Ẹgbẹ́ OPC nílùú Ibadan ke gbàjarè lórí ọkọ̀ akẹ́rù ńlá tó kó Fulani ati Hausa wọ̀lú Ibadan

Agọ ọlọpàá Sanyo ni wọn dari ọkọ̀ akero to kó awọn Fulani tọ wọ ilu Ibadan si náà lọ - OPC

Oríṣun àwòrán, Olumo

Daru-dapọ waye ni adugbo Maje, to wa ni agbegbe Soka, nilu Ibadan.

Eyi ko ṣẹyin iroyin kan to ni ọkọ akero nla 'luxurious bus' ko awọn eeyan kan to ṣe ajoji si adugbo naa wọ ibẹ.

Lati fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ẹgbẹ New Era OPC, Akinpẹlu Adesina, sọ fun BBC pe irú ńkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹ̀lẹ̀ rí ni ǹkan bi osu meji sẹyin tó sì jẹ́ pé Sunday Adeyemo Igboho lo tú àsìrì náà lásìkò ọ̀hún.

Ó kó OPC lọ sí sibẹ̀ tó sì tún pé àwọn ọlọ́pàá láti mú wọ́n ní ìgbà náà.

Ọgbẹni Adesina sàlàye pé kò sí àrídájú kankan níbi èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé, àfi tó bá jẹ pé, àwọn OPC ń sẹ̀ṣẹ̀ bá ǹkan to ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ní.

Ọgbẹ́ni Olumo ní ti rẹ̀ fi fóto sọ́wọ́ sí BBC tó jẹ́ bi ẹri pé ǹkan náà ṣẹlẹ̀ lónìí ní àgbègbè Maje ni Soka, ìlú Ibadan

Agọ ọlọpàá Sanyo ni wọn dari ọkọ̀ akero to kó awọn Fulani tọ wọ ilu Ibadan si náà lọ - OPC

Oríṣun àwòrán, Olumo

"Ero ti pọ lé wọn lórí pé wọn ò gbọ̀dọ já wọn sílẹ̀. O ni lóòtọ ni pé kò si ẹya Yoruba kan nínú rẹ̀ bíkòṣe Bororo, Fulani àti Hausa.

Ó ní àwọn fura pé àwọn Fulani darandaran ni wọn, sùgbọ́n lẹ́yìn ti wọn kó wọ́n lọ si àgọ́ ọlọ́pàá, à o mọ nkan ti ọlọ́pàá ń ṣe pẹ̀lú wọn.

Yàtọ sí ọkọ̀ akẹrò mẹ́ta (Luxury Buses) ti ìwé ìròyìn kan sọ, Olumo ni ẹyọkan péré ni òun rí tí oun si ya fótò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí.

Àmọ́, Adesina ni tiẹ sọ pé àwọn o gbọ́ ǹkan to jọ bẹ àti pé agbègbè Soka ni òun wà bi òun ṣe ń bá BBC sọ̀rọ̀.

Agọ ọlọpàá Sanyo ni wọn dari ọkọ̀ akero to kó awọn Fulani tọ wọ ilu Ibadan si náà lọ - OPC

Oríṣun àwòrán, Olumo