Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo ń wá Lamidi Mukaila 'Auxillary' báyìí fún ẹ̀sùn ìpànìyàn

Mukaila Lamidi Auxiliary

Oríṣun àwòrán, Others

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ ti kéde alága àkóso páàkì, Park Management System (PMS) ìpínlẹ̀ náà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fọwọ́ òsì júwe ilé fún, Mukaila Lamidi, Auxiliary gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá.

Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí wọ́n gbọn ilé ìtura rẹ̀ yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ ní ọjọ́bọ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo, Adewale Osifeso fi síta lọ́jọ́ Ẹtì ní ohun tí àwọn ń wá Auxiliary sí dá lórí ìpànìyàn, olè jíjà àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn.

Osifeso tún fẹ́sùn kan Auxiliary pé ó lọ́wọ́ nínú àwọn ìjínigbé tó wáyé ní agbègbè Ibarapa àti Oke Ogun àti ìpínlẹ̀ Oyo lápapọ̀.

Ṣáájú ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lọ gbọn ilé Auxiliary tó wà ní Ibadan yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ tí wọ́n sì ní àwọn bá àwọn ohun ìjà ogun ní ilé rẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n ní tún nawọ́ gán àwọn ènìyàn rẹ̀ tó wà ní ilé rẹ̀ lásìkò náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ẹnikẹ́ni tó bá ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ láti fi tó àgọ́ ọlọ́pàá tó bá wà ní agbègbè wọn létí.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ni ọjọ Iṣẹgun ni Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ eeyan mọ si 'Auxiliary' na papa bora nitori ikọlu ti ileeṣẹ ọlọpaa sẹ si ile rẹ.

Awọn ọlọpaa ni eeyan mejidinlọgọrin ni awọn ko nile 'Auxiliary' lasiko ti wọn ya wọ ibẹ.

Bakan naa ni wọn ba onde, ibọn ati ohun ija ija loriṣirisi ninu ile naa.

Iroyin ni bi o tilẹ jẹ pe Auxiliary ti na papa bora, ẹmi eeyan kan ba iṣẹlẹ lọ lasiko ti wọn kọju ija si awọn agbofinro.

Lara ẹru ti awọn agbofinro ko ni ile naa ni ọpọlọpọ ibọn, ọta ibọn ti o le ni ẹdẹgbẹrin, ẹrọ ibanisọrọ mẹtalelọgbọ ati owo ti o le ni Milliọnu mẹta Naira.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ṣe afihan awọn ọmọlẹyin Auxiliary ti kele ofin gbe ninu ile ti wọn n gbe pẹlu ọga wọn.

Ọpọlọpọ ibọn ati ọta to fi mọ awọn nnkan ihamọra mii ni awọn agbofinro ba lọwọ wọn.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede loju opo Twitter ni wọn ti ni awọn ba igbiyanju awọn ti wọn mu naa lati da alaafia ipinlẹ Oyo ru.

Wọn ni o kere tan eniyan mejidinlọgọrin ni ọwọ awọn tẹ pẹlu ọpọlọpọ ibọn, onde ati owo iyebiye.

Saaju ni iroyin jade pe gomina ipinlẹ Oyo, ṣeyi Makinde ti gba gba iṣẹ lọwọ alamojuto igbokegbodo ọkọ, 'Park Management System (PMS)', Alhaji Mukaila Lamide ti ọpọ eeyan mọ si "Auxiliary" ati gbogbo igbimọ rẹ.

Eyi n waye lẹyin iburawọle fun saa ikeji ijọba Gomina ipinlẹ Ọyọ Ṣeyi Makinde lọjọ Aje.

Ninu atẹjade ti olori oṣiṣe tuntun n'ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Segun Ogunwuyi fi lede lorukọ Gomina, o ni, "Mo ti gba aṣẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde lati fi ọrọ too yin leti nipa ituka igbimọ to n ṣe amojuto igbokegbodo ọkọ bẹrẹ lati oni, ọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023".