Babajide Sanwo Olu, El Rufai: Mo ṣetán láti dojú ìjà kọ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ bá ọ̀rọ̀ ajé Eko jẹ́- Sanwo Olu

Sanwoolu

Oríṣun àwòrán, @Lagosgovt

Mo ṣetán láti dojú ìjà kọ àwọn tó fẹ ba ọrọ ajé Èkó jẹ

Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko tí seleri lati koju gbogbo awọn to ba n gbero lati tẹ oju ọrọ aje Eko mọlẹ.

O fidi ọrọ yi mu'lẹ lasiko to n gba akẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Kaduna Nasir El-Rufai lalejo ni ile ìjọba.

Sanwo olu

Oríṣun àwòrán, @Lagos govt

Sanwo-Olu ni ijọba oun n wa gbogbo ọna ajọṣepọ ti yoo mu ki ipinlẹ Eko gberasọ padà.

Bakan naa lo salaye pe: ijọba ko ni yẹ lati ri pe ayé ko gba gbogbo awọn to ba fẹ ba eto ọrọ aje ipinlẹ naa jẹ.

O ni toun ti gbogbo rogbodiyan to tẹle iwọde ENDSARS oun ṣetan lati fidi idajọ ododo rinlẹ fun awọn to farakasa ijiya eyikeyi lọwọ àwọn ọmọ ikọ SARS

Sanwo olu

Oríṣun àwòrán, @Lagos govt

Ninu ọrọ tirẹ Gomina Kaduna Nasir El-Rufai ni omije fẹ lè máa bọ loju oun nigba toun ri akoba t'awọn janduku ṣe ni Èkó.

O ni ara wọn ni awọn to ba nkan ilu jẹ da loro ati pe bopẹ boya wọn yóò jèrè àkóbá ti won ṣe.

"A o ṣe gbogbo nkan ti ipinlẹ Eko ba nilo ká ṣé ni iranwọ lati le gbe Eko dide pada"

Àkọlé fídíò, Orlando Owoh: Èmí àti Oladipupo Owomoyela jọ lọ ẹ̀wọ̀n Alágbọn- Caroline Owoh, aya Orlando