Ibadan: Oluwapọ̀nmile sọ ìrírí rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn sójà tó fìyàjẹ́ ní Ibadan
Arakunrin Ẹmiọla David Oluwapọnmile ṣe alabapade ikọ ologun "Operation Burst" ni agbegbe Bẹẹrẹ nilu Ibadan ti wọn si fi abẹ ṣekele fa irun ori rẹ.
Iredi ti ikọ naa fi ṣe bẹẹ ni ko si han si ẹnikẹni titi di asiko yii.
Oniṣowo ni Ẹmiọla, bakan naa lo si jẹ agbẹ ọlọsin adiyẹ.

Ninu ọrọ ti o ba BBC Yoruba sọ, o ni ile ijọsin ni oun ti n bọ l'ọjọ aiku ti oun si pada ikọ ologun "Operation Burst" ni agbegbe Bẹẹrẹ nilu Ibadan.
O tẹsiwaju pe oun ti fẹ gun ọkada ki ọkan ninu awọn ikọ naa to ke si oun wi pe oun ni ẹjọ lati jẹ.
Ẹmiọla kọkọ fẹ ṣe agidi ṣugbọn ibọn ti awọn ikọ naa gbe lọwọ ko ṣee yaju si.

Nigba ti yoo fi de ọdọ ẹni to pee, ẹsun ti wọn fi kan an ni pe irun to gbe si ori ti kun ju.
Ere ni, awada ni, Ẹmiọla ṣe alaye wi pe ọrọ to jade lẹnu awọn ikọ ologun naa ni pe, "Kaabọ si ibi ti a ti n fa ori fun awọn ọmọ alaigbọran".
- Ta ni Wolii Olapade Agoro tó re ibi àgbà ń rè tí ayé ń pariwo rẹ̀ yìí?
- Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ní Oyigbo lẹ́yìn tí ọlọ́páà mẹ́ta àti sọ́jà kú nínú rògbòdìyàn EndSARS
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Ta ni Wolii Olapade Agoro tó re ibi àgbà ń rè tí ayé ń pariwo rẹ̀ yìí?
Lẹyin-ọrẹyin wọn fi abẹ ṣekele ṣe irun rẹ baṣabaṣa wọn si tun fi ipa gba ẹẹdẹgbẹta naira lọwọ rẹ gẹgẹ bi i owo irun ti wọn baa fa.
Ẹmiọla fi kun ọrọ rẹ pe oun tun ba awọn ẹlomii ni akata awọn ikọ ologun yii ti oun si tun ni lati san owo irun wọn naa pẹlu nitori wọn ti lu wọn gẹgẹ bi i ejo aijẹ nitori airi owo san.
Alaye mii ti Ẹmiọla ṣe fun BBC Yoruba ni pe awọn ikọ yii tun lu obinrin ni agbegbe Ogunpa nilu Ibadan nitori pe aṣọ to wọ ko tẹ wọn lọrun.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Igbe to Ẹmiọla fi ta ni ori itakun ayelujara lo mu ki okiki iṣẹlẹ naa kan kaakiri.
Eyii lo mu ki ijọba ipinlẹ Ọyọ kan sii nipasẹ alamọran pataki fun gomina Ṣeyi Makinde lori ọrọ awọn ọdọ.
Nibayii, kele ofin ti gbe awọn aṣoju ikọ "Operation Burst" ti wọn fi ẹsun kan.
Adari ikọ naa, Captain Usolo lo kede rẹ lọjọ Aje lẹyin ti o tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan ti wọn yanjẹ.














