Yoruba movie: Ẹ wo ohun tí mama Ire, Toyin Abraham ní òun yóò máa fi ìyókù ọdún yìí ṣe

Oríṣun àwòrán, Instagram/Toyin Abraham
Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba ati ede gẹẹsi lorilẹede Naijiria, Toyin Abraham ti sọ fun awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn ma reti sinima kankan latọdọ rẹ mọ titi ọdun yii yoo fi pari.
Toyin fi sita pe ootọ ni oun n sọ pe "emi, Olúwatóyìn Dàda Abọ́sẹ̀dé aya Kọ́láwọlé Ajéyẹ́mí ti de gongo mo si ti kọja ala to yẹ ki n de ninu gbigbe sinima agbelewo jade".
Toyin Abraham ni ohun to ku oun ku ni lati tun dara ju Toyin ọdun to kọja ati ti atijọ ti ẹ mọ lọ.
Gbajugbaja oṣere yii to ṣẹṣẹ gbe sinimaa "Fate of Alakada" jade tawọn ololufẹ rẹ si n bo o witiwiti ni sọ pe oun ko le bo ore Ọlọrun mọra.

Oríṣun àwòrán, Instagram
O ni bo tilẹ jẹ pe ọdun yii, bii ere ori itage lo jẹ pẹlu bi wọn ko ṣe jẹ ki awọn eeyan wọ ile fiimu lọpọ lati joko pọ wo sinima oun tori ajakalẹ arun COVID-19, nigba to tun ya, Iwọde ifẹhonuhan ni Naijiria naa tun wa pẹlu ipa tirẹ ati ọsẹ ṣugbọn o ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun atawọn ololufẹ rẹ.
O ni awọn dojukọ awọn iṣoro kan bii ni Ilorin, Surulere, ati Jakande ti wọn ti ba awọn ile fiimu jẹ lasiko iwọde ifẹhonuhan to waye laipẹ yii.
Toyin mu iranti wa pe ere ti oun gbe jade ri ti pa miliọnu mẹtadinlọgọrin ti oun si ti wa pa ju bẹẹ lọ bayii o si mu inu oun dun.
Ọrọ yii fẹ dabii ọrọ ikini ni ayẹyẹ ipari ọdun pẹlu bi Toyin Abraham ṣe n dupẹ lọwọ ololufẹ rẹ to di olubadowopọ fun un ninu ere titata to si tun dupẹ lọwọ awọn olubadowopọ gangan to ni wọn ti di mọlẹbi.
O fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe oun yoo tẹsiwaju lati maa polowo ere toun ṣe gbẹyin, oun yoo maa gbe fidio ipade oun atawọn ololufẹ oun jade atipe bi sinima toun ti ṣe ri ba lee pa miliọnu mẹtadinlọgọrin, a jẹ wipe ọrọ yii kuro ni keremi.
Wo díẹ̀ lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe ní èwe.

Oríṣun àwòrán, @Nations
Àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe ní èwe.
Kii ṣe diẹ ni awọn oṣere Yollywood Yoruba, to bẹrẹ ere ṣíṣe lati igba ti wọn ti wa ni ọmọde.
Bo tilẹ jẹ pe awọn kan ninu wọn ko fi isẹ tiata jẹun mọ, àwọn to ku mu ayipada wọ isẹ wọn, ti wọn si ti di gbajugbaja ju ti igba ewe wọn lọ.
Diẹ lara wọn niyii:
1) Funke Akindele
Gbajugbaja oṣerebinrin Funke Akindele-Bello, bẹrẹ ere ṣíṣe nigba to wa ni ọdọ langba.
Ọdun 1998 lo bẹrẹ ere ṣíṣe, ninu ere onise kan, I need to know. O ko ipa Bisi, ro jẹ akẹkọọ ileewe girama, ti ori rẹ pe.
Sugbọn ni ọdun 2009 ni ogo rẹ bu jade daadaa fun ipa to ko ninu sinima Jenifa.
Lati igba naa lo si ti n tayọ nidi sinima sise, to si jẹ ọkan lara awọn ti ko ṣe e fi ọwọ rọ sẹyin.

Oríṣun àwòrán, @Nations
2) Samuel Olasehinde
Ọmọ agba osere, Kayode Olasehinde 'Ajirebi', ni Samuel.
Asiko to wa ni èwe lo bẹrẹ ere ṣíṣe. O si jẹ gbajugbaja nigba naa, fun awọn ipa to ma n ko, paapaa gẹgẹ bi ọmọ líle.
3) Khabirat Kafidipe:
Ọdun 1999 ni Khabirat bẹrẹ isẹ sinima sise, lasiko to ko ipa Araparegangan ninu gbajugbaja sinima 'Saworo Ide'.

Oríṣun àwòrán, others
O si ti ṣe ọpọlọpọ sinima lẹyin rẹ.
Ni bayii, òun naa ti di oludari ati olootu ere sinima Nollywood
- Oyinkan Abayomi, akọni obìnrin tó fi ìfẹ́ pa orúkọ ọkọ kejì dà sí ti ọkọ àárọ̀
- Ẹkún àti ìbànújẹ́ láwọn mọ̀lẹ́bí fi sìnkú ọmọ méje ní Kumba, Cameroon lónìí
- Wo ìgbà márùn ún tí Buhari ti rìnrin àjò lọ sókè òkun fún ìtọ́jú ara rẹ̀
- Wo àwọn ọmọ Naijiria mẹ́ta tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sílé aṣòfin ilẹ̀ Amẹrika
- Bí àwọn kan tí ń ní àtimọ̀lé tí wọ́n sọ olorin Nazir sí ní Kano ni ọwọ́ kan òṣèlù ní àwọn mii ní...

















