Florence Ajimobi: Àwọn Káfíńtà ti kó igi dé láti tún òrùlé ilé ìtajà tó jóná ṣe

Ibudo itaja aya Ajimobi

Awọn agba ni ọjọ taa ba ri ibi, ni ibi n wọ ilẹ, ohun to ba si ti ya kan, kii tun pẹ ms.

Eyi lo mu ki aya gomina ana nipinlẹ Oyo, Florence Ajimobi tete pakiti mọlẹ lati se atunse ibudo itaja rẹ to jona.

Bẹẹ ba gbagbe, alẹ ana la mu iroyin wa fun yin pe abala kan lọwọ ẹyin ibudo itaja aya Ajimobi naa, Grandex, to wa ladugbo Bodija nilu Ibadan gbina.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba ti ikọ iroyin BBC se abẹwo sibudo itaja naa loni, a se akiyesi pe aayan ti n lọ lati se atunse abala ile itaja to jona naa.

Ikọ iroyin BBC Yoruba kofiri awọn Kafinta ti wọn ti ra igi da silẹ lati tun orule to jona kan, to si seese ki isẹ atunse naa bẹrẹ lọla.

Iná ṣẹ́yọ nílé ìtajà aya Ajimobi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó jáde opó

Aworan iyawo Ajimobi

Oríṣun àwòrán, oyoinsight.com

Saaju la ti sọ fun yin pe, ina nla kan ti ṣẹyọ to si ṣakoba fun ọpọ dukia ni ile itaja iyawo Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, arabinrin Florence Ajimobi.

Ile itaja igbalode taa n sọ yi ni Grandex Supermarket to wa ni agbegbe Bodija nilu Ibadan.

Iṣẹlẹ yi to se awọn eeyan ni haa, waye lẹyin ọjọ mẹta ti Arabinrin Florence jade ile opo iku ọkọ rẹ, Sẹnẹtọ Abiola Ajimobi .

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ina naa ṣadede ṣẹyọ lọsan ọjọ Aiku lati ọwọ ẹyin ile itaja naa ti ko si pẹ to fi ran kaakiri.

Titi di igba ta fi n ṣe akojọ iroyin yi, a ko ti fidi ọrọ mulẹ lori ohun to fa ina naa.

Ajimobi

Oríṣun àwòrán, @aishambuhari

Florence Ajimobi jáde ilé opó lẹ́yìn ọjọ́ 140 tí ọkọ rẹ̀ jáde láyé

Aya gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Abiola Ajimobi to ti di oloogbe bayii, Florence Ajimobi ti jade ile opo lẹyin ogoje ọjọ.

Abiola Ajimobi papoda lọjọ karundinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2020 nile iwosan aladani kan nipinlẹ Eko, lẹyin to lugbadi arun Covid-19.

Lẹyin iku rẹ ni aya rẹ ọhun wọle opo ologoje ọjọ gẹgẹ bi ilana ẹsin Musulumiṣe gbe kalẹ.

Nigba ti wọn n sọrọ lẹyin ti aya gomina tẹlẹri ọhun jade ile opo, ẹgbẹ awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC baa ṣajọyọ, wọn si tun kii ku oriire.

Ajimobi

Oríṣun àwòrán, @vanguardngrnews

Ninu atẹjade ti awọn obininrin na fi lede, wọn ki aya Ajimobi ku irọju ati afarada lẹyin iku ọkọ rẹ.

Atẹjade naa ti olori awọn obinrin ẹgbẹ APC ipinlẹ Oyo, Mabel Williams ati igbakeji rẹ, Toyin Ajibade buwọlu ki Florence Ajimobiu ku irọju.

Wọn ni "a ti gba f'Ọlọrun pe olori ati aṣiwaju wa ti dagbere faye, a si n fi akoko yii ṣeranti rẹ."

"A si fẹ fi akoko yii sọ fun aya olori wa, iyẹn, Florence Ajimobi pedigbi ni a wa lẹyin lọjọ gbogbo."