Ilé aṣòfin Oyo tún rọ alága Káńsú mìíràn lóyè

Ile asofin ipinlẹ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, others

Ile igbimọ asofin ipinlẹ Oyo ti palasẹ ki alaga ijọba ibilẹ iwọ oorun Saki, Sharafadeen Omirinde lọ ma rọkun ile fun bi o sese owo ilu makumaku.

Igbesẹ naa waye nibi ijoko awọn ile igbimọ asofin loni, ti awọn asofin pẹlu awọn asoju ijọba ibilẹ si buwọlu igbesẹ naa.

Omirinde ni awọn dẹsun kan pe o ni ọkọ owo toto milọnu mẹtalelọgọta naira to jẹ ti ijọba ibilẹ si apo rẹ, ija ẹsin ati sise akoba fun ẹgbẹ pẹlu awọn ẹsun miiran.

Abẹnugan ile, Adebo Ogundoyin lẹyin to gbogbo atotonu lati ẹnu awọn asofin ni ki Alaga ọhun lọ ma gba atẹgun ni ile naa, ki iwadi si ma tẹsiwaju.

Bakan naa ni Abẹnugan wa palasẹ pe ki igbakeji alaga ijọbaibilẹ naa bẹrẹ si ni tukọ isakoso ijọba ni kiakia titi ile asofin yoo fi pari iwadi wọn lori ẹsun naa.

Ti a ko ba gba gbe, ọsẹ to kọja ni Ile asofin kana ni ki alaga ijọba ibilẹ Irepo, Arakunrin Lateef Sulaiman Adediran lo ma rọkun ile lori ẹsun iwa a tobi-ma ṣee bawi ti wọn fi kan alaga naa.

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ rọ alaga Kansu loye, wọn fi igbakeji rẹ rọpọ

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ti kede iyọnipo alaga ijọba ibilẹ Irẹpọ, Kiṣi, Arakunrin Lateef Sulaiman Adediran.

Igbimọ ile ṣe ikede naa l'Ọjọbọ lẹyin ti igbimọ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ, oye jijẹ ati eto ẹnawo pari iṣẹ iwadii wọn lori ẹsun iwa a tobi-ma ṣee bawi ti wọn fi kan alaga naa.

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ṣe alaye siwaju sii wi pe wọn yọ alaga naa nipo ni ibamu pẹlu ẹka ikọkanlelogun ofin ijọba ibilẹ ti ọdun 2001 gẹgẹ bi wọn ti ṣe atunto rẹ.

Iṣẹ iwadii naa ṣe akiyesi wi pe alaga ijọba ibilẹ naa jẹbi ẹsun kiko owo to yẹ ki wọn fi ra ọkọ ayọkẹlẹ 'Toyota Camry 2016' si apo ara rẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iwadii tun fi idi rẹ mulẹ wi pe o ra ọkọ ayọkẹlẹ ‘Lexus’ fun ara rẹ lai gba aṣẹ.

Bakan naa lo ra ọkọ tokunbọ 'Toyota' fun alamojuto agba ni ijọba ibilẹ.

Saaju ni ọfisi to n yẹ iwe owo fi ẹsun kan alaga naa ninu abajade iṣẹ iwadii ti wọn fi ṣọwọ si ile igbimọ aṣofin.

Bakan naa ni ile igbimọ aṣofin ke si ẹka ileeṣẹ ijọba to mojuto ijọba ibilẹ, oye jijẹ ati eto idajọ lati riidaju pe Adeniran sa owo to jẹ #4,616,800.00 pada si apo ijọba ibilẹ Irẹpọ ti o jẹ owo ti wọn yọ silẹ ninu Milliọnu Marun un o le ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira to yẹ ki wọn fi ra iwe fun awọn akẹkọọ.

Ọkan lara awọn alamojuto ijọba ibilẹ naa, Mutalubi Adigun Salami ti o gba owo ti o jẹ #2,676,000,00 gẹgẹ bii owo ti wọn da ninu ẹgbẹ oṣelu ninu owo oṣu awọn to di ipo oṣelu mu lati inu oṣu keji ọdun 2022 si oṣu kẹta ọdun 2023 ni wọn ti ke si pe ki o da #2,676,000,00 pada si apo ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ni ijọba ibilẹ Irẹpọ ki wọn si fi ẹri wi pe wọn ti san owo naa ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin laarin ọsẹ kan.