Lekki Toll Gate: CNN vs Lai Mohamamed rèé o!

Aworan Lai Mohammed ati CNN

Oríṣun àwòrán, CNN

Ileesẹ iroyin agbaye ni,CNN, ti fesi si ọrọ Minisita feto iroyin Naijiria Lai Mohammed to ni ijọba yoo fofin de ileesẹ iroyin naa lori ayederu iroyin to gbe jade nipa isẹlẹ iyinbọn paniyan to waye ni Lekki.

Ileesẹ naa sọ pe iwadii to mundadoko lawọn se ki awọn to gbe iroyin naa jade nitori gbọin gbọin lawọn duro lori iroyin tawọn gbe jade ṣaaju lori iṣẹlẹ naa.

Lasiko to n sọrọ pẹlu awọn akọroyin lọjọbọ ni Minisita Lai Mohammed sọ pe ko si ẹnikankan to ku ninu ikọlu to waye ni Lekki.

Bẹẹ lo sọ pe ko si mọlẹbi kankan to jade sita lati wa kede pe awọn padanu eeyan kankan lasiko ikọlu to waye logunjọ osu Kẹwa ọdun 2020.

O fi kun ọrọ rẹ pe ẹka to n mojuto iye awọn eeyan to ku nipinlẹ Eko naa ti kesi araalu to ba padanu eeyan wọn kankan lati wa ran awọn lọwọ fun eto idanimọ oku to ba ku laarin ọjọ Kọkandinlogun si ọjọ Kẹtadinlọgbọn Osu Kẹwa.

CNN sọ pe lọpọ igba lawọn gbiyanju lati ba ileesẹ ologun Naijiria sọrọ ati ileesẹ ọlọpaa.

Wọn ni ileesẹ ọlọpaa kọ lati fesi ti atẹjade kan lati ọdọ ijọba ipinlẹ Eko si ni awọn ko ni nkankan sọ lasiko ti igbimọ iwadii si n joko lori ọrọ naa.

Ninu iwadii ati iroyin ti CNN gbe jade wọn lawọn kan si awọn akọsẹmọsẹ to salaye pe asẹku ọta ibọn tawọn fi han jẹ iru eyi tawọn ọmọ ileesẹ ologun Naijiria n lo.

Bakan naa ni wọn ni gbogbo fọnran fidio tawọn fi han jẹ ojulowo sugbọn ti Minisita layederu ni.

CNN ni Minsita Lai Mohammed ko mu ẹri kankan wa lati fi han pe ayederu ni fidio awọn tabi pe awọn ọta ibọn naa kii se tawọn ọmọ ogun Naijiria.

Ìpànìyàn orí ayélujára lásán lẹ̀ ń pariwo, ìbọn òfifo làwọn sọ́jà yìn sínú afẹ́fẹ́ - Lai Muhammed

Minisita eto ibanisọrọ ati iroyin lorilẹede Naijiria, Lai Mohammed ti sọ pe, awọn ọmọ ologun ko yinbọn lu oluwọde kankan nibi iṣẹlẹ Lekki Toll gate to waye loṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Lai Mohammed lo sọ ọrọ naa nibi ipade awọn akọroyin kan to waye ni ilu Abuja, nibi to ti sọ iha ti ijọba apapọ kọ si iwadii CNN ọhun.

O ni irọ patapata ni iroyin ti ileeṣẹ CNN gbe jade pe awọn ọmọ ogun pa awọn oluwọde ni Lekki lalẹ ọjọ naa.

Lai Mohammed ni ori ayelujara lasan lawọn ọmọ Naijiria ti n pariwo pe sja paayan, ko sẹni to ni aridaju.

Minisita naa ṣalaye pe gbogbo ipinlẹ Eko ni ijọba da awọn sọja si lẹyin ti ijọba Eko bere fun iranlọwọ wọn nitori apa awọn agbofinro ko ka iwọde naa mọ, kii ṣe Lekki nikan.

O ni wọn sọ fun awọn ologun naa iru iha to yẹ ki wọn kọ si awọn oluwọde ki wọn to de iloro Lekki ti awọn oluwọde wa, ati pe wọn ko yin ibọ pa eeyan kankan.

