Mike Bamiloye ti Mount Zion fi ọmọbìnrin rẹ̀ kan ṣoṣo, Darasimi fún ọkọ nílùú Ibadan

Darasimi ati Oyor

Oríṣun àwòrán, Joshua Mike Bamiloye/instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ariwo ayọ tun sọ nile gbajugbaja osẹre ẹsin Kristiẹni, Mike Bamiloye, lasiko ti abigbẹyin rẹ, Darasimi, lọ sile ọkọ.

Ọjọ Ẹti ati Satide, ọjọ kẹsan-an ati ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ni ayẹyẹ igbeyawo naa waye nilu Ibadan.

Eto idana iyawo lo kọkọ waye, ti isin igbeyawo ati wẹjẹ-wẹmu si waye lọjọ Satide.

Bayii ni awọn ẹgbọn iyawo, idile wọn, ati ọmọ Alufaa ijọ Redeem, Leke Adeboye ṣe ro dẹdẹ fun ayẹyẹ naa

Oríṣun àwòrán, Joshua Mike Bamiloye/instagram

Àkọlé àwòrán, Bayii ni awọn ẹgbọn iyawo, idile wọn, ati idile ọmọ Alufaa ijọ Redeem, Leke Adeboye ṣe ro dẹdẹ fun ayẹyẹ naa

Diẹ lara aworan ayẹyẹ naa ti BBC Yoruba ri lori ayelujara fihan pe, o larinrin.

Igbeyawo Darasimi

Oríṣun àwòrán, @Gospel film

Aṣọ bi oriṣi mẹta ni tọkọtaya tuntun naa wọ fun eto idana naa, ti wọn si wọ kaba funfun ati kootu funfun lọ si ṣọọṣi lọjọ Satide.

Ijo ati ayọ ni baba ati iya iyawo, Mike ati Gloria Bamiloye fi sin Darasimi lọ sile ọkọ.

Oríṣun àwòrán, gospelfilmsng

Àkọlé àwòrán, Ijo ati ayọ ni baba ati iya iyawo, Mike ati Gloria Bamiloye fi sin Darasimi lọ sile ọkọ.

Aṣọ alarambara naa ko yọ awọn obi ati ẹbi wọn silẹ rara.

Oluwadarasinmi ati Lawrence

Oríṣun àwòrán, Mike bamiloye/facebook

Olorin Kristẹni, Lawrence Oyor ni ọkọ iyawo, to si jẹ ọmọ Oluṣọ Agutan Gomba Fortune to di oloogbe laipẹ yii.

Ninu fidio kan to ṣafihan awọn ẹgbọn iyawo, Damilola ati Joshua , to sọrọ nipa bi aburo wọn ṣe fi to wọn leti pe Lawrence dẹnu ifẹ kọ oun, awọn mejeeji sọ pe "iṣẹ iranṣẹ orin kikọ ni Lawrence wa a ṣe lọdọ wọn, lo gba ibẹ dẹnu ifẹ kọ Darasimi".

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

"Ọrẹ wa ni Lawrence o, amọ o gbe n kan gbẹyin wa.

Ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe irinajo naa jẹ adun lati ibẹrẹ pẹpẹ."

Oluwadarasinmi ati Lawrence

Oríṣun àwòrán, Mike bamiloye/facebook

Oluwadarasimi Mike-Bamiliye (gẹgẹ bi apeja orukọ rẹ) kẹkọ gboye ninu imọ ede Gẹẹsi ni fasiti Babcock, Naijiria.

Bayii ni baba ati iya iyawo, Mike ati Gloria Bamiloye ṣe fi idunnu jo nibi idana ọmọ wọn, Darasimi

Oríṣun àwòrán, Mike bamiloye/facebook

Àkọlé àwòrán, Bayii ni baba ati iya iyawo, Mike ati Gloria Bamiloye ṣe fi idunnu jo nibi idana ọmọ wọn, Darasimi

Ohun ni ọmọbinrin kan ṣoṣo ni idile Mike-Bamiloye, oun naa si jẹ oṣere Kristẹni bii ti baba rẹ, iya ati awọn ẹgbọn rẹ ọkunrin meji.

Asiko yii ni awọn obi ọkọ, ṣi oju iyawo ọmọ wọn wo.

Oríṣun àwòrán, Mike bamiloye/facebook

Àkọlé àwòrán, Asiko yii ni awọn obi ọkọ, ṣi oju iyawo ọmọ wọn wo.
Mike ati Gloria Bamiloye niyii to n rọ ojo adura le ọmọ wọn lori, boṣe n rele ọkọ

Oríṣun àwòrán, Mike bamiloye/facebook

Àkọlé àwòrán, Mike ati Gloria Bamiloye niyii to n rọ ojo adura le ọmọ wọn lori, boṣe n rele ọkọ

Darasimi tun jẹ afi ewi sọrọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Darasimi ni abigbẹyin, ọmọ kẹta fun idile oṣere Kristẹni Mike ati Gloria Bamiloye ti wọn jẹ gbajugbaja ninu awọn fiimu ẹsin Kristẹni ti awọn eeyan mọ si Mount Zion Films.

Darasimi ati Oyor

Oríṣun àwòrán, gospelfilmsng

Ayẹyẹ idagbere 'Bridal shower' ti awọn ọrẹ iyawo ṣe fun ṣaaju ọjọ igbeyawo re e.

Oríṣun àwòrán, gospelfilmsng

Àkọlé àwòrán, Ayẹyẹ idagbere 'Bridal shower' ti awọn ọrẹ iyawo ṣe fun ṣaaju ọjọ igbeyawo re e.
Ọkọ iyawo, Lawrence, ati awọn ọrẹ rẹ re e to n dọbalẹ niwaju awọn obi iyawo rẹ.

Oríṣun àwòrán, Mike bamiloye/facebook

Àkọlé àwòrán, Ọkọ iyawo, Lawrence, ati awọn ọrẹ rẹ re e to n dọbalẹ niwaju awọn obi iyawo rẹ.

Olorin Kristẹni ni Lawrence Oyor, to jẹ ọkọ Darasimi.

O kẹkọ gboye ninu imọ ofin ni fasiti ilu Ibadan lọdun 2013 to si tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ nileewe imọ ofin, Yola. Lawrence Oyor.

Oluwadarasinmi, Lawrence ati awọn ọrẹ iyawo

Oríṣun àwòrán, Mike bamiloye/facebook

Ọmọ Eleme ni ipinlẹ Rivers ni Lawrence Oyor, wọn bi i lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹfa ọdun 1992.

Awọn ẹgbọn Darasimi mejeeji, ati awọn iyawo pẹlu ọmọ ọkan lara wọn

Oríṣun àwòrán, Mike bamiloye/facebook

Àkọlé àwòrán, Awọn ẹgbọn Darasimi mejeeji, ati awọn iyawo pẹlu ọmọ ọkan lara wọn

Ibeji ni Lawrence, orukọ ibeji rẹ a si maa jẹ Godswill.

Bayii ni iya Lawrence ṣe fi owo yẹ ọmọ rẹ si, lasiko to n jo nibi eto idana naa

Oríṣun àwòrán, Mike bamiloye/facebook

Àkọlé àwòrán, Bayii ni iya Lawrence ṣe fi owo yẹ ọmọ rẹ si, lasiko to n jo nibi eto idana naa

Akọrin Kristẹni lawọn mejeeji.

Ayé mi kò bá dojú rú, ká ní mi o fẹ́ Gloria - Mike Bamiloye

Gloria ati Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Instagram/gloriabamiloye

"Mo ki ara mi ku oriire laye, nitori pe mo fẹ ọ.

" Abajọ ti nkan fi n dara fun mi; abajọ ti mo fi ni iru awọn ọmọ to dara ti o bi fun mi; abajọ to fi dabi ẹni pe mo n lo àjídèwe, nitori pe o ko lo mi ni alobajẹ."

Wọn yii ni diẹ lara ọrọ ti ogbontarigi osere fiimu ẹṣin Kristẹni, to tun jẹ Oludasilẹ ileesẹ Mount Zion Ministries, Mike Bamiloye, sọ lati fi mọ riri iyawo rẹ, Gloria Olusola Bamiloye, ni ayajọ ọdun kejilelọgbọn ti wọn ṣe igbeyawo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu akọsilẹ naa to fi si ori ayelujara Facebook, Mike Bamiloye sọ pe, oun ko ni ohunkohun bi i owo ati dukia, nigba ti Gloria gba lati fẹ oun, bo tilẹ jẹ pe awọn ẹbí wa gba wa ni imọran pe, ki a ma ṣe bẹ ẹ.

Gloria Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Facebook/Mike Bamiloye

Bamiloye ni ọpọlọpọ igba ni oun ti ṣẹ iyawo oun nipa ai fi aaye silẹ fun bose yẹ.

O ṣalaye pe, ọpọ igba ni isẹ Oluwa ma n gba gbogbo akoko oun, debi i pe oun kii ri aaye wa pẹlu rẹ.

