Osun after protest: Mo pinu látí dá Iphone ti mo mú padà, ṣùgbọ́n ọlọpàá mú mi- Afurasí

Oríṣun àwòrán, Punch
Suliya Tajudeen, ẹni ogun ọdún kan to wà lára àwọn ènìyàn mẹ́rìndíláàdọ́rún ti wọ́n mú pé wọ́n ja sọọbu ti wọ́n sì kẹ́rù ní ìpińlẹ̀ Osun
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ sí àwọn oníròyìn ló ti sàlàye pé ọjọ́ ti òun ń pinu láti dá fóònù ti ó ń mú lásìkò ìwọ́de #EndSars ni àwọn ọlọ́pàá mú òun.
Tí ẹ ò bá gbàgbé, lásìkò ti àwọn jàndùkú ja ọ̀rọ̀ ìwọ́de ìfẹ́hónúhàn #EndSars gbà, lọ́jọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹwàá ti wọ́n si lọ n já ilé ìtajà ńla ni Osogbo.
- Wo ojú àwọn òṣèré yìí láì lo "Make-up" orí ìtàgé bó ṣe rí gẹ́lẹ́
- Wumi Toriọla ti sọ̀rọ̀ sóke láti fi idí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun àti ọ̀rẹ́ òun níjà
- Gómìnà Sanwo-Olu dẹ okùn ìséde l'Eko, ó gbé ìlànà tuntun jáde
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ṣèwúrí fáwọn ọlọ́pàá tó kúrò lójú pópó fún ọjọ́ márùn-ún
- Eyitayo Jegede gbé Akeredolu lọ síwájú ìgbìmọ̀ tó n gbọ́ ẹ̀sùn ìdìbò
Suliya ní òun kò si lára àwọn tó lọ já ilé ìtàjà ńla náà sùgbọ́n agbègbè náà ni òun wà nígbà ti rògbòdìyàn náà ṣẹlẹ̀.
" Mo lọ si agbègbè náà láti lọ bá aṣerunlóge mi lọ́jọ́ ti ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ nítori mo fẹ́ kún irun mi padà si dúdú, sùgbọ́n kò pẹ́ sí ìgbà ti mo dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, mó ri ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wọ́n ń sáré sí ibi ilé ìtàja ọ̀hún, mó tún gbọ́ ǹkan to jọ ìró ìbọ̀n, sùgbọ́n ko dámi lójú, gbogbo wa ni ẹru ba ti olúkálùkù sì sá àsálà fún ẹmi rẹ ni àyíka ilé ìtajà náà.
"Mí o le lọ nítori mo gbàgbọ́ pé àwọn tó wà ni ibẹ̀ le pa mí lára, nítori náà mo sá pamọ́, bi wọ́n ṣe n ja sọ́ọ̀bù, àwá kan náà sá pamọ́ nínú ọgbà náà, sùgbọ́n àwọn tọ́ ń já sọ́ọ̀bù ń lọ láti inú sọ́ọ̀bù kan si èkejì wọ́n si n ji ǹkan.
"Nígbà ti wọ́n de sọ́ọ̀bu ti wọ́n ti ń ta fóònù, wọ́n ji ọ̀pọ̀ fóònu, ìgbà náà ni Iphone méji jábọ́ ni ẹ̀gbẹ́ ibi ti mo dúró sí, mo kó méjèèjì pamọ́ sábẹ́ aṣọ mi, mo si lọlé.
"Ìpinu mi ni láti dá fóònù náà padà lọ́jọ́ kejì ti mo bá ti lọ si ọ̀dọ̀ aṣerulóge mi, sùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá ti tọpasẹ̀ fóònu náà wọ́n si mú mi.
Nígbà ti oníròyìn bèrè pé se ó lo fóònù náà o ní rárá àti pe irú iṣẹ́ wo ló n ṣe, Afurasi ọ̀hún ni òun kò tilẹ̀ mọ Iphone lò, ṣùgbọ́n òun fi síìmù òun sínú rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ òun fi ya fọ́tọ̀, àti pé iṣẹ́ olóṣó ni òun ṣe.
Nígbà ti wọ́n tun bèrè pé ṣé o darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọ́de #EndSars tẹ́lẹ̀, o ni rárá òun ko si lára wọ̀n rárá.
Gómínà Oyetola ṣàtúnṣe kónílé-ó-gbélé ní Osun

