Cholera in Oyo: Èèyàn Mọ́kànlá dèrò ọ̀run n‘Ibadan torí àrùn àìmọ̀dí

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @OfficialSeyiMakinde

O kere tan, eniyan mọkanla lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti awọn ara agbegbe ijọba ibilẹ Lagelu lugbadi aisan aimọdi.

Awọn marun mii ṣi wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n doola ẹmi wọn lọwọ.

Iroyin ti a ko le fi idi rẹ mulẹ ni aisan onigbameji ni, nitori awọn ami ti awọn eniyan to lugbadi aisan aimọdi naa n fihan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, ijọba ni awọn ko lee fi idi ọrọ naa mulẹ ni isinsinyii, amọ awọn ti bẹrẹ ayẹwo ati iwadii lori iru aisan to jẹ.

Awọn alaisan nile iwosan

Oríṣun àwòrán, @OYSG

Awọn ara adugbo Ariku ni agbegbe naa ni isẹlẹ yii ti kọkọ bẹrẹ, ti eniyan marun si ti papoda nitori arun naa.

Lẹyin naa ni arun ọhun tan ka de agbegbe Lagun, ti o si tun mu ẹmi eniyan mẹfa lọ lẹẹkan naa.

Alaga ijọba ibilẹ Lagelu, Kelani Abdullahi ni awọn ti bẹrẹ iwadii ni pẹrẹwu lori aisan naa, to si fi idi rẹ mulẹ pe, lootọ ni eniyan mọkanla ti jẹ Olorun ni pe, ti eniyan mẹrin mii si wa ni ileewosan.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà

Bakan naa ni Kọmisọna fun eto ilera nipinlẹ Ọyọ, Bashiru Bello ni awọn ko i tii le fi idi rẹ mulẹ pe, aisan onigbameji' 'Cholera' lo n ṣeku pa awọn eniyan naa.

Amọ, o fikun wi pe, aisi imọtoto wọpọ ni awọn agbegbe ti arun naa ti bẹ silẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

"Ìyá mi sì wà ní páńpẹ́ ajínigbé, ọlọ́pàá, irọ́ lẹ̀ ń pa pé ó ti gba ìdáǹdè"

Awọn gende agbebọn

Oríṣun àwòrán, @TheRoyOsuji

Ẹbi iyalọja Isua Akoko ti ni ko i tii si ẹni to doola ẹmi Iyalọja naa nitori o ṣi wa ni panpẹ awọn ajinigbe.

Eyi ko ṣeyin ikede awọn ọlọpaa pe awọn ti doola ẹmi awọn ti ajinigbe gbe lọ ni ọsẹ to kọja ni Isua Akoko.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Teo-Leo Ikoro ni awọn ti doola ẹmi awọn arinrinajo ti awọn ajinigbe ṣekọlu si ni ọsẹ to kọja ni ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, awọn ẹbi Iyalọja naa ni awọn ṣi ba iya awọn sọrọ ni panpẹ awọn ajinigbe, to ṣi n bẹbẹ pe ki awọn jọwọ da owo jọ, lati san fun awon ajinigbe to n beere owo ẹmi lọwọ wọn.

Àkọlé fídíò, Ifa Worshippers: Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ń fẹ́ kíjọba pín èrè òṣèlú alágbádá yíká gbogbo ẹ̀sìn

Ọmọ iyalọja naa, Abilekọ Alaba Edward ni gbogbo ilu Isua Akoko lo hoo fun ayọ nigba ti wọn gbọ iroyin pe, awọn ọlọpaa ti doola ẹmi iyalọja naa, amọ ibanujẹ lo jẹ fun awọn wipe ọrọ ko ri bẹẹ.

Nibayii, Abilekọ naa ni awọn ajinigbe ni ki awọn lọ mu miliọnu marun wa, lẹyin ti wọn kọkọ beere fun miliọnu mọkanla naira, amọ ko si eleyii ti awọn lagbara lati san ninu owo naa.

Ati wipe, iyalọja naa nikan ni obinrin to wa laarin awọn arinrinajo marun ti awọn ajinigbe naa ṣekọlu si.

Àkọlé fídíò, Bose Okeowo: Àárẹ̀ kékeré ló sọ mi dí aláàbọ̀ ara yìí ṣùgbọ́n...

Bakan naa ni awọn oloyeni ilu Isua Akoko wa kesi ileeṣẹ ọlọpaa lati tẹle aṣẹ Ọga Agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Muhammed Adamu to ni ki awọn ọlọpaa pada si oju popo lati doola ẹmi awọn arinrinajo,

''Nitori ibẹru pe awọn ọlọpaa wa ni oju popo jẹ ki ijinigbe rọlẹ si ni agbegbe naa.''

Awọn oloye naa wa kesi ileeṣẹ ọlọpaa lati mase jẹ ki awọn janduku ati ọdaran gba iṣakoso orilẹede Naijiria nitori aibikita awọn ọlọpaa.

"Ìfẹ́ akọ sákọ àti abo sábo tó wọ́pọ̀ ní Àríwá Nàíjíríà ló fa ìbínú Ọlọ́run"

Awọn akọ to n fẹ akọ ati abo to n fẹ abo n se iwọde

Oríṣun àwòrán, Bisi Alimi Foundation

Awọn Yoruba lo maa pa a lowe pe, bi ko ba nidi, obinrin kii jẹ Kumolu.

Emir ilu Birnin Gwari nipinlẹ Kaduna, Mallam Zubairu Jibrin Maigwari II ti wa woye pe, iwa iṣekuṣe akọ sakọ ati abo sabo to gbilẹ kan, lo ṣokunfa eto aabo to mẹhẹ lapa ariwa orilẹede Naijiria.

''Lonii lapa ariwa Naijiria, aimọye ọkunrin lo n fẹ ọkunrin ẹgbẹ rẹ, tawọn obinrin si obinrin naa ṣi n bara wọn ṣe ṣina ni gbangba lai fibo rara,'' Emir Birnin Gwari lo sọ bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Mallam Maigwari II ni awọn iwa idọti yii gan an ti to, ki Ọlọrun binu si apa Ariwa orilẹede Naijiria.

Mallam Zubairu Jibrin Maigwari II

Oríṣun àwòrán, Facebook/Emir of Birnin Gwari

Emir naa sọ pe, ohun kan to le mu ki Ọlọrun yọnu si apa Ariwa Naijiria ni pe, ki wọn wolẹ adura, ki wọn si tọrọ idarijin ẹsẹ lọwọ Eleduwa.

Emir ilu Birnin Gwari ni ''a nilo igbala ọkan, Ọlọrun nikan lo le ra wa pada pẹlu awọn iwa buruku ta n hu yii. Ko sẹni to le ṣe e.''

O ni aṣa ki akọ maa fẹ akọ ati abo si abo ti di meji tọrọ bayii, eyi ti ọpọ fi n yangan lawujọ.

Àkọlé fídíò, Pistachio Green Puppy: Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláwọ̀ funfun, tí òun sì jẹ́ aláwọ̀ ewé

Mallam Maigwari II sọ pe, ko si ibẹru Ọlọrun mọ, o ni ohun to ba wu ibinu Ọlọrun ko ṣe, ni iwa bawọn eeyan se kọ lati bẹru rẹ.

Emir Birnin Gwari ni idi gan naa niyii ti arelu ati ajaalu fi n ṣẹlẹ lagbegbe Ariwa orilẹede Naijiria.