Erelu Elemure: Ìyá mi rò pé mi ò lè tibi kíkọrin bíi bàbá mi là
Yoruba ni bi baba ba ku, baba nii kù. Adia fun ọmọ bibi inu gbajugbaja olorin ilu Ekiti, Elemure Ogunyemi ti gbogbo eeyan mọ si Elemure iyẹn Funmilayo Elemure to fiwa jọ baba ninu gbogbo nkan.
Erelu Elemure ni orukọ itage rẹEde Ekiti kan naa ti baba rẹ, Peter Ogunyemi elemure to ti di oloogbe bayii ma fi n kọ orin loun naa nlo, koda bii ọkunrin lo yan lati maa mura ninu ẹwu bii Agbada, Sokoto ati sọọrọ.
- Wo àwọn èèkàn, ìlúmọ̀ọ́ka olórin tó ṣàbẹ̀wò sí ijọ Celestial Church ti Genesis Global
- CCC Genesis Global: Ǹkan mẹ́wàá tí ẹ ò gbọ́ rí nípa Israel Oladele, Woli ìjọ Genesis Global
- Ẹ̀tanú pé Olùṣọ́ Genesis kò fẹ́ Laide Williams-Oni ló ṣe rán an lọ́ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan - CCC Genesis Global
- Saka ń wá ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan nítorí aṣọ kóòtù ọdún 34 sẹ́yìn
- Kà nípa ibi tí wọ́n bí Àrẹ̀mọ tuntun Ọọ̀ni Ife sí, àti orúkọ tó ń jẹ́
- A kò tíì lè sọ pé ọmọ Ọba tuntun ni yóò jẹ Ooni lọ́jọ́ iwájú - Elebuibọn
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye fun BBC Yoruba, ara ọtọ to n gba mura lo n fun un ni ọgbọn atinuda fun iṣẹ rẹẹ bẹẹ si ni o ni oun n ri iyi ati ọwọ gba latara eyi.
O sọ bi iya rẹ ṣe kọkọ sọ ireti nu ninu oun to yan laayo yii to si sọ fun un pe ko le ṣe oriire nibẹ amọ ṣe ni ohun ati ilu ijo mama gan yipada nigba tinkan ti ọmọ rẹ, Erelu elemure n ṣe bayii ti di iwuri nla fun un.




