Nigerian Police: Àgbègbè odogbolu ní ìpínlẹ̀ Ogun ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé

Aajo SARS ti ijọba apapọ

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Minisita feto ẹkọ tẹlẹri, Iyabo Anisulowo lo ọsẹ kan ni ihamọ awọn agbenipa naa n'ipinlẹ Ogun

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ni awọn ti mu ọkọ ati iyawo pẹlu awọn meji kan ti wọn bẹ ori oku nipinlẹ Ogun.

Niyi ati Remilekun Folorunso ti wọn jẹ ọkọ ati iyawo, ni ọwọ sinku ọlọpaa tẹ pẹlu Muyideen Tolubi ati babalawo wọn, Sonubi Taiwo fun ẹsun gige ori oku nipinlẹ Ogun.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi to fi iṣẹlẹ naa lede ni, awọn mu awọn mẹrin naa lẹyin iroyin ti wọn gbọ pe, awọn mẹrẹẹrin n wu iboji ni agbegbe Odogbolu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Lẹyin ti a gbọ iroyin yii, a lọ sibẹ, amọ awọn afurasi mẹrin naa ti ge ori oku, ti wọn si salọ, sugbọn bi a ṣe bẹrẹ iwadii lẹkunrẹrẹ niyẹn, eleyii to jẹ ki a ri tọkọ-taya naa mu pẹlu Muyideen Tolubi."

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Awọn mẹtẹẹta jẹwọ wi pe lootọ ni awọn hu iboji oku, ti awọn si ge ori rẹ kuro.

Lẹyin naa ni wọn mu awọn ọlọpaa lọ si Ikenne ti babalawo to jẹ ẹni kẹrin, ti wọn si ni oun lo ni ki awọn lọ ge ori oku naa fun irubọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ni, Kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Edward Ajogun ti paṣẹ ki wọn gbe awọn afurasi naa lọ si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran, fun iwadii ẹkunrẹrẹ.

Afunrasi afipajinigbe k'agbako ni Ogun

Aajo SARS ti ijọba apapọ ti pa afurasi ọmọ ẹgbẹ afipajinigbe kan, ti wọn n s'ọsẹ ni agbegbe Ilaro ni ijọba ibilẹ guusu Yewa ni ipinlẹ Ogun, ajọ ọlọpa ti sọ eyi di mimọ.

Agbenusọ fun ajo ọlọpa ni ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, wipe awọn ẹgbẹ ajinigbe naa ti ji ọkunrin kan, Saani Nasarawa gbe, ti wọn so o mọ igi fun ọjọ meje, nigba ti wọn duro de awọn ẹbi rẹ lati san owo idasilẹ

Oyeyẹmi wi pe ọkunrin ti wọn jigbe naa tu ara rẹ silẹ, ti o si na papa bo'ra nigba ti awọn ti o jii gbe n sun. Lẹyin eyi ni ọkunrin naa ba gba ile-isẹ awọn SARS ni Abeokuta lọ, lati lọ sọ gbogbo bi isẹlẹ naa se ri.

O fikun ọrọ rẹ wipe, ajọ SARS ko fa ọrọ gun rara, nibi adari wọn se lewaju iko to lọ koju awọn agbenipa ọhun, nibi ti wọn lugọ si.

Agbẹnusọ ajọ ọlọpaa naa sọ wipe ijakadi laarin awọn agbenipa naa ati ajọ SARS ja si iku ọkan lara wọn, ti awọn meje miran si farapa yẹlẹyẹlẹ nigba ti wọn na papa bo'ra. Ajọ SARS naa ri ibọn AK47 ti o ni ọta ibọn marundinlogun ninu.

Oyeyẹmi fi kun un wi pe, kọmisọna fun ajọ ọlọpa ni ipinlẹ naa, Ahmed Iliyasu wa parọwa si awọn ara ilu, ile-iwosan tijọba ati tibilẹ lati tete fi to awọn ọlọpaa leti, ti wọn ba ri ẹnikẹni to yọju sile iwosan pẹlu ọgbẹ ọta ibọn.