Bo tilẹ jẹ pe Lai ni awọn ṣoja naa yinbọn, ṣugbọn o ni kii ṣe ọta to lagbara lati gbẹmi eeyan ni wọn yin, ati pe inu afẹrẹ lasan ni wọn yin ibọn naa si, wọn ko doju rẹ kọ ẹnikẹni.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

Nigba to n bu ẹnu atẹ lu iroyin ileeṣẹ CNN, Lai sọ pe ko si oku kankan ti wọn ri he ni iloro Lekki, ati pe ko si ẹbi kankan to wa sọ fun ijọba pe eeyan wọn di awati lẹyin iṣẹlẹ naa.

O tẹsiwaju pe ki ẹnikẹni to ba ni ẹri pe awọn ologun ṣekupa ọpọ eeyan ni Lekki le lọ fi ẹri naa han niwaju igbimọ to n ṣewadii iṣẹlẹ ọhun, tabi ko gbẹnu dakẹ.

Ni ti CNN, lai Mohammed ṣalaye pe iwadii ofege ni wọn ṣe, eyii to yẹ ko jẹ ohun itiju fun wọn gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin to kari aye.

Lai sọ pe, inu ijọba apapọ dun si iṣẹ ti awọn ologun ati awọn agbofinro ṣe ni Lekki Toll gate, nitori wọn fi ẹmi ara wọn sinu ewu fun abo ilu.

Lẹyin naa lo ṣalaye pe ko din ni ọmọ ogun mẹfa ati ọlọpaa mẹtadinlogoji ti ẹmi wọn ba atunbọtan ifẹhonuhan EndSARS ọhun lọ, yatọ si awọn ọkọ ati agọ ọlọpaa to jona.

Ijọba ipinlẹ Eko ti fesi si iroyin iwadii CNN lori ohun to waye ni Lekki Toll gate logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

EndSARS

Oríṣun àwòrán, @AyowoleSanyaolu

Ijọba ipinlẹ Eko ti fesi si iroyin iwadii CNN lori ohun to waye ni Lekki Toll gate logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Nigba ti BBC kan si ijọba, wọn ni awọn ko ni ohunkohun lati sọ lori fidio ti ileeṣẹ iroyin CNN gbe jade, eyii to n ṣafihan pe ijọba pa irọ lori iṣẹlẹ to waye lẹnu iloro naa.

Wọn ni awọn ko le sọ ohun kankan lọwọ yii lori fidio CNN titi di igba ti esi igbimọ ti wọn kalẹ lati ṣe iwadii iṣẹlẹ naa yoo fi jade jade.

Agbẹnusọ gomina Babajide Sanwo-Olu, Gboyega Akosile sọ fun BBC pe, iwadii ṣi n lọ lọwọ, nitori naa yoo ṣoro lati sọ ohunkohun lasiko yii.

CNN Nigeria protest:

Oríṣun àwòrán, BABAJIDE SANWO-OLU/TWITTER

Iwadii ti ileeṣẹ iroyin CNN ṣe fi han pe awọn ọmọ ileesẹ ologun Naijiria dana ibọn ya awọn oluwọde EndSARS ni Lekki Toll Gate.

Ṣugbọn ileeṣẹ ologun ti fesi pe ko si ootọ ninu ọrọ ọhun, nitori awọn ko yibọn lu ẹnikẹni.

Wọn ni ọta ti wọn yin kii ṣe eyii to le gbẹmi eeyan ati pe inu afẹfẹ lasan ni awọn yin ibọn naa si.

CNN Nigeria protest

Oríṣun àwòrán, Other

Ninu iwadii CNN, wọn ni ọpọlọpọ wakati ni awọn fi yẹ awọn fidio kan ti awọn eeyan ya nibi iṣẹlẹ ọhun wo, bẹẹ ni wọn si tun gba ọrọ lẹnu awọn oṣoju mi koro, awọn ti ọrọ naa ṣe si atawọn ti wọn padanu ẹbi wọn nibi iwọde naa.

