EndSars Protest: Wo awọn iroyin manigbagbe to waye ni ọsẹ yii

Endsars

Oríṣun àwòrán, Google

Ọpọlọpọ iroyin manigbagbe lo ti waye lọsẹ yii kaakiri orilẹede Naijiria, paapaa lori jagidijagan to waye lẹyin ifẹhọnuhan tako bii ọlọpaa ṣe n fi iya jẹ awọn eniyan ti o ba ti bọ si ọwọ wọn.

Lara awọn iṣẹlẹ to mi ilu titi to waye ni ọṣẹ yii naa ni bi minisita fun ọrọ ịṣẹ ati ibugbe, Fashola ṣe ṣọ wi pe ohun ri fidio bi iṣẹlẹ ipaniyan to waye ni Lekki toll gate ṣe ṣẹlẹ.

Bakan naa ni awọn to ji ohun ini ijọba gbe ati awọn ohun amayedẹrun fun ajakalẹ aarun Coronavirus naa ti bẹrẹ si ni da pada, lẹyin ti ijọba halẹ mọ wọn.

Lọsẹ yii naa ni ileeṣẹ ologun ni Naijiria kede wi pe Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Fashola lo ran awọn lọ si Lekki Toll Gate lati lọ koju awọn afẹhọnuhan to wa nibẹ.

Awuyewuye naa ṣi n lọ lọwọ lori boya awọn janduku ti da ọpa aṣẹ ọba ilu Eko pada abi bẹẹ kọ.

Ṣe Lootọ ni Minisita Babatunde Fashola ri fidio ipaniyan ni Lekki Tollgate?

Ọkan lara awọn iroyin to mi ilu titi ni ọsẹ yii ni Minisita fun ọrọ iṣẹ ati ibugbe, Babajide Fashola sọ wi pe oun ri fọnran to safihan ikọlu to ṣẹlẹ ni Lekki nigba ti awọn n kaakiri ibi iṣẹlẹ naa.

Fashola lo sọ eyi lasiko ti oun ati awọn gomina ni iwọ -oorun Naijiria n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori ipaniyan ti awọn ologun ṣe si awọn afẹhọnuhan ni Lekki.

Fashola ni ohun aṣọ ti wọn fi n nu oju ni ohun fi mu ẹrọ amohunmaworan naa nilẹ, ti oun si fun Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria to fesi si ọrọ Fashola yii lo fi ṣe yẹyẹ, ti wọn si fi dapara lori ẹrọ ayelujara pe irọ patapata ni ọrọ naa.

Ọdun 2007 si 2015 ni Fashola jẹ gomina nipinlẹ Eko, ki Aarẹ Muhammadu Buhari to fun ni ipo minisita ni ọdun 2015, to si ti wa ni saa keji bayii.

Gomina Sanwo-Olu lo ran w anise lati lo doju ko awon afehonuhan Lekki Tollgate - Iko Omoogun Naijiria

Awuyewuye bẹ silẹ lọsẹ yii lẹyin ti ikọ ọmọogun Naijiria ke sita wi pe gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu gan an lo wa nidi iṣekupani to waye ni Lekki.

Ikọ ọmọogun ni kii ṣe ijọba apapọ lo pe awọn lọ si Lekki, amọ gomina ipinlẹ Eko fun ara rẹ lo ni ki awọn lo doju kọ ẹnikẹni to ba rufin igbele rẹ ti ijọba pariwo lati dẹkun rogbodiyan to suyọ ni ifẹhọnuhan EndSars.

Ninu ọrọ tirẹ, Sanwo-Olu ni oun ko ran wọn lati lọ pa awọn eniyan, amọ ki wọn jẹ ki alaafia jọba lorilẹede Naijiria.

Amọ, ikọ ọmọogun ni ko si otitọ ninu ọrọ ti Sanwo-Olu sọ, ati wi pe awọn ko pa ẹnikẹni ni Lekki Tollgate.

Ẹwẹ, titi di asiko yii iwadii ṣi n lọ lori iye eniyan to ku ninu iṣẹlẹ Lekki ati ohun gangan to mu ki awọn soja da ibọn bo araalu.

Araalu da awọn ohun ini ijọba ti wọn jigbe pada lasiko ifẹhọnuhan EndSars

Rogbodiyan bẹ silẹ kaakiri orilẹede Naijiria lẹyin ti awọn ologun pa awọn afẹhọnuhan ni Lekki tollgate ti wọn pẹ fun opin si ikọ ọlọpaa Sars lorilẹede Naijiria.

Kaakiri orilẹede Naijiria ni awọn janduku ti lọ jo ileeṣẹ ọlọpaa, ti wọn tun lọ si ibugbe ikohunpamọsi, ti wọn si ko awọn nkan elo ounjẹ iranwọ fun aarun Coronavirus, ti ijọba fẹ pin fun awọn eniyan.

Bi awọn kan ṣe n gboriyin fun awọn to hu iru iwa yii naa ni awọn kan n bu ẹnu atẹ lu wọn.

Eleyii lo mu ki awọn ijoba ipinlẹ fun awọn eniyan ni gbedeke lati da awọn ohun ini ti wọn ji gbe pada, lai jẹ bẹẹ awọn yoo ma a ya ojule si ojule lati fi panpẹ ọba mu awọn ti wọn ba ba awọn ohun ini wọnyii ni ile wọn.

Kiakia ni awọn eniyan ti n da awọn ohun ini yii pada ni awọn ilu bii Adamawa, ipinlẹ Eko, Oyo, Osun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣe lootọ ni ọpa aṣẹ Ọba ilu Eko ti pada si afin?

Ọpọlọpọ iroyin lo ṣi n ja ranyin nilẹ lori ọpa aṣẹ ọba ilu Eko, Ọba Rilwan lẹyin ti awọn janduku ṣekọlu si aafin rẹ, ti wọn si gbe ọpa aṣẹ rẹ lọ.

Awọn eniyan ati lọbalọba lo ti n kesi awọn janduku naa lati da ọpa aṣẹ pada ki oju wọn ma ba ri ibi.

Amọ, iroyin ti a ko le fi idi rẹ mulẹ sọ wi pe wọn ti da ọpa aṣẹ pada lẹyin ti Ọba Akiolu pada si afin.

Bakan naa ni awọn ọba alaye sọ wi pe wọn yoo gbe ẹbọ, ti wọn yoo si ṣe etutu lati da ọba pada si aafin nitori awọn janduku naa ti balẹ jẹ.

Amọ, ohun ti Ọba Akiolu sọ nigba to sa kuro laafin ni wi pe oun ko pada si ibẹ mọ,oun lọ si Banana Island, ni Ipinlẹ Eko, titi ti ohun gbogbo yoo fi pada sipo.