Bola Tinubu: Wo àṣírí tó gbé ìgbéyàwó Remi àti Bola Tinubu dúró bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn wọn yàtọ̀

Oríṣun àwòrán, MOtherhood-in-style
Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria to tun jẹ Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu, Oluremi Tinubu ti sọ pe iṣoro iyandagbe lo sọ oun di ẹlẹsin Kristiẹni tootọ.
Remi Tinubu, to jẹ sẹnetọ fun ẹkun Lagos Central, gẹgẹ bi Iwe Iroyin ori ayelujara, Motherhood-in-Style ṣe sọ, sọ lasiko ifọrọwanilẹnu wo kan to ṣe pẹlu ileeọẹ amohunmaworan TVC pe lasiko ti oun n da gbe pẹlu ọmọ meji lorilẹ-ede America ni oun di onigbagbọ.
O ṣalaye pe oun di atipo ni America pẹlu ọmọ oun meji, lasiko ti ijọba Ọgagun Sani abacha, ni Naijiria fi ọkọ oun si ẹwọn, nitori ọrọ June 12.
Bakan naa lo sọ pe bi oun ṣe di obinrin akọkọ gẹgẹ bi iyawo gomina ipinlẹ Eko, mu ki oun mọ pe itọni Ọlọrun nikan lo le mu oun ṣe aṣeyọri lori ipo naa.
"Bi ọdun marun ni mo fi n ṣe atipo, ti eeyan ba si ni iṣoro, Ọlọrun nikan lo le sa ba.
"Asiko ti mo wa ni America ni mo di atunbi."
O fikun ọrọ rẹ pe oriṣiriṣi ijọ ni oun wa Ọlọrun de.
"O le debi i pe mo ni aisan to n mu ni gbagbe nkan 'Amnesia', nigba ti mo pada de, nitori pe iṣoro naa ti pọju.
"Nitori naa si ni mi o ṣe fẹran lati ma a lọ si ode ariya, nitori ọpọ eeyan ni mi o damọ mọ."

Oríṣun àwòrán, Rauf Aregbesola/facebook
O ni oun ko ju ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn lọ nigba ti oun ati ọkọ oun (Bola Tinubu) pinya, fun igba akọkọ. Koda, ọrọ naa le debi i pe ọna ẹburu ni a n gba rira lẹẹkan l'oṣu mẹfa.
Laipẹ yii lo ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun.
"Inira gba a ni asiko naa jẹ fun mi, paapa bukaata awọn ọmọ. Nitori naa, iriri ọtọ lo pada jẹ, nigba ti mo pada si Naijiria lati di iyawo gomina."
Lori bi oun ati ọkọ rẹ ṣe jẹ ẹlẹsin ọtọọtọ, Sẹnetọ Tinubu sọ pe oun ko ri bi nkan babara nigba ti oun ati ọkọ rẹ pade.
O ni "ọmọ ijọ Anglica ni mi, ọpọ Kristiẹni lo si n fẹ Musulumi lasiko naa. Koda, ẹgbọn mi obinrin lo mu emi ati ọkọ mi mọra."
Nkan kan ni pe, baba mi sọ fun ọkọ mi pe "mo nireti pe o ko ni di ọmọ mi lọwọ lati ma a lọ si ṣọọṣi.'' O si ṣeleri pe oun ko ni ṣe bẹ ẹ."
Otitọ to wa nibẹ ni pe, ọkọ mi pọn ẹsin mi le gan-an, emi naa si pọn ti ẹ le. Nitori naa ni ko sẹ si ija."
Remi Tinubu tun ṣalaye pe oun ko fi igba kankan ni iṣoro ri, nitori pe oun fẹ Musulumi lọkọ, bakna naa ni ọkọ rẹ ko fi agidi mu awọn ọmọ wọn lasi ṣe ẹsin Islam.
¨Ilana ẹsin Kristẹni ni mo fi tọ awọn ọmọ mi dagba, bo tilẹ jẹ pe orukọ Musulumi ni wọn n jẹ."