CNN ni gbogbo awọn ẹri wọnyii ni wọn ko jọ pọ ki wọn to gbe iwadii wọn jade.

Ki lo ṣelẹ sẹyin?

Wo nkan tí ìjọba UK sọ lórí ìwé ẹ̀sùn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà kọ si lórí ENDSARS

Awọn oluwọde ENDSARS to gbe asia orilẹ-ede Naijiria dani ni agbegbe Ikeja nilu Eko, lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, sun 2020

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde ENDSARS to gbe asia orilẹ-ede Naijiria dani ni agbegbe Ikeja nilu Eko, lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, sun 2020

Ijọba orilẹ-ede United Kingdom, ti fesi lori iwe ẹsun ti awọn ọmọ Naijiria fọwọ si, ti wọn si fi ransẹ si.

Iwe naa lo n ke si awọn orilẹ-ede agbaye to wa ninu ajọ Commonwealth, lati fi 'iya' jẹ awọn olori Naijiria gẹgẹ bi ibawi, fun ẹnikẹni ninu wọn to lọwọ ninu titẹ ẹtọ ọmọniyan loju, gẹgẹ bi ofin ajọ naa ṣe sọ.

Ọmọ Naijiria bii okoolerugba o din diẹ (219,665) lo fi ọwọ si iwe ẹsun naa lọ sọdọ ijọba UK.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ile aṣofin orilẹ-ede UK sọ pe, ominu nkọ oun lori rogbodiyan to waye lasiko iwọde ENDSARS, ati pe awọn ṣi n duro de iwadii ti ijọba Naijiria yoo ṣe lori ẹsun ifiyajẹni ti araalu fi kan awọn ọlọpaa.

Asia ilẹ UK

Oríṣun àwòrán, @GOVUK

Iwe ẹsun to ba ti ni ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan to fọwọ si , ni ile aṣofin orilẹ-ede UK ma n jiroro le lori, iwe ẹhonu ENDSARS yii si ti le ni ẹgbẹrun lọna igba.

Amọ ṣa, wọn ni awọn kii sọ igbesẹ ti awọn yoo gbe lori awọn iwe ẹsun naa ni gbangba.

Aṣaájú olùwọ́de EndSARS 50 dèrò iléẹ́jọ́ lórí ìfẹ̀hónúhàn àti ìdàlúrú

Àjàfẹ́tọ ọmọnìyàn kan ti gbé àwọn 50 lọ sílé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ #Endsars

Ajàfẹ́tọ ọmọniyàn kan, Kenechukwu Okeke ti fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan àádọ́tà èèyàn nílé ẹjọ́ Májísíreeti kan nílùú Abuja.

Ẹ̀ṣùn tó fi kàn wọ́n dá lórí ipa ti wọ́n kó nínú ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn #Endsars tó wáye ni oṣù tó kọjá.

Okeke fẹ̀sùn kàn pé lásìkò ìfẹ̀hónú hàn náà, ọ̀pọ̀ dúkìá ló sòfò, ìdí sì nìyìí tí wọn fi gbọdọ̀ fi àwọn tó wà lẹ́yìn ìwọ́de náà jófin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn tó pè lẹ́jọ́ náà ni, Damini Ogulu ti àwọn ènìyàn mọ̀ sí Burna Boy, David Adeleke (Davido) Folarin Falana (Falz); Debo Adebayo (Mr Macaroni), àti Maryam Akpaokagi (Taoma).

Peter àti Paul Okoye, Innocent Idibia (Tuface), Bankole Wellington (Banky W), Tiwa Savage, Michael Ajereh (Don Jazzy ) àti Yemi Alade.

Àjàfẹ́tọ ọmọnìyàn kan ti gbé àwọn 50 lọ sílé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ #Endsars

Oríṣun àwòrán, Kenechuckwu/twitter

Àwọn míràn tún ni Pasitọ, Daystar Christian Centre, Sam Adeyemi, ajàfẹ́tọ ọmọniyan, Aisha Yesufu; agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà nígbà kan rí, Kanu Nwankwo; ọ̀mọ̀wé Joe Abah, Kiki Mordi, gbájugbajà òṣèré Nollywood Yul Edochie àti Uche Jombo.

