣe maa da si ọrọ ti ko kan wọn, ki wọn si ma ṣeyọnu nipa ẹni ti ko ba fẹran wọn.

Oladele da obinrin kan lọla ninu iwaasu

Ọdun 2018 ni Oladele da obinrin lọla ti ko ro tẹlẹ ninu ijọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Tí mo ba ti múra bí ọkùnrin fi kọrin, kò sí ọ̀dọ̀ ààrẹ́ tí mi ò lè wọ̀- Erelu, ọmọ Elemure Ekiti

Ohun to ṣẹlẹ lọjọ naa ni pe bi wolii ọhun ṣe n waasu lọwọ ni awọn ọmọ ijọ bẹrẹ si n fi owo si ẹsẹ rẹ gẹgẹ bi iṣe wọn.

Ṣugbọn kaka to yẹ ki owo naa jẹ wolii ọhun, ni ṣe lo pe obinrin kan sita, to si ni ki obinrin naa ma ko gbogbo owo ọhun lọ.

O ni Ọlọrun sọ fun oun pe ki oun ko gbogbo naa fun oninrin ọhun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni obinrin naa ko bere owo lọwọ ohun, ṣugbọn oun gbe igbesẹ naa nitori oun ti ṣe alaini ri, ati pe Oluwa lo ni ki oun ṣe bẹẹ.

Fifariga àwọn ẹ́ka ijọ Celestial mii pe o gbe olorin aye wa sinu ijọ mimọ

Wasiu Ayinde K1 De Ultimate

Wasiu Ayinde ati Oluṣọ Genesis

Oríṣun àwòrán, Genesis Global

Alhaji Wasiu Ayinde K1 De Ultimate naa lara awọn ilumọọka to ti ṣabẹwo si ijọ Celestial CCC (GENESIS) labẹ akoso pasitọ Ogundipe.

K1 De Ultimate ṣere ninu ijọ naa pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ.

Alhaji Ayinde kọ ninu orin nibẹ pe ayọ ni fun gbogbo awọn ijọ Genesis ati fun oun naa to fi mọ idile oun.

Wasiu tun kọ ninu orin pe awọn to n binu Pasitọ Ogundipe le maa binu lasan nitori ẹni ti Ọlọrun gba fun un ni.

K1 De Ultimate tun ki gbogbo awọn alatilẹyin Pasitọ Oladele ninu orin rẹ bakan naa.

Pasitọ Ogundipe naa dupẹ lọwọ K1 De Ultimate pẹlu idọbalẹ, bakan naa lo tun gbadura fun olorin naa.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?