Oríṣun àwòrán, @GboyegaOyetola
Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti paṣẹ ki ofin konile o -gbele rọlẹ si nipinlẹ Osun.
Ninu atẹjade gba ọwọ Akọwe ijọba ipinlẹ Osun,Wole Oyebamiji lo fi lede pe gomina Oyetola ri bi awọn eniyan ṣe tẹlẹ ofin isẹde naa lo jẹ ki o fa ọwọ rẹ sẹyin.
Oyebamiji ni ofin isẹde naa ti kuro ni ọlọjọyipo si aago mẹfa aarọ si aago mẹjọ alẹ kaakiri gbogbo ipinlẹ naa.
''Awọn ẹṣọ alaabo yoo si wa nita lati ṣọ lilọ ati bibọ awọn eniyan ati bi wọn ṣe tẹle ofin si ''.
- Báyìí ni 50kobo ṣe dá ìfẹ̀hónú "Ali Must go" sílẹ̀ tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ lọ
- Bọ́ọ̀sì ìrìnà 106 tuntun yóò máa ná Ibadan sí Eko àtàwọn ìpínlẹ̀ míì - Seyi Makinde
- Wo ìdí tí orílẹ̀-èdè America ṣe tako ìyànsípò Okonjo-Iweala gẹ́gẹ́ bi olórí ajọ WTO
- Àkùkọ dojú ìjà kọ ọlọ́pàá, ikú ló já sí fún agbófinró
- Ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ déé fáwọn ọmọ Ọlọ́pàá tó kú lásìkò EndSARS, Gómìnà ìpìnlẹ̀ Eko kéde
''Awọn awakọ ati ọlọkada ko ni ṣiṣẹ ju asiko isẹde naa lọ, paapaa ti wọn ba kasẹ isẹde naa kuro nilẹ''
Gomina Oyetọla dupẹ lọwọ awọn araalu fun atilẹyin wọn lasiko yii titi alaafia yoo fi pada si ipinlẹ naa.
Bakan naa lo rọ awọn araalu lati mọ daju wi pe isẹde naa kii ṣe lati fi aye ni awọn eniyan lara, amọ ki alaafia le jọba ni.
Gomina ipinlẹ Osun naa fikun wi pe ẹnikẹni to ba si ni ẹru ti wọn ji sile rẹ yoo foju wina ofin nitori oni ni ayẹwo ojule si ojule yoo bẹrẹ.
Gómìnà Oyetola: Kò sí àfikún ọjọ́ ìdáríjì fáwọn jàndùkú tó jí ohun iyebíye gbé lọ nípinlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, @GboyegaOyetola
Gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola ti ni oun ko ni ṣe afikun ọjọ idariji fun awọn janduku to gbe ohun ini ijọba lọ lati da pada.
Gomina ipinlẹ Osun fi ikilọ yii lede lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ile ijọba ni ilu Osogbo.
Oyetola ni oun fun wọn di Ọjọọru lati da awọn ohun ini naa pada ati ti awọn eniyan ni awọn janduku naa ko lọ.
O ni ẹnikẹni ti ko ba da awọn ohun ti wọn jigbe lọ pada, yoo foju wina ofin.
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Osun naa gboriyin fun awọn to ti wa da oun ini ti wọn jigbe lọ pada si iwaju ile ijọba ni ipinlẹ Osun.
O ni ọpọlọpọ awọn ohun ini ti awọn eniyan ti da pada ti le ni miliọnu meji naira.
'' A dupe lọwọ ikọ Amọtẹkun, ikọ ọlọpaa ati awọn ẹsọ alaabo ti wọn ri daju wi pe wọn gba awọn ohun ini yii pada''.
'' Mo ti paṣẹ ayẹwo ojule si ojule fun awọn ikọ eleto aabo lati lo ma a wa awọn ohun ini ti awọn eniyan jigbe lọ yii pada''.
'' Inu mi dun pe awọn eniyan kọọkan ti n da ohun ti wọn jigbe lọ pada, amọ wọn gbọdọ da gbogbo rẹ pada ni kiakia.''
Ninu ọrọ tirẹ, adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Osun, Comrade Amitolu Shittu ni inu oun ko dun si bi awọn janduku ṣe yabo ileeṣẹ ijọba, ti wọn si ba awọn ohun ini awọn eniyan jẹ kaakiri.
Ti a ko ba gbagbe, lẹyin ifẹhọnuhan EndSars ni awọn janduku yabo ile igbe ounjẹ si ati ileeṣẹ ijọba ti wọn si ko awọn ohun ini ijọba lọ nipinlẹ naa.
Ohun lo mu ki gomina Oyetola wa paṣẹ ofin konile-o gbele ọlọjọyipo oni wakati mejilelaadorin, ki ohun gbogbo fi le pada sipo.
Wo àwọn ìpínlẹ̀ tí ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ojúlé sí ojúlé káàkiri Nàìjíríà torí ohun tí wọ́n jí kó

Iroyin kan n fo kaakiri pe Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ni awọn yoo bẹrẹ ayẹwo onile si ile lati lọ gba awọn ohun ini ti janduku ti jigbe lọ kaakiri ipinlẹ naa.
Ọpọ ileeṣẹ iroyin lo ti n gbe e ka pe ipinlẹ Ondo naa ti kun awọn ipinlẹ to fẹ funra wọn maa fi ọwọ ofin lọ gba nkan tawọn janduku ji ko.
Amọ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Tee-Leo Okoro sọ fun BBc Yoruba pe ko ri bẹẹ.
Tee-Leo Okoro ni awọn eniyan marundinlogun ni awọn ti fi panpẹ ọba mu kaakiri ipinlẹ Ondo, lẹyin ti awọn janduku ba ile ati dukia jẹ lasiko ifẹhọnuhan tako ifiyajẹni ikọ ọlọpaa Sars.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo naa fikun pe awọn ti wọn fi panpẹ ọba mu naa kii ṣe awọn afẹhọnuhan EndSars, amọ awọn janduku ni.
Bakan naa ni awọn ara ipinlẹ Yola ti bẹrẹ si ni da awọn ohun ini ti wọn ji pada lẹyin ti ijọba kede ayẹwọ ojule si ojule.
Lara awọn ohun ti wọn da pada ni ilu Adamawa ni ẹrọ ilọta, ẹya ara ọkọ, irẹsi, ikoko ọbẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹwẹ, ipinlẹ Osun naa ti fun awọn araalu ni gbedeke Ọjọọru lati ri wi pe wọn da gbogbo ohun ti wọn jigbe pada.
Gomina Gboyega Oyetola ni Ọjọbọ ni awọn yoo da ọlọpaa sita lati ma a wọ ojule si ojule lati fi panpẹ ọba mu awọn to ba ni ohun ini ti wọn ko fi owo ra si ile.















