Ondo State Election result 2020: INEC kéde èsì ìbò gómìnà níjọba ìbílẹ̀ méjìlá

Rotimi Akeredolu na ọwọ soke

Oríṣun àwòrán, @R_Akeredolu

Ajọ eleto idibo nilẹ wa, INEC, ti bẹrẹ ikede esi ibo gomina nipinlẹ Ondo bẹrẹ lati oru ọjọ Satide si Aiku.

Ibo kika naa, to bẹrẹ ni bii aago mejila aabọ loru ọjọ Aiku, ni alamojuto eto idibo gomina ni ipinlẹ Ondo, Ọjọgbọn Idowu Olayinka, tii se ọga agba fasiti Ibadan, ṣide rẹ.

Nigba to n ki awọn alẹnulọrọ ninu eto idibo naa kaabọ, Ọjọgbọn Olayinka ti ka esi idibo ijọba ibilẹ mẹẹdogun ninu mejidinlogun to wa ni ipinlẹ Ondo.

Awọn ijọba ibilẹ ti wọn kọkọ fi fi bẹrẹ naa ni Ifedore, Ile oluji/oke igbo, Irele ati Akoko North West.

Titi di asiko yii eyitayo Jegede ni meta nigba ti Akeredolu Rotimi ni mejila ninu ijọba ibilẹ mẹẹdogun ti wọn ti ka

Awọn osisẹ ajọ INEC

Ṣaaju, ninu ọrọ ikinni kaabọ rẹ, Kọmiṣọnna fajọ eleto idibo nipinlẹ Ondo, Oluwatoyin Akeju dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan to wa nikalẹ fun atilẹyin wọn, lati ri daju pe eto idibo naa kẹsẹ jari.

Alakoso apapọ fajọ eleto idibo to n bojuto ipinlẹ Ondo, Ọmọwe Ademola Ogunmola ninu ọrọ tiẹ, wa gboriyin fawọn oludibo, fun bi wọn se jẹ ki ileri ajọ INEC, lati se aseyọri kọja ohun to waye nipinlẹ Edo, di mimusẹ.

Ni kete ti eto kika naa bẹrẹ si ni awọn ijọba ibilẹ miran n wọle, yatọ si ti mẹrin to wa nilẹ saaju.

Eyitayo Jegede n ki awọ ololufẹ rẹ

Nigba ti yoo si fi di aago meji aabọ oru, ajọ INEC ti kede esi ibo nijọba ibilẹ mejila ninu mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo.

Awọn ijọba ibilẹ ti wọn kede naa ni Irele, Ile Oluji, Ondo East, Owo, Akoko North East, Akoko South West, Idanre, Akoko North West, Akure North, Akoko South East and Akure South.

Awn ijọba ibilẹ mẹfa yoku ti wọn ko tii kede ni Ondo West, Odigbo, Okitipupa, Ilaje, Ese Odo ati Ondo West.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu awọn esi ibo ti wọn kede naa, ijọba ibilẹ mẹta pere ni ẹgbẹ oselu PDP ti moke, nigba ti ẹgbẹ oselu APC jawe olubori nijọba ibilẹ mẹsan.

Awọn ijọba ibilẹ ti PDP ti moke ni ijọba ibilẹ Ifedore, Akure North ati Akure South.

Awọn ijọba ibilẹ ti APC ti moke ninu mẹsan to ti jawe olubori bayii ni, Akoko North West, Akoko North East, Akoko South East ati Akoko South West.

Agboola Ajayi

Oríṣun àwòrán, @AAjayiAgboola

Awọn yoku ni le Oluji/Okeigbo, Owo, Idanre ati Ondo East.

Deede aago meji oru ni ajọ INEC kede pe oun fẹ lọ rẹju diẹ naa lati sinmi, ti oun yoo si pada ni aago mẹsan owurọ ọjọ Aiku, lati kede awọn esi ibo to ku lawọn ijọba ibilẹ mẹfa.

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike