Nigeria Brazil loan: Wo bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe n kí fún ìjọba nítorí $1.2bn Naira tó fẹ́ ẹ yá lọ́wọ́ Brazil

Buhari

Oríṣun àwòrán, Nig Presidency/ Getty

Ìkéde ìjọba Nàìjíríà láti yá owó lọ́wọ́ Brazil fa awuyewuye

Àwọn ọmọ Naijiria n binu lori ayelujara nitori bi ìjọba ṣe fẹ ẹ ya owo lọwọ ijọba Brazil.

Laipẹ yii ni ijọba orilẹ-ede Naijiria sọ pe oun fẹ ẹ ya owo to le ni biliọnu kan Dọla, $1.2bn, lọwọ orilẹ-ede Brazil, lati fi gbọ bukaata isẹ agbẹ ninu eto isuna ọdun 2021.

Minisita fun eto inawo, eto isuna, ati eto ilu, Zainab Ahmed, lo sọ eyi nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn aṣofin.

O ṣalaye pe awọn ti fi iwe ránṣẹ si awọn aṣofin lati buwọlu owo naa ni yiya.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa lórí BBC Yorùbá: Mọ̀ síi nípa ẹ̀kún ìyàwó níbí

O ni wọn o lo lara owo naa lati ra ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeka ilẹ ni ipinlẹ kọọkan fun ipese oúnjẹ.

Okwute

Oríṣun àwòrán, @Okwute

Ikede igbesẹ yii ti mu ki awọn ọmọ Naijiria o ma a ṣọ ọrọ kobakungbe si ijọba l'ori owo to fẹ ẹ ya lọwọ Brazil ti 'ipo rẹ ko yatọ si ti Naijiria'.

Yentown

Oríṣun àwòrán, @YawngBoss

Ẹnikan ti ẹ kọ iwe ránṣẹ si ijoba Brazil "lati ma a ya ijọba Naijiria lowo kankan, nitori pe awa ọmọ orilẹ-ede ko nilo owo yiya.

Gabriel

Oríṣun àwòrán, @Gabriel

A ni nkan alumọọni to pọ... mi o si lero pe a ti san eyi ti a ya lọwọ China".

Adeyemi

Oríṣun àwòrán, @Adeyemi

Ẹlomiran sọ pe "ki ẹnikẹni to ba mọ ijọba Brazil bẹ wọn lati ma ya Naijiria lowo, nitori pe wọn n fi àwọn ọmọ ti mi o ti i bi sinu gbẹsẹ".

Patrick

Oríṣun àwòrán, @Ifeanyi

Folsmith ni ti ẹ sọ pe "ti ao ba ti ri owo da pada fun Brazil, ki wọn o ya a gbẹsẹ le ẹgbẹ agbabọọlu wá".

Endswat

Oríṣun àwòrán, Ifeanyin

Àkọlé fídíò, Orlando Owoh: Èmí àti Oladipupo Owomoyela jọ lọ ẹ̀wọ̀n Alágbọn- Caroline Owoh, aya Orlando