'Iná fóònù ló kù tí àwa Dókítà fi ń gbẹ̀bí àwọn aláboyún'

Awọn Dokita ati oṣiṣẹ ilera to di foonu mu lati fi rina ṣe iṣẹ abẹ

Oríṣun àwòrán, DR HOWAIDA AHMED AL-HASSAN

Diẹ ninu awọn ileewosan ni olu ilu orileede Sudan, Khartoum lo wa ni ṣiṣi bayii.

Pupọ lo ti kogba sile nitori ogun abẹle to n tẹsiwaju lorileede naa.

F'awọn to ku to n ṣiṣẹ wọnyii, tipatipa ni wọn fi n ṣiṣẹ nitori ipenija ina mọnamọmọ ti ko wa deede.

Eleyii mu ki igbẹbi ọmọ jẹ inira fawọn alaboyun ati awọn oṣiṣẹ ilera to n gbẹbi wọn.

Ipenija yii a maa foju han paapa lasiko ti wọn ba nilo lati ṣe iṣẹ abẹ.

Ki wa lọna abayọ fun awọn oṣiṣẹ ilera yii nibi ti okunkun ba ti wa nitori aisi ina mọnamọna?

"Ina ori foonu wa laa n lo lati fi ṣe iṣẹ abẹ fawọn alaboyun''.

Esi ree lati ẹnu onimọ iṣegun itọju alaboyun Dr Howaida Ahmed al-Hassan ninu fọnran fidio kan to ṣalabapin pẹlu BBC.

O ya fọnran fidio yi lasiko to n ṣe iṣẹ abẹ fun alaboyun kan to fẹ bimọ.

Ninu rẹ, a ri bi o ṣe n fi ọwọ to wọ ibọwọ si tẹ igbaaya alaboyun yi ati ikun rẹ lasiko iṣẹ abẹ yii.

Awọn akẹgbẹ rẹ to rọgba yiika gbe ina foonu wọn soke ki o baa lee rina ṣe iṣẹ abẹ ọhun.

Obinrin ni gbogbo awọn to wa nibẹ.

Dokita Hassan wa lara awọn dokita diẹ to ṣẹku ni ileewosan Alban Jadeed ni agbegbe ariwa olu ilu Sudan lẹyin ti ikọlu ti n waye leralera fun ọsẹ mẹta gbako nibẹ.

Ninu fidio to fi ranṣẹ si BBC, a ri bi awọn oṣiṣẹ ilera ṣe n ba iṣẹ lọ pẹlu inira.

'Nkan buru pupọ. Aimọye ọjọ la ti wa ni ibi ti a ko tiẹ le sọ pe igba bayii pato la ti wa ni ileewosan.Ko fẹẹ si iyatọ laarin ojumọ ati igba ti ilẹ ba ṣu fun wa''

Dokita Hassan sọ pe ''A ko loṣiṣẹ to kapa iṣẹ to wa nilẹ lọpọ igba ti ina mọnamọna ba si lọ, ko si bẹntiroo taa le da si ẹrọ amunawa nigba ta baa n ṣe awọn iṣẹ abẹ''

Ewu nla laa n fori la lati gbẹbi awọn alaboyun

O ni niṣe ni awọn ileewosan kun fọfọ fun awọn alaboyun to nilo itọju paapa iṣẹ abẹ.

''Ewu nla la n fori la lati ṣe awọn iṣẹ abẹ yi.A ko ni nkan elo to peye''

''A ko ni eronja taa le fi kun eeyan loorun,awọn akọṣẹmọṣẹ.A ti sọ fun awọn taa ṣe iṣẹ abẹ fun pe ki wn pada sile lẹyin wakati mẹwaa taa ṣe iṣẹ abẹ fun wọn tan''

Ni oṣu Kẹrin, Ajọ isọkan agbaye to n ri si iye eeyan to wa laye sọ pe o sunmọ alaboyun 219,000 to wa ninu ewu latari ikọlu to n waye ni Khartoum.

Lasiko ti ija yi kọkọ bẹrẹ,ajọ naa s pe nkan bi alaboyun 24,000 ni yoo bimọ ''lawọn ọsẹ to n bọ''

Bashayar al-Fadil ati ọkọ rẹ n woju ọmọ wọn tuntun

Oríṣun àwòrán, BASHAYAR AL-FADIL

Bashayer al-Fadil wa lara awọn obinrin to bimọ lasiko taa n wi yi.

Lẹyin ọjọ meloo kan ti ikọlu bẹrẹ ni wọn ṣe iṣẹ abẹ fun un.

O ba BBC sọrọ lori ipe ''Video call'' taa si ri to n gbe ọmọ rẹ obinrin tuntun Omayma jo.

O ni oun ṣe koongẹ ileewosan kan ti wọnṣi n ṣiṣẹ ati pe wọn gba oun wọle pẹlu bi iro ibọn ṣe n ro ni kikan kikan.

O ni niṣe ni ''A kan n gbọ ibugbamu laarin titi ''

Ileewosan kan ninu mẹfa ni ajọ WHO sọ pe o ṣi n ṣiṣẹ ni Khartoum.

Bashayer sọ pe oun ati ọkọ rẹ ni lati sare de ileewosan ni pẹlu bi wọn ṣe n yinbọn layika wọn.

O ni titi di asiko yi, oun ko tii ri iwe ẹbi gba debi tawọn yoo ti ẹ ri awọn nkan eelo to ṣe koko ra fi tọju ọmọ naa.