Mo rin ìrìnàjò wákàtí 30 dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ Reluwé, Mọ́ṣúárì àmọ́ mi ò rí ọmọ mi - Aráàlú

Ijamba ọkọ Reluwe

Oríṣun àwòrán, Rajah Sahani

Awọn mọlẹbi awọn to fara gba nibi ijamba ọkọ Reluwe mẹta to waye ni orilẹede India ti sọrọ nipa ilakaka wọn lati ṣawari awọn eeyan wọn to dawati nibi ijamba ọkọ naa.

Arabinrin kan to n wa ọmọkunrin rẹ ti kii ṣe ọmọde sọ fun BBC pe oun rinrinajo fun wakati ọgbọn lọ si ibi iṣẹlẹ aburu naa, kaakiri awọn ileewosan to fi mọ mọṣuari.

Awọn oṣiṣẹ ijọba sọ pe ni ọjọ Abamẹta ti wọn pari iṣẹ idoola ti wọn n ṣe ni agbegbe Odisha, oṣojumikoro kan sọ pe oun ti ri eeyan kan to ye ijamba naa yọ sita lowurọ ọjọ keji.

Iye eeyan to ti ku to wa lakọsilẹ bayii ti di 275.

Ijamba yii ni yoo jẹ eyi to buru jai ju ni orilẹede India lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin eyi si ti n kọ awọn eeyan lominu.

Lilayati Dave bu sẹkun bo ṣe n ba BBC sọrọ ni ọjọ Aiku wipe oun si n wa ọmọ oun bo tilẹ jẹ pe awọn mọlẹbi rẹ mẹjọ mii to wa ninu ọkọ Reluwe naa ti di riri.

Àkọlé fídíò, India train accident: Workers remove wreckage from tracks
Ijamba ọkọ Reluwe

“Mo gbadura pe ka rii nibi kan, yala lọna kan tabi omiran, ko sohun miran ti mo fẹ ju ki Ọlọrun ba mi da ọmọ mi si lọ”.

Ọmọ rẹ, Raja Sahani to jẹ ẹni ọdun mejilelogun n rinrinajo lọ pẹlu awọn mọlẹbi rẹ ni lati ilu wọn, Bihar lọ si ilu nla nni, Bangalore – nibi ti wọn ti maa n ṣe oniruuru iṣẹ jamajama mọra wọn lati ri ounjẹ oojọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọpọ igba iru irinajo yii maa n gba ki wọn parọ ọkọ oju irin ni ilu Howrah eyi si ni ibi ti wn ti wọ ọkọ oju irin ti ko gbadun naa. Koda Raja ya fọto ara rẹ nibẹ to si fi ranṣẹ.

Lẹyin wakati melo kan lẹyin to kuro nile, iya rẹ, Lilayati gba ipe latọ́bọ mọlẹbi miiwipe ijamba ọkọ kan ti ṣẹlẹ. O pe foonu Raja ti ti ti lẹyin naa amọ o ti wa ni pipa.

Gbogbo wiwa to n wa a ka, pabo lo ṣi n ja si. O ni awọn ti na iye owo to to ẹgbẹrun marundinlaadọta Rupee, owo ilẹ India iyẹn iwọn £438 lati ya ọkọ ti wọn n lo fi wa a kiri – owo yii gọbọi ju ohun to yẹ lọ.

“Koda mo tun ti wa gbogbo awọn ileewosan ati ile igbokupamọsi ṣugbọn mi o rii.

O fi kun un pe “a sọ fun awọn oṣiṣẹ mọṣuari lati fi aworan han nipa gbogbo oku to wan nibẹ, amọ ko si nibẹ.

Odisha to jẹ oṣiṣẹp Pradeep Jena sọ fun BBC pe o kere tan, oku eeyan 187 ti wọn ko tilẹ tii da mọ bayii, awọn oṣiṣẹ n fi aworan sita lori itakun ayelujara ti ijọba bẹẹ si ni wọn yoo ṣe ayẹwo ẹjẹ bo ba nilo.

Maapu Odisha ni India

‘O ́ ṣeéṣe kó jẹ́ ẹ̀rọ tó ń ṣàpèjúwe ọ̀nà ló fa ìjàmbá ọkọ̀ Reluwé tó pa ènìyàn 275’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Minisita fun eto irina oju irin ti ni o ṣeeṣe ko jẹ ẹrọ to n ṣapejuwe ọna lo fa ijamba ọkọ ojurin to mu ẹmi ọgọọrọ eniyan lọ lorilẹede India.

Ashwini Vaishnaw ni o seese ki awọn ero to ma n sọ ọna to ỵẹ ki eniyan gba lo ṣe akoba naa to si fa ijamba ọkọ ọhun.

Atẹjade lori iṣẹlẹ naa sapejuwe iṣẹlẹ yii gẹgẹ bi eleyii to buru julọ ni itan orilẹede naa lati bi ọgọrun ọdun sẹyin.

Nibayii, iye eniyan to ti ba iṣẹlẹ naa lọ jẹ igba eniyan ati marundinlọgọrin, 275.

Ijọba ni eleyii ju iye ti wọn kọkọ kede lọ nitori wọn ka awọn oku eniyan kan lẹẹmeji.

Ninu eniyan to le ni 1,175 to fi ara pa ti wọn si gbe lọ si ilewosan, eniyan 793 ninu wọn ni wọn tit u silẹ.

Amọ awọn mọlẹbi kan ni awọn ṣ in wa awọn mọlẹbi wọn.

Ìjàmbá ọkọ̀ ojú'rin pa èèyàn 288, bíi 850 farapa

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ko din ni eeyan 288 to ti ku bayoi, ti 850 si farapa ninu ijamba ọkọ ojú'rin kan to waye nipinlẹ Odisha, ni orílẹ̀-èdè India.

Ọkọ̀ ojú'rin kan to ko èrò ni igbagbọ wa pe o yẹ̀ kuro ni oju ọna rẹ, ko to di wi pe ọkọ ojú'rin miran to n kọja lọ ni òdì-kejì kọlu u, lalẹ́ ọjọ Ẹti.

Ijamba yii ni ti ọkọ ojú'rin to tii buru ju ni India, lati bi ọgọrun ọdun.

Àwọn aláṣẹ sọ pe o ṣeéṣe ki awọn to kú pọ̀ si.

Akọwe ijọba ipinlẹ Odisha, Pradeep Jena sọ pe igba ọkọ ambulansi ni wọn ti ko lọ sibi iṣẹlẹ naa.

Bakan naa lo sọ pe dokita to le ni ọgọrun-un ni wọn tun ti ko lọ síbẹ̀.

Àwọn aláṣẹ ileeṣẹ ọkọ reluwe ni India sọ pe ọkọ ojú'rin Coromandel Express ati Howrah Superfast Express lo kagbako ninu ijamba naa.

India wa lara awọn orile-ede ti eto irinna ojú'rin rẹ tobi julọ ni agbaye, ijamba reluwe si jẹ nnkan to wọ́pọ̀ níbẹ̀.

Ọdun 1981 ni ijamba oko ojú'rin to tíì buru julọ ni India waye.

Iji lile kan lo ti ọkọ ojú'rin kan kuro ni oju ọna rẹ ni ipinlẹ Bihar. Ko din ni eeyan 800 to ku.