Ẹkún àti ìbànújẹ́ láwọn mọ̀lẹ́bí fi sìnkú ọmọ méje ní Kumba, Cameroon lónìí

Oku omode Cameroon

Oríṣun àwòrán, Joel Kouam

Ẹkun oun ibanujẹ l'awọn molebi fi n sinku awọn ọmọ wọn meje to kagbako iku ni ilu Kumba lorile-ede Cameroon.

Ninu ibanujẹ yi naa ni wọn tun kesi ijọba lati fidajọ ododo mulẹ lori iku awọn ọmọ yi.

Lọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa ni awọn agbebon ṣina bo'lẹ ti wọn pa ọmọdé meje t'awọn mejila miran si farapa ni ile ẹkọ Mother Francisca International Bilingual Academy, Fiango Kumba, ni iwọ oorun guusu

Cameroon.

Ijọba orileede naa lo ṣeto isinku awọn ọmọ yi ti olootu ijọba Joseph Dion Ngute si soju Aarẹ Biya níbẹ.

Ṣaaju isinku lawọn mọlẹbi ke gbajare pe ki ijọba wadii awọn to sẹku pa awọn ọmọ wọn.

"Inu ibanujẹ la wa ni mọlẹbi mi,igba yi buru púpọ fún wa" ni oun ti Nzakame Julius sọ lasiko to n sin oku ọmọ rẹ Nzakame Rema to jẹ ọmọ ọdún mọkanla.

Iku awọn ọmọde ni Cameroon

Oríṣun àwòrán, Joel Kouam

"Mo máa ṣe afẹri imoran ti Rema maa n gba mi pe ki n yago fun ọti mimu ki n si maa lọ si ile ijọsin deede.

Ọmọ yẹn jẹ olubẹru Ọlọrun. O mọ Ọlọrun ju mi lọ"

Pasitọ Victor Camibon naa to padanu ọmọ rẹ ni oun ko ni gbagbe bi "o ti ṣe maa n lu ilu ninu ijọ ti a si maa ba wa ṣi ferese ile ijọsin wa"

Iku awọn ọmọde ni Cameroon

Oríṣun àwòrán, Evelyne Metuge

Ajọ ajafeto-omoniyan, Human Rights ti kesi ijọba Cameroon la ti ṣe iwadii tó tọ ki wọn si fi iya jẹ awọn to lọwọ ninu ipaniyan to waye ni Kumba.

Wọn fi kun un pe ki won gbe awọn akọṣẹmọṣẹ oniwadii wa lati UN ati AU ki ọrọ naa ba le yanju.

Ileewe Kulu Memorial comprehensive College.

Oríṣun àwòrán, @Agborem

Àwọn agbébọn kọlu iléèwé, wọn bọ́ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ sí ìhòhò

Cameroon students killing: Àwọn agbébọn bíi ogún kọlu iléèwé, wọn bọ́ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ sí ìhòhò

Àwọn agbébọn kọlu iléèwé, wọn bọ́ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ sí ìhòhò

Ọkunrin agbebọn bi ogún lo kọlu ileewe girama Kulu memorial comprehensive, to wa ni Gusu orilẹ-ede Cameroon.

Ni ṣe ni awọn agbebọn naa pasẹ fun awọn olukọ ati akẹkọọ, lati bọ ara wọn si ihoho, ki wọn si sa asala fun with ẹ̀mí wọn.

Ikọlu yii waye lẹyin ọjọ kan ti ikọlu kan waye nileewe P S Kumbo. Olukọ mọkanla lo ṣi wa ni ihamọ ajinigbe.

Koda, ọjọ mọkanla lẹyin ti wọn pa ọmọde meje ni Kumba, ni iṣẹlẹ naa waye.

Ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ni nkan bi aago mẹjọ aabọ owurọ ni ikọlu tuntun yii waye, nigba ti awọn agbebọn wọ inu ileewe naa, ti wọn si pàṣẹ fun olukọ ati akẹkọọ láti bọ aṣọ wọn.

Lẹyin naa ni wọn ko awọn iwe kika àti iwe ẹri jade ni ibi ti wọn ko wọn si, wọn si dana sun wọn.

Àkọlé fídíò, Orlando Owoh: Èmí àti Oladipupo Owomoyela jọ lọ ẹ̀wọ̀n Alágbọn- Caroline Owoh, aya Orlando

Bakan naa ni wọn kọlu ọfiisi Ọga Agba ileewe naa, ati ti awọn olukọ.

Awọn alasẹ ileewe naa sọ fún bbc Pidgin pe wọn ko ji ẹni kankan gbé.

"Sugbọn wọn da epo bẹtiro si wọn lara, wọn si tun fi wọn ẹ̀sín."

Ikọlu naa ni ìkẹta to waye si awọn ileewe laarin ọsẹ meji pere, lasiko ti awọn ajijagbara n gbe igbesẹ lati fi opin si eto ẹkọ ni agbegbe ti wọn ti n sọ èdè Gẹẹsi lorilẹ-ede Cameroon.

Ọdun 2016 ni rogbodiyan bẹrẹ ni agbegbe naa.

Akọsilẹ ajọ isọkan agbaye fihan pe ẹgbẹrun lọna ẹgbẹ̀ta ọmọ ni ko ti i le lọ sileewe.

Nise ni àwọn ajijagbara ti ji ọpọlọpọ olukọ gbé, wọn lu wọn, wọn si tun pa àwọn kan.