APC Crisis: Àwọn ọmọ ẹgbọ́ APC kan ti n yarí nítorí àì tí ṣe ìpàgọ́ ẹgbẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn iroyin kan ti n lọ labẹnu pe, o ṣe e se ki igbimọ alakoso ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ṣe ipade apapọ ko to o di ọjọ Keresi, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2020.
Ati pe, igbimọ naa yoo beere fun afikun saa rẹ pẹlu oṣu mẹfa, nitori asiko ti ko fi bẹ ẹ si fun mọ.
Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awuyewuye n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ kan pe, wọn yoo koro oju si igbimọ naa ti ko ba fi ṣeto ipagọ gbogboogbo 'National Convention' ẹgbẹ naa ni kiakia.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló ń fa ikú ọ̀wọwọ̀ọ́ níjọba ìbílẹ̀ Lagelu, n‘Ibadan?
- Ẹ̀sìn ìṣẹ̀ṣe ṣún síwájú, wo orin aládùn lẹ́nu ẹgbẹ́ akọrin àti ìjèrè ọkàn tí wọn ń ṣe
- Ojúlówó Shina Rambo yọjú sígboro lọ́jọ́ Àìkú, ó fi ìka hánu lórí ìpànìyàn tó ti ṣe
- Àwọn ọ̀dọ́ Benue pa pásítọ̀ ti wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó ń mú ǹkan ọmọkunrin
- Iléẹjọ́ mú ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kọkànlá fún ìgbẹ́jọ́ àwọn tó jí ìbejì Àáfà Akeugbagold ní Ibadan
- Àgọ́ ọlọ́pàá Sanyo ni wọ́n darí ọkọ̀ akérò tó kó àwọn Fulani wọ ìlú Ibadan lọ - Oyo OPC
Ṣugbọn ṣa, awọn kan tun n sọ pe, ko jọ pe ipagọ naa yoo waye titi di ọdun 2021.
Ẹ o ranti pe ọjọ Karundinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2020, ni wọn tu igbimọ oludari ti Alaga ẹgbẹ APC nigba kan, Adams Oshiomole ko sodi ka, ti wọn si gbe igbimọ fidihẹ, ti gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni, dari kalẹ.
Ohun ti ofin ẹgbẹ naa sọ ni pe, oṣu mẹfa pere ni saa igbimọ fidiẹ naa, to si gbọdọ ṣe ipagọ gbogboogbo laarin akoko naa, nibi ti wọn yoo ti yan awọn adari ẹgbẹ tuntun.
Amọ ko dabi ẹni pe igbaradi kankan ti n waye lati ṣe ipagọ naa lọdun yii.
Ṣaaju ni olori igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Zamfara, Sẹnetọ Kabiru Marafa, sọ pe ki Buni mu ọ̀kan ninu ko kọwe fi ipo silẹ, tabi ko ṣe ipagọ l'oṣu Kejila.
Làásìgbò ọ̀tun súyọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC
Asamọ ọrọ kan lo ni ile to ba gbogun ti ara rẹ, ko ni duro, bẹẹ si ni adiẹ kii jẹ ifun ara wọn.
Amọ eyi ko ri bẹẹ ninu ẹgbẹ oselu to n se ijọba lọwọ lorilẹede Naijiria nitori akọtun laasigbo to n da omi alaafia ẹgbẹ oselu naa ru bayii.
Idi ni pe gbogbo aayan igbimọ fidiẹ to n tukọ ẹgbẹ APC lọwọ lọwọ lati yanju aawọ abẹnu to n daamu ẹgbẹ oselu naa, lo ja si pabo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Afurasí afipábánilópọ̀ kàgbákò, obìnrin tó jà lólè fi eyín gé nǹkan ọkùnrin rẹ̀ jábọ́ lásìkò ‘Blow Job’
- Àwọn ọba alayé, Mínísítà àti gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ṣèpàdé pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀, àbọ̀ rèé
- "Ìyá mi sì wà ní páńpẹ́ ajínigbé, ọlọ́pàá, irọ́ lẹ̀ ń pa pé ó ti gba ìdáǹdè"
- Iná ṣẹ́yọ nílé ìtajà aya Ajimobi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó jáde opó
- Ìjọba Eko fẹ́ tú olùwọ́de EndSARs 253 sílẹ̀ lọ́jọ́ Ajé nínú 361 tó wà láhàámọ́
- "Ìfẹ́ akọ sákọ àti abo sábo tó wọ́pọ̀ ní Àríwá Nàíjíríà ló fa ìbínú Ọlọ́run"
- Ọ̀pá àṣẹ Ọba Akiolu tẹ gbé, a kò ní fọwọ́ yẹpẹrẹ mu - Ìgbìmọ̀ Ọba l‘Eko yarí
- Olori Badra sọ̀rọ̀ nípa ayé rẹ̀, ó ní ẹ́ bá òun sọkún
Aarẹ orilẹede yii, Muhammadu Buhari lo kọkọ saaju igbesẹ lati doola awọ to suyọ ninu ẹgbẹ APC nitori bi ile ẹjọ se yẹgi mọ alaga rẹ, Adams Oshiomole nidi.

Nibayii, lẹyin ti atẹgun ti fẹ si saa to yẹ ki alaga fidi hẹ ti wọn yan lẹyin Oshiomole lo nipo, ni awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP kan tun ti n lọgun pe, ki wọn se agbekalẹ ojulowo ikọ oludari fẹgbẹ oselu naa.
Awọn eekan ẹgbẹ PDP kan, ti wa kesi igbimọ fidihẹ naa, ti gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ko sodi lati pe ipade apapọ ẹgbẹ oselu APC losu to n bọ, ki wọn le dibo yan awọn ọmọ igbimọ amusẹ tuntun.
Awọn eeyan naa ni awọn ọmọ igbimọ amusẹ ọhun ti tasẹ agẹrẹ pẹlu gbigbe awọn igbesẹ ti ko si ninu ojuse wọn, ti wọn ko si yẹ lati maa tukọ ẹgbẹ oselu naa mọ.
Bawo lawọn ọmọ igbimọ amusẹya APC se kọja aaye wọn?
Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ APC to n fapa janu, Sẹnetọ Kabiru Marafa ni awọn ọmọ igbimọ fidihẹ APC ti kọja aaye wọn pupọ.
Marafa, ẹni to dije dupo gomina nipinlẹ Zamfara tẹlẹ ni, bi igbimọ fidihẹ naa se n fi orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa silẹ jakejado Naijiria kii se ojuse wọn.

Oríṣun àwòrán, Buhari Salihu
Marafa, lasiko to n ba BBC sọrọ ni "eto iforukọsilẹ ti wọn gunle naa kii se ara isẹ wọn, yoo kan tubọ da ẹgbẹ ru ni."
Amọ agba oselu kan ninu ẹgbẹ oselu APC, tii tun se oludamọran fun aarẹ lori ọrọ ile asofin, Hon Kawu Sumaila salaye pe igbimọ fidihẹ naa ko tiii tasẹ agẹrẹ rara.
Kawu ni o di dandan ki igbimọ fidiẹ naa ri si eto iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ, eyi to maa n waye ni ọdun mẹfa mẹfa lati mọ bi ẹgbẹ naa se ni eeyan si.
Bẹẹ ba si gbagbe, ara aawọ abẹnu to n waye ninu ẹgbẹ oselu APC yii lo mu ki wọn padanu ipo gomina nipinlẹ Edo.
Bakan naa ni awọn onwoye se akiyesi pe ijakulẹ nla lee waye fun ẹgbẹ oselu naa lọdun 2023 fẹgbẹ APC, ti aarẹ Muhammadu Buhari ba pari saa rẹ.
A ko setan lati yan adari ẹgbẹ tuntun - Igbimọ Fidihẹ
Wayi o, igbimọ fidihẹ fẹgbẹ oselu APC ti gbọnmu pe oun ko ni seto ipade apapọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati yan awọn adari tuntun gẹgẹ bawọn kan se n beere fun.
Atẹjade kan ti akọwe apapọ fẹgbẹ APC, Yekini Nabena fisita salaye pe ayafi ti aawọ abẹnu ẹgbẹ naa ba di afiẹyin, ni ipade apapọ ẹgbẹ yoo to waye.
Atẹjade naa ni wọn ti gbe igbimọ kalẹ lawọn ipinlẹ kan, eyi ti yoo wa ojutu si aawọ aarin wọn, ti eyi si ti n fidi mulẹ nipinlẹ Oyo, Ondo, Ekiti, Edo, Bauchi, Cross River, Enugu ati Zamfara.
Bakan naa ni Hon Kawu fikun pe ti wọn ba pari iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ pẹlu yiyanju aawọ aarin wọn, ni eto ipade apapọ yoo to waye.
Se o seese ki aawọ inu ẹgbẹ oselu APC de ile ẹjọ bi?
Ninu alaye rẹ, Sẹnetọ Marafa ni ko tii si ọna ati yanju aawọ nipinlẹ Zamfara ti oun ti wa, nitori to ba ri bẹẹ ni, o yẹ ki wọn ti kan si oun.
O ni oun wa lara awọn ti inu n bi, ti ẹgbẹ APC ti sẹ, ti wọn si gbọdọ tu ninu pẹlu aafikun pe, ti igbimọ fidihẹ naa ko ba dẹkun ojuse aitọ to n se, oun yoo gbe wọn lọ sile ẹjọ.
Sugbọn awọn onwoye kan ti salaye pe, aawọ abẹnu ẹgbẹ oselu APC lo seese ko tẹsiwaju wọnu eto idibo ọdun 2023, ta ba wo iyapa, ati ikunsinu to wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa.