Feyikemi Abudu, Olorunrinu Oduala, Pamilerin Adegoke, Japhet Omojuwa, Ayo Sogunro àti Deji Adeyanju náà kò gbẹ́yìn.

Àjàfẹ́tọ ọmọnìyàn kan ti gbé àwọn 50 lọ sílé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ #Endsars

Oríṣun àwòrán, Kenechukwu/twitter

Àjàfẹ́tọ ọmọnìyàn kan ti gbé àwọn 50 lọ sílé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ #Endsars

Oríṣun àwòrán, Kenechukwu/twitter

Ọjọ́ Ajé ló gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ilé ẹjọ́, pé àwọn ènìyàn náà kó ipa ribiribi nínú ìfẹ̀hónúhàn EndSars, èyí tó padà yìí sí rògbòdìyàn

Nínú ìwé ẹ̀sùn tó fi pẹjọ́ lo ti sàlàyé pé, gbogbo nkan ìní òun ló bàjẹ́ poo.

Àjàfẹ́tọ ọmọnìyàn kan ti gbé àwọn 50 lọ sílé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ #Endsars

Oríṣun àwòrán, Screenshot

kó ohun tí ìràn Yorùbá ń fẹ́ lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ nìyí

Awọn asoju ilẹ Yoruba ati ijọba apapọ

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Awọn agbaagba nilẹ kaarọ oojire, ninu eyi ti awọn gomina ipinlẹ Oodua mẹfẹẹfa wa, ti se ipade pẹlu ijọba apapọ nilu Abuja lọjọ Aiku.

Lara awọn to si wa nibi ipade naa tun ni awọn ọba alaye nilẹ Oodua, awọn minisita lati ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, awọn gomina ati ikọ asoju ijọba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ Muhammadu Buhari si lo se atọna ipade ọhun lẹyin iwọde EndSARS ati rogbodiyan to tẹle, eyi to se okunfa ole jija, idaluru ati biba alaafia ilu jẹ, paapaa nilu Eko.

Awọn ohun ti wọn si fẹnuko le lori nibi ipade naa niyi:

  • Owona ti ijọba n bu fun awọn ọlọpaa ko to rara, o si yẹ ki wọn bu owo pupọ fun wọn lati ra awọn ohun eelo ti wọn nilo fun ipese eto aabo to peye
  • Ki ilana isọwọ sisẹ awọn ọlọpaa ba ilana ọtẹlẹmuyẹ ode oni mu, ki irufẹ laasigbo to tẹle iwọde EndSARS ma baa waye mọ
  • Agbeyẹwo abọ ipade apero ilẹ wa tọdun 2014 pẹlu ọna lati se amusẹ awọn aba to wa ninu rẹ bii eto aabo, ọrọ aje ati ibaradọgba awsn ọmọ orilẹede yii
  • Awọn agbaagba ilẹ Yoruba naa tun n fẹ ki ijọba si awọn ẹnu bode ilẹ wa pada nitori eyi lo mu ki inira ọrọ aje tubọ pọ si, to si tun mu kawọn ọja gbogbo gbe owo lori
  • Igbesẹ lati se atunse awọn dukia ti awọn janduku bajẹ lasiko rogbodiyan EndSARS nilẹ Kaarọ oojire, ti wọn si tun yin ijọba lawo pe o tete dahun ibeere tawọn ọdọ naa gbe siwaju rẹ
  • Agbekalẹ eto ti yoo wa isẹ oojọ fun awọn ọdọ ati fifi ẹnu ọrọ jona pklu awọn oluks fasiti, ki awọn akẹkọọ lee wọle pada
  • AWọn tun se atilẹyin fun aba ijọba apapọ lati se akoso awọn oju opo itakun agbaye nitori wọn ni awọn mọ ipa buruku ti iroyin eke n ni lawujọ ati bo se lewu si
  • Amulo imọ ẹrọ igbalode lọna ti yoo mu agbega ba eto aabo wa, yatọ si bi wọn se n lo ẹrọ igbalode fun ibajẹ lori Facebook, Twitter, Instagram ati bẹẹ bẹẹ lọ
  • Ko tan sibẹ, awọn asoju ilẹ Yoruba naa tun n fẹ agbekalẹ ajọ ti yoo maa ri si idagbasoke ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria gẹgẹ bo se wa lawọn ẹkun yoku ni Naijiria.