O ni "Mo si n kekọọ lati mọ bi mo ṣe le fi ifẹ han si ọ bo ṣe yẹ.

" Ọpọlọpọ igba ni mo ma n wa ni agbedemeji ìwọ ati isẹ iranṣẹ... O ju isẹ iranṣẹ lọ, àmọ́ dandan ni fun mi lati ṣe iṣẹ ẹni to ran mi... "

Ọpọlọpọ igba ni mo ti kuna, nipa ai fi aaye silẹ lati wa pẹlu rẹ bose yẹ.

Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Facebook/Mike Bamiloye

"Eyi si ni mo tọrọ idariji fun lọwọ rẹ, lonii."

"Dariji mi fun awọn asiko ti mo pariwo mọ ọ, nitori ẹrù isẹ iranṣẹ àti bukaata ile wọ̀ mi lọrun.

Ajinhinrere Bamiloye tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, oun ko ni koko isẹ kankan lọwọ ju ere ori itage lọ nigba ti oun gbe Gloria niyawo.

O ṣalaye pe ẹbí, ara ati ọrẹ lo da owo ti awọn fi ṣeto ayẹyẹ igbeyawo naa lọdun 1988,to fi mọ eyi ti wọn fi gba ile.

Mike Bamiloye, Gloria aya rẹ ati awọn ọmọ wọn

Oríṣun àwòrán, Facebook/Mike Bamiloye

Bamiloye sọ pe iyawo to n ṣe ojuṣe rẹ ni Gloria jẹ, debi i pe oun ko ni ìdí kankan lati jẹun nita.

Ko tan sibẹ o, o tun ni oun dupẹ lọwọ Ọlọ́run pe gbogbo àwọn obinrin ti oun kọkọ dẹnu ifẹ kọ ko gba lati fẹ oun.

"Mo dupẹ pe mo ba ọ sọrọ igbeyawo lọdun marundinlogoji sẹyin; mo dupẹ pe o gbọran si àṣẹ Oluwa lati fẹ mi.

Gloria ati Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Facebook/Mike Bamiloye

Mo dupẹ pe a di tọkọtaya ni ọdun mejilelọgbọn sẹyin; mo dupẹ pe iṣẹ iranṣẹ wa ri bo ṣe ri; mo dupẹ fun igbe aye rẹ."

O sapejuwe iyawo rẹ gẹgẹ bi iwe akaikatan, "nitori pe bi mo ṣe n ka ọ si, ni mo n mọ awọn adun ati anfaani rẹ si."

"Iyawo to ni ìtẹríba ni ọ, abajọ ti awọn ọmọ wa ọkunrin fi gbadura pe ki Ọlọrun fun wọn ni iyawo bi iru rẹ. Mo si dupẹ pe o ri bẹ ẹ fun wọn.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Ju gbogbo rẹ lọ, mo dupẹ fun ọfiisi tuntun ti o ṣi fun mi gẹgẹ bi ẹ̀bùn ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun ti mo pe.

Titi de opin ẹmi mi ni ma a ni ifẹ rẹ."

N kò mọ ẹni tó fẹ́ gba ìyàwó mi, àmọ́ wọn máa ń sọ pé ó rẹwà - Mike Bamiloye

Gloria ati Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Instagram/gloriabamiloye

Se ẹ ti wo awọn sinima yii ri - Ide Esu, Agbara nla (Ayaaaaaaamatanga), Egun aimọ, Ogun atilewa, Ibere opin aye...ati bẹẹ bẹẹ lọ?

To ba jẹ pe bẹẹ ni, a jẹ wipe ẹ kii ṣe ikoko rara tori ọdun gbọọrọ sẹyin ni orukọ Mike Bamiloye ti maa n ro leti awọn eeyan, pẹlu awọn fiimu to n ṣe sita.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ajihinrere Mike Bamiloye, tii se ẹni to gbe awọn sinima awodamiẹnu naa sita ni ọdun gbọọrọ sẹyin, salaye nipa awọn asiri aseyọri rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bamiloye sisọ loju rẹ faraye pe, oun kii ṣe pasitọ tabi adari ijọ kankan gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe ma n fi oju wo bi igbagbọ rẹ ti gbona to.

Eyi ko si sẹyin ohun to jẹyọ latara awọn sinima rẹ ati iru awọn ọrọ to maa n fi sita lori ayelujara loore koore lẹnu ọjọ mẹta yii, to jọ mọ ka maa bu ẹnu atẹ lu awọn iwa kọọkan tawọn ọdọ n hu.

Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Instagram/gloriabamiloye

Bakan naa ni gbajumọ osere tiata ti ẹmi naa ni oun ko da ijọ kankan silẹ o.

Mike Bamiloye ni "mi o ki n ṣe pasitọ, mo ni ijọ ti emi naa n lọ gẹgẹ bi ọmọ ijọ, ti mo si ni pasitọ pẹlu, nigba kuugba ti a ba wa nile lorilẹede Naijiria, a n darapọ mọ ijọsin".

Amọ Bamiloye ni iṣẹ iranṣẹ ijere ẹmi Kristẹni ti Ọlọrun pe oun si, nikan ni oun gbajumọ.

"Ki ni itumọ AYAAAAAAMATANGA"?

Ṣe "I am a Tiger" ni itumọ "Ayamatanga"?

Mike Bamiloye ati Gloria aya rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/gloriabamiloye

Fun igba akọkọ, Mike Bamiloye ṣalaye ọrọ kan to jade ninu fiimu Agbara Nla to ṣe, ninu eyi ti obinrin kan, Bose to gba agbara okunkun lọwọ ọrẹ rẹ, Paulina, ti maa n kigbe "Ayamatanga", ki agbara Ọlọrun to tu u silẹ.

Ajihinrere Mike Bamiloye ni,ọrọ naa ko ni itumọ kankan lodi si oriṣiriṣi itumọ ti awọn eeyan n fun un.

"Emi ṣaa ni mo mọ ọrọ ti Ọlọrun fun mi, Ayamatanga kii ṣe "I am a Tiger" tabi "I am at anger" tawọn eeyan n wi o, baa ṣe pe e ninu ere gẹlẹ, bẹẹ ni Ọlọrun ṣe sọ fun mi, ti mo si kọ ọ silẹ".

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?

Musulumi ati Kristẹni ati ẹlẹsin ibilẹ, lo wo ere Mount Zion, bo o lẹ ṣe ṣe e?

"Nigba to ti jẹ wipe awọn ere wa da lorii ki idile toro, bibọ lọwọ ogun eṣu ati bẹẹ bẹẹ lọ ko si sẹni ti ko fẹ bọ lọwọ ogun tabi ti ko fẹ ki idile oun to".

Bamiloye ni idi niyi ti ere awọn ṣe wulo fun gbogbo ẹya tabi ẹsin.

Koda o fi kun un pe, lara awọn sinima tuntun tawọn ṣẹ tun gbe jade bii "The train, Shackles, Abejoye ati bẹẹ bẹẹ lọ, orilẹede ọtọọtọ to ju mẹwaa lọ, ni wọn ti fẹ ṣe akọkọ wo rẹ.

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Ta lo ti fẹ gba arẹwa obinrin Gloria, iyawo Bamiloye ri?

"Ha ha ha ha", Bamiloye rẹrin, o ni lootọ oun mọ pe iyawo oun rẹwa, ti awọn eeyan si maa n sọ ọ kan oun loju.

"Amọ ti wọn ba ti sọ ọ, maa ni ẹ ṣeun. Ko sẹni to sọ fun mi ri pe, oun yoo gba iyawo mi o, abi boya awọn to n beere ibeere yii naa lo ni i lọkan".

Nigba to n salaye idi ti igbeyawo wọn se tọjọ di oni, Bamiloye ni awọn kii tasẹ agẹrẹ ko ipa ti ko yẹ ki awọn ti kii ṣe tọkọ taya ko ninu ere.

"Fun apẹrẹ, lori ipa ọrẹkunrin si ọrẹbinrin, ọkunrin ko le gbe obinrin le itan o, bẹẹ si ni mi o le fẹnu ko iyawo oniyawo lẹnu ninu ere toripe a fẹ ko ye awọn eeyan".

Bamiloye ni eyi lodi si ofin Ọlọrun.

Mike Bamiloye ati Gloria aya rẹ pẹlu awọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ wọn

Oríṣun àwòrán, Instagram/gloriabamiloye

Awọn ọrọ Bamiloye lori ayelujara to n da ariwo silẹ:

Bamiloye ni oun le jẹ "Old school" ṣugbọn oun ni oun n tẹ foonu funrarẹ oun, ti oun si n kọ ọrọ sita lojoojumọ lati jiṣẹ Ọlọrun.

O ni oun ko ko ọrọ oun jẹ lori imura buruku tawọn ọdọbinrin mii n mura lọ ṣọọṣi ati lori ọrọ awọn to n kanju lati ṣegbeyawo.

Ajihinrere Mike Bamiloye ati iyawo rẹ Gloria, ni ọmọ ọkunrin meji ati abigbẹyin obinrin kan, tawọn naa yan lọwọ ara wọn lati darapọ mọ iṣẹ iranṣẹ fiimu Kristẹni, ti baba ati iya wọn n ṣe.

