Electricity Tarrif: A kò tíì gbé àwọn oníbàrà wa sórí tàríìfù tuntun - IKEDC

Prepaid Meter

Oríṣun àwòrán, @EKEDP

Ileeṣẹ apinaka ni ipinlẹ Eko, Ikeja Electric Distribution Company, IKEDC, ti sọ pe awọn ko tii bẹrẹ si ni gba idiyele owo ina tuntun lọwọ awọn onibara wọn.

Alukoro ileeṣẹ naa, Felix Ofulue lo kede bẹẹ ninu ofọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.

O ni "Niwọn igba ti a ko tii gba aṣẹ lọwọ ajọ to n ṣakoso ileeṣẹ wa, a ko lee bẹrẹ si ni gba owo ina tuntun ọhun lọwọ awọn eeyan."

Ofuleue sọ pe iye owo ti awọn eeyan n san lọwọ yii naa ṣi ni iye ti wọn n san tẹlẹ ki wọn to gbe aba idiyele owo tuntun naa jade."

Ni ti awọn onibara wọn ti iye ina ti wọn n ri gba kò tó ti iye owo ti wọn san, o ni o ṣeṣe ki irufẹ awọn eeyan bẹẹ ti jẹ gbese ina tẹlẹ ki wọn to gba mita ti wọn n lo.

ina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aadota odun ree ti e ti n paro atunse ise yin fawon omo Naijiria lero awon kan

O ni ileeṣẹ awọn yoo kọkọ yọ iye owo gbese ti irufẹ ẹni bẹẹ jẹ tẹlẹ, ki wọn to fi iye owo to ku fun ni ina.

Ni ti iyatọ to wa ninu idiyele atijọ ati tuntun yii, Ofulue sọ pe awọn eeyan yoo maa san owo ina gẹgẹ bi wọn ṣe n lo ina si.

Bakan naa lo tu ṣalaye pe wọn pin isọri owo naa si ọna marun un eyii to pe ni "Band A, B, C, D ati E."

Ofulue ni awọn to wa ni isọri D ati E ko ni nipin ninu idiyele owo tuntun naa nitori akoko ti wọn fi n ri ina lo ko pọ to ti awọn to wa ni isọri A, B ati C.

Àkọlé fídíò, Tóo bá pá lórí, Mílíìkì sóyà àtàwọn ǹkan mẹ́ta yìí leè mú irun rẹ hù padà!

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iye wakati ti awọn to wa ni isọri D fi n lo ina lojumọ jẹ nnkan bii wakati mẹjọ, nigba ti awọn to wa ni isọri E n lo ina ijọba fun nnkan bii wakati mẹrin din diẹ.

Eyii to n tumọ si pe ninu idiyele tuntun naa, iye akoko ti eeyan fi n lo ina ni yoo ṣe odiwọn bi wọn yoo ṣe maa san owo ina si, eyii ko si ni nkan ṣe pẹlu iye owo ti wọn ra ina ọhun.

Àkọlé fídíò, Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá