Àwọn ojú tó ṣeéṣe kí ẹ rí ní ìjọba ààrẹ Tinubu rèé…

Oríṣun àwòrán, Collage
Ohun ti o kan lẹyin ti wọn ti bura wọle fun aarẹ Tinubu ni lati yan awọn eniyan ti yoo ba ṣiṣẹ ni ijọba rẹ.
Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un, ọdun 2023 ni wọn bura wọle fun ni ilu Abuja to jẹ olu ilu orilẹede Naijiria.
Bio tilẹ jẹpe ko rẹyin lati kede awọn ti yoo ba ṣiṣẹ timọtimọ, o ti yan Femi Gbajabiamila gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ, to si tan Sẹnetọ Ibrahim Hadejia gẹgẹ bi igbakeji adari awọn oṣiṣẹ ati George Akume gẹgẹ bi akọwe ijọba ni Naijiria.
Lẹyin eyi ni awọn eniyan bere awọn ti yoo wani ijọba Tinubu naa.
Awọn eniyan ti n darukọ awọn eniyan kan amọ aarẹ naa ko le yan awọn minisita si ijọba rẹ ali jẹ pe ile asofin agba buwọlu u.
Awọn to seese ki wọn w ani ijọba aarẹ Buhari ree;
Dele Alake

Oríṣun àwòrán, Others
Arakunrin Dele Alake jẹ gbajugbaja akọroyin to tun jẹ kọmiṣọnna tẹlẹri fun ọrọ iroyin nipinlẹ Eko.
O tib a Tinubu ṣiṣẹ lati ọdun 1999 si ọdun 2007 nigba ti Tinubu jẹ gomina ipinlẹ Eko to si ṣiṣẹ fun Tinubu gẹgẹ bi adari ikọ iroyin fun ikọ ipolongo fun Tinubu.
Orukọ rẹ lẹkunrẹrẹ ni Henry Dele Alake ti wọn sib ii ni Ọjọ Kẹfa, Osu Kẹwaa, ọdun 1956.
Lati igba ti MKO Abiola ti wa ni ipo lo ti bẹrẹ oselu, amọ to tun jade pada lasiko ti wọn gbaradi fun idibo ọdun 2015 to si ṣiṣẹ fun ikọ ipolongo aarẹ Buhari nigba naa, to si jawe olubori.
Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, Others
Oloselu lorilẹede Naijiria ni Nyesom Wike to si tun jẹ agbẹjọrọ ati gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Rivers.
Atilẹyin ti Wike fun aarẹ Bola Ahmed Tinubu lasiko ati ẹgbẹ oselu APC lasiko idibo sipo aarẹ ti ọdun yii lo jẹ ki awọn eniyan maa darukọ rẹ gẹgẹ bi ẹni to seese ko w ani ijọba aarẹ Tinubu
Ọjọ Kẹtala, Osu Kejila, ọdun 1967 ni wọn bi Wike to si ni ọpọlọpọ iriri nipa eto oselu.
Igba meji lo ti se alaga ijọba ibilẹ Obio Akpor ni ọ̀un 1999 si 2007, to si jẹ igbakeji minisita fun eto ẹkọ ni Ọjọ Kẹrinla, Osu Keje, ọdun 2011 .
Bakan naa lo di minisita fun eto ekọ lẹyin ti minister Ruqqayatu fi ipo silẹ lati lo dije du ipo gomina.
Ọdun 2015 lo di gomina ipinlẹ Rivers, to si tun wọle pada ni ọdun 2019.
Hadiza Bala Usman

Oríṣun àwòrán, Others
Hadiza Bala Usman jẹ onimọ nipa eto ijọba ati oloselu to si jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ẹgbẹ oselu APC.
O ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari ileese Nigerian Ports ni ọdun 2016 si ọdun 2021.
Saaju igba naa lo ti di ipo adari awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ Kaduna ni ọdun 2015 si ọdun 2016.
Ni ọdun 2014 lo di ọkan lara awọn oludasilẹ ikọ Bring back our Girls.
Bakan naa lo sisẹ ni ikọ ipolongo aarẹ Buhari, to si tun ko ipa googi ni ikọ ipolongo aarẹ Bola Tinubu.
Chimaroke Nnamani
Gomina ipinlẹ Enugu tẹlẹri ni Chimaroke Nnamani ni ọdun 2003, to si jẹ ọrẹ aarẹ Tinubu
O di asofin orilẹede Naijiria lasiko to jawe olubori lọ si ile igbimọ asofin agba ni ọdun 2007 si 2011.
Nnamani ti ko wọle sipo aarẹ lọdun 2011, lo pada wa ni ọdun 2019, to si di ipo naa mu ni ọdun 2019.
Nigba naa ni wọn yan an gẹgẹ bi alaga ile igbimọ asofin agba lori asilo oogun .
Wale Edun
Oun ni alaga ileese ChapelHillDenham Group ni ipinlẹ Eko, to si jẹ ọkan lara awọn banki idokowo to dantọ ni Naijiria.
Ohun ni adari banki Stanbic IBTC tẹlẹri to si ni imọ nipa idokowo, Isẹ ifowopamọ, imọ isiro ati eto ọrọ aje ni agbaye.
Sunday Dare
Oun ni minisita fun ọrọ ọdọ ati ere idaraya ni Naijiria ni ijọba to ṣẹsẹ kuro lori oye. Aarẹ Muhammadu Buhari lo yan an si ipo ni ọdun 2019 lati rọpọ minisita Solomon Dalung.
O ni iwe ẹri giga ni imọ ofin lagbaye ati ibasepọ laarin awọn orilẹede, to si jẹ onimọ nipa eto iroyin ni gbogbo ẹka.
Ọjọ Ḳkandinlọgbọn, Osu Karun, ọdun 1966 ni wọn bi onimọ nipa eto iroyin naa to si ti sisẹ ni awọn ileeṣẹ iroyin fun ọdun marundinlọgbọn.
Oun ni alasẹ ileeṣẹ Nigerian Communications Commission tẹlẹri.

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn miran to tun seese ki ẹ ri ni ijọba Tinubu ni Abubakar Bagudu to jẹ gomina ipinlẹ Kebbi tẹlẹri, Simon Lalong to jẹ gomina ipinlẹ Plateau tẹlẹri, James Faleke to n ṣoju ẹkun Ikeja ni ile igbimọ asọfin agba, to si jẹ alaga ijọba ibilẹ Ojodu LCDA laarin ọdun 2004 si 2011.
Bayo Onanuga to jẹ gbajumo oniroyin ati oloselu naa seese ko wa ni ijọba Tinubu ati Nuhu Ribadu to wa lati ipinlẹ Adamawa, ti wọn si bi ni ọdun 1960.














