Shina Rambo: Mo ti di atúnbí àti ajíhìnrere, ń kò jẹ́ orúkọ àtijọ́ mọ́

Oríṣun àwòrán, Fresh FM Facebook
Gbajugbaja ogboju adigunjale ni amọ to ti wa di ojisẹ Ọlọrun bayii, Shina Rambo ti pa orukọ da.
Orukọ tuntun to n jẹ bayii ni Sina Jesu.
Rambo, ti ọpọ eeyan n pariwo pe o ti ku, lo ni alaaye ni oun, isẹ Oluwa si ni oun n se, to si foju han fun araye.
Shina Rambo naa, to jẹ gbajumọ ọdaran taye n polongo rẹ tẹlẹ, ki ọwọ ofin to tẹ ẹ, lo tun yọju kulẹ sileesẹ Fresh FM nilu Ibadan lọjọ Aiku lati kopa lori eto redio kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Wàhálà míì dé! Nupeng àti Pengassan gùnlé ìyanṣẹ́lódì
- Làásìgbò ọ̀tun súyọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Báwo ni Joe Biden yóò ṣe mú ìyípadà bá òfin tí Trump fi de orílẹ̀èdè àgbáyé?
- Afurasí afipábánilópọ̀ kàgbákò, obìnrin tó jà lólè fi eyín gé nǹkan ọkùnrin rẹ̀ jábọ́ lásìkò ‘Blow Job’
- Àwọn ọba alayé, Mínísítà àti gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ṣèpàdé pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀, àbọ̀ rèé
- Iná ṣẹ́yọ nílé ìtajà aya Ajimobi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó jáde opó
Gbajugbaja akọrin Tungba nni, Yinka Ayefele funra rẹ si lo jẹ atọkun eto naa, nibi to ti n ju oniruuru ibeere si Rambo.
Rambo, ẹni to pe orukọ ara rẹ ni Oluwasina Oluwagbemiga lo salaye pe, oun ti di ojisẹ Ọlọrun ati ajihinrere fun Jesu, ti iyipada nla si ti ba aye oun.
O wa jẹwọ pe oun gan ni ogbontagi ọlọṣa to n mi ilu titi fun ọpọlọpọ ọdun, bi oun si se n jale, ni oun tun npa alaisẹ, ti oun si n fi imu agbofinro danrin.
Rambo ni ọpọ agbofinro ni ẹnu yoo ya lati gbọ pe oun ti wọn ni oun ti ku lo si wa laaye lonii.
"Baba mi jẹ gbajumọ ẹda ati ologun to n lọ lati agbegbe kan si omiran yika orilẹede yii.

Oríṣun àwòrán, Wikipedia
Lọna ati gba agbara okunkun, ibi mọkanlelogun ni mo lọ, lara wọn ni Minna nipinlẹ Niger ati oro nipinlẹ Kwara."
"Mo wa nilu idanre nipinlẹ Ondo fun ọjọ mọkanlelaadọrun, nibi ti wọn ti ni ki n maa mu ọmu obinrin kan gẹgẹ bii ounjẹ ati omi, ki agbara okunkun le wọnu ara mi.
Lẹyin o rẹyin, mo ni agbara okunkun ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹwa ati ẹyọ kan, 901, eyi ti mo n lo lati maa poora lasiko ti mo ba huwa ọdaran, tabi sọ ara mi di ẹlomiran.
Ti wọn ba pa mi nibikan, mo ni agbara lati ji dide, ki n si tun fara han ni ibomiran."

Oríṣun àwòrán, NAN
Amọ iroyin naa ni Rambo wa kabamọ, to si n fi ika hanu lori awọn iwa aidaa to hu naa eyi to fi da orilẹede Naijiria joko fun ọpọ ọdun, to si ni awọn ẹmi aimọ lo faa.
Rambo ni ni kete ti oun fi aye oun fun Jesu ni ẹmi Ọlọrun wọ inu oun lọ, to si pasẹ fun oun lati jọwọ gbogbo agbara okunkun naa ati iwa buruku, ki oun si maa waasu .
O ni oun ti jere ọkan pupọ fun Ọlọrun lati ipasẹ iwaasu ti oun n se, ti oun si tun ti da ọpọ ile ijọsin silẹ pẹlu.
Ogbontagi adigunjale tẹlẹ naa ni ohun ti oun kabamọ julọ ni iku aya oun ati ọmọ mẹta, ti awọn to wa mu oun, amọ ti wọn ko ba opun pa.
Shina Rambo wa parọwa sawọn eeyan to si n huwa ọdaran lati jawọ, ki wọn si ronupiwada, ki ibinu Ọlọrun ma baa de ba wọn.