Lara awọn ọba alaye to wa nibi ipade Ọọni ti Ile Ife, Alaafin ti Oyo, Eleko ti Eko, Ọ́lọwọ ti Ọwọ, Ọrangun ti Oke-Ila, Ayangburen ti Ikorodu ati Alawẹ tilu Aawẹ pẹlu Olu ti Ilaro ati Ọwa-Ooye ti Okemesi.

A kò yìnbọn lù olùwọ́de Lekki, omi tútù àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò la fi pẹ̀tù sí wọ́n - Iléeṣẹ́ ológun

Aworan oluwode

Orisirisi lo n jẹyọ nibi iwadii igbimọ to n gbẹjọ ifiyajẹni ati iwa aitọ lati ọdọ ọlọpaa si ara ilu nipinlẹ Eko.

Ni ijoko ipade naa to waye kẹyin, n ṣe ni ọgagun to n ṣoju ileeṣẹ ologun niwaju igbimọ naa ṣalaye pe, awọn ko yinbọn pa oluwọde kankan ni Lekki.

Ninu ọrọ rẹ Ọgagun Musa Etsu-Ndagi sọ pe, Gomina Babajide Sanwo-Olu pe oun lori ago lalẹ ọjọ Isẹgun ti isẹlẹ Lekki naa waye, to si ni ọgagun kan torukọ rẹ n jẹ Bello, ti n yinbọn lu awọn oluwọde ni Lekki.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olori ọwọ kẹsan ileesẹ ologun (9 Brigade) naa sọ ọrọ yii, ninu iwe ijẹri to kọ siwaju igbimọ oluwadi ọhun lọjọ Ẹti.

Aworan oluwode

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Musa ni kete ti ọrọ yii to oun leti, ni oun ti pe Bello to jẹ ọga ọwọ karundinlaadọrin ileeṣẹ ologun (65 Battalion) to wa ni Bonny Camp, to si sọ fun oun pe ibọn ti ko ni ọta ninu, lawọn yin soke, kii ṣe ọta gidi.

Ọga ologun naa tẹnumọ pe, awọn ọmọ ogun ko yinbọn lu oluwọde tabi pa ẹni kankan, ati pe iroyin to ni awọn pa awọn eeyan nipakupa lalẹ ogunjọ oṣu Kẹwa ọdun yii, kii ṣe ootọ.

Bẹẹ lo tun sọ pe, awọn ọmọ ogun ko gbe oku ẹnikankan kuro nibi iṣẹlẹ naa.

Awon ologun niwaju igbimọ oluwadii

Oríṣun àwòrán, @LASG

Bello ni koda, niṣe ni inu awọn oluwọde naa dun nigba ti wọn ri awọn ati pe, oun paapaa fun awọn oluwọde ni omi ati ati ọti ẹlẹrindodo pẹlu imọran pe, ki wọn pada sile.

Yatọ si awọn wọnyii, awọn ọgagun mii to wa jẹri niwaju igbimọ naa ni ọgagun to n dari 81 Military Intelligence Brigade to wa ni Victoria Island, ọgagun Ahmed Taiwo, olori oṣiṣẹ ọmọ ogun 81 Division V.I kanna, Nsikak Edet ati ọgagun Francis Omata to n dari 81 Division Garrison.

Àkọlé fídíò, Pistachio Green Puppy: Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláwọ̀ funfun, tí òun sì jẹ́ aláwọ̀ ewé

Ohun to jẹyọ ninu ọrọ awọn ọgagun wọnyi ni pe, iwọde naa to kọkọ n lọ nirọwọrọṣẹ, pada di onijagidijagan.

Ninu ẹri ti wọn jẹ niwaju igbimọ naa, wọn sọ pe awọn ologun ko yinbọn lu oluwọde, bi kii ṣe pe awọn yin ibọn ti ko ni ọta soke, lati fi tu wọn ka.