Ọmọ Mike Bamiloye tó ṣe fíìmù Ayamatanga fẹ́ ṣègbéyàwó, kà síi nípa ọkọ rẹ̀

aworan Lawrence ati Darasimi

Oríṣun àwòrán, Darasimi/Lawrence Oyor Instagram

O ṣe diẹ ti iroyin igbeyawo olorin Kristeni da oju opo ayelujara ru bi ti iroyin eleyi ta mu tọ yin wa.

Igbeyawo tawọn eeyan n jẹ ọrọ rẹ lẹnu yi si ni ti Darasimi, ọmọ gbajugbaja oṣere, olukọtan Kristẹni, Mike Bamiloye pẹlu olorin Kristẹni, Lawrence Oyor.

Igbeyawo naa yoo waye ni oṣu kẹwa ọdun yi.

Ikede yi ti mọlẹbi Mike-Bamiloye kan fidi rẹ mulẹ fun BBC ti n da awọn eeyan lọrun ti awọn ọmọ Naijiria si ti n da si ọrọ ifẹ wọn.

Boya nitori pe ni ọdun yii ni baba ọkọ afẹsọna Darasimi Mike-Bamiloye, iyẹn Rev. Dr Gomba Fortune jẹ Ọlọrun nipe, a ko mọ ṣugbọn ọrọ naa gbode kan.

Lawrence Oyor to jẹ afẹsọna Darasimi jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn.

Ọmọwe Gomba Fortune Oyor ni baba to bi lọmọ.

Aworan mọlẹbi Lawrence Oyor

Oríṣun àwòrán, Facebook/Lawrence Oyor

Ẹ gbọ ohun ti mọlẹbi Mike Bamiloye sọ fun BBC: "Lagbara Ọlọrun, imura igbeyawo naa ti n lọ rẹgi rẹgi.''

Àkọlé fídíò, No reception wedding: Adewale ni àpèjẹ kò ṣe pàtàkì sí òun

''Nitori iru awọn eeyan nla nla ti yoo wa sibi igbeyawo ọhun ati titori a ni lati tẹle ofin ijọba, a o ṣe bi a ṣe le din ero ku.''

O tẹsiwaju pe ''pẹlu iwe ipe nikan si ni awọn eeyan yoo fi wọle",

Ohun to o ni lati mọ nipa Darasimi Bamiloye

aworan Lawrence ati Darasimi

Oríṣun àwòrán, Darasimi/Lawrence Oyor Instagram

Oluwadarasimi Mike-Bamiliye (gẹgẹ bi apeja orukọ rẹ) kẹkọ gboye ninu imọ ede Gẹẹsi ni fasiti Babcock, Naijiria.

Ohun ni ọmọbinrin kan ṣoṣo ni idile Mike-Bamiloye oun naa si jẹ oṣere Kristẹni bii ti baba rẹ, iya ati awọn ẹgbọn rẹ ọkunrin meji.

Darasimi tun jẹ afi ewi sọrọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Aworan Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Mike Bamiloye

Darasimi ni abigbẹyin, ọmọ kẹta fun idile oṣere Kristẹni Mike ati Gloria Bamiloye ti wọn jẹ gbajugbaja ninu awọn fiimu ẹsin Kristẹni ti awọn eeyan mọ si Mount Zion Films.

Ọjọ kẹrinla oṣu karun ni wọn bi i, ọmọ ilu Ilesa nipinlẹ Oṣun ni idile wọn nilẹ Yoruba. Darasimi ṣe agunbanirọ ni ipinlẹ Kebbi.

Mọ nipa ọkọ afẹsọna rẹ, Lawrence Oyor

Yatọ si pe Lawrence jẹ olorin Kristẹni, o kẹkọ gboye ninu imọ ofin ni fasiti ilu Ibadan lọdun 2013 to si tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ nileewe imọ ofin, Yola.

Ọmọ Eleme ni ipinlẹ Rivers ni Lawrence Oyor, wọn bi i lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹfa ọdun 1992.

Ibeji ni Lawrence, orukọ ibeji rẹ a si maa jẹ Godswill.

Akọrin Kristẹni lawọn mejeeji.

Aworan Lawrence ati Ibeji rẹ ti wọn n jijọ n kọrin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Lawrence Oyor

Lawrence lee sọ ede mẹta - Gẹẹsi, Yoruba ati Ibibio-Efik.

Baba Lawrence ni oloogbe Rev. Dr. Gomba Fortune.