Ondo Politics: Eyitayo Jegede gbé Akeredolu lọ síwájú ìgbìmọ̀ tó n gbọ́ ẹ̀sùn ìdìbò

Oríṣun àwòrán, Twitter/Eyitayo Jegede/Rotimi Akeredolu
Oludije fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, ninu idibo gomina ipinlẹ Ondo, to waye laipẹ yii, Eyitayo Jegede, ti pe ẹjọ tako iyansipo Gomina Rotimi Akeredolu.
Jegede gbe ẹjọ lọ siwaju igbimọ to n gbọ awuyewuye to ba ṣuyọ lẹyin eto idibo, nitori "awọn mago-mago, ihalẹ mọ ni ati rogbodiyan to waye lasiko idibo naa".
Gomina Akeredolu bori ni ijọba ibilẹ mẹẹdogun, ninu mejidinlogun to wa ni ipinlẹ Ondo, eyi to mu ko fi ẹyin Jegede janlẹ pẹlu esi ibo to pọ.
Akeredolu lo gba ibo ju bẹrẹ lati ijọba ibilẹ Akoko North West, Akoko North East, Akoko South East ati Akoko South West.
Awọn yoku ni Ile Oluji/Okeigbo, Owo, Idanre ati Ondo East.
Awọn ijọba ibilẹ ti PDP ti moke ni ijọba ibilẹ Ifedore, Akure North ati Akure South.
Amugbalẹgbẹ fun Jegede to ba BBC Yoruba sọrọ, Kunle, sọ pe awọn gbe igbesẹ yii lẹyin ọpọlọpọ ifarabalẹ.
O ni idajọ ile ẹjọ nikan ni yoo mu ki awọn gba pe bi nkan ṣe ri gan-an niyẹn.
"Ọrọ naa dabi ayo tita ni, asiko ọtọọtọ ni awọn to n ta ayo ma n mu olori ayo wọn jade."
O ni nibi ti ọrọ de duro yii, awọn ẹkọ ti Jegede kọ ninu eto idibo ọdun 2016, lo n ṣamulo bayii.












