Ọmọdébìnrin tó lé 30 dàwátí níbi tí wọ́n ti ń sẹ́gi, èèyàn 20 fará gbọ́ta

Aworan awọn janduku agbebọn

Oríṣun àwòrán, VOA

Awọn janduku agbebọn tun ti ṣoro bi agbọn ni ipinlẹ Zamfara pẹlu bi wọn ṣe kọlu awọn abule kan nibẹ.

Ọpọ lo padanu ẹmi wọn ti awọn alaburu yi si ji ọmọdebinrin to le ni ọgbọn gbe salọ.

Awọn janduku naa kọlu abule Sakkida ati Janbako ni ọsan ọjọ Abamẹta nibi ti wọn ti pa eeyan to le ni ogun ti awọn aimọye mii si farapa.

Olugbe agbegbe naa kan to ba BBC sọrọ sọ pe o le ni ọmọdebinrin to le ni ọgbọn ni wọn ji gbe ni abule Gora nigba ti wọn lọ sẹgi ninu igbo Daggera.

O sọ pe: ''Awọn janduku naa fohun silẹ pe taa ba fẹ dako ni Daggera lọdun yi, a gbọdọ dunadura pẹlu wọn.

A ko mọ idi ti wọn fi ji awọn eeyan gbe. Awọn ọmọde yi ko mọwọ mọsẹ''

O tẹsiwaju pe ''titi di asiko yi, a ko gburo awọn ọmọ wa. Amọ awọn agbofinro ti tọ wọn lọ bo ti lẹ jẹ pe a ko gburo kankan''

Ara ilu Janbako kan naa sọ fun BBC pe jẹjẹ lawọn n ba faaji lọ ki eeyan kan to mu iroyin wa lati abule Sakkida ni tosi pe awọn janduku ti yabo abule wọn pe wọn si nilo iranwọ.

Ni kia lawọn araalu ti ṣa ara wọn jọ, àwọn to jẹ fijilante si gbe ibọn ti wọn gba Sakkida lọ.

O ni nigba ti wọn yoo fi sunmọ abule naa lawọn janduku bẹ jade siwọn lati inu igbo.

O ni wọn dabọn bolẹ ti wọn si pa awọn eeyan lọ rẹkẹrẹkẹ.

Eeyan mejilelogun ni wọn sin oku wọn si abule naa.

Arakunrin to ba BBC sọrọ yi fikun pe awọn ke si awọn agbofinro lati tọ ipasẹ awọn janduku yi lọ.

O ni alupupu meji awọn janduku yi nikan ni wọn ri mu pada wa.

O fi kun un pe awọn ologun tawọn tun ke si sọ pe awọn ko ni le ribi tete de nitori ọkọ táwọn n lo ko si ni itosi.

O ni wọn pada wa ṣugbọn alupupu meji nikan ni wọn ri mu pada.

Ileeṣẹ ọlọpaa fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC ṣugbọn wọn ni awọn ko ni iroyin mii mọ lasiko yi.

Ipinlẹ Zamfara wa lara awọn ipinlẹ to n koju ipenija aabo paapa lọwọ awọn janduku agbegbọn, ajinigbe.

Lọpọ igba ikọlu wọn si araalu a maa mu ọpọ ṣi ipo pada eyi a si maa kọ awọn araalu lominu.