Ìdí rèé tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, TUC fi wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì lórí àfikún owó èpo bẹntiróò

Aworan ami idanimọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC

Oríṣun àwòrán, NLC/TUC

Ẹgbẹ oṣiṣẹ meji to lewaju lorileede Naijiria ti wọgile iyanṣẹlodi ti wọn ti ṣaaju kede pe awọn yoo gunle lỌjọru ọjọ Keje oṣu Kẹfa.

Iyanṣẹlodi naa ko ṣẹyin alekun owo bẹntiroo ti ijọba Naijiria kede.

Ẹgbẹ mejeeji sọ ipinnu yi lẹyin ipade kan pẹlu awọn aṣoju ijọba apapọ ni Aso Rock lọjọ Aje.

Lọsẹ to kọja lawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ yi fi gbendeke lelẹ fun ijọba tii ṣe ọjọ Iṣẹgun ọjọ Kẹfa oṣu Kẹfa lati da owo epo pada bi bẹẹ kọ iyanṣẹlodi jakejado Naijiria yoo bẹrẹ ni ọjọ Keje oṣu Kẹfa.

Olori oṣiṣẹ ọfisi aarẹ Femi Gbajabiamila lo kede ipinnu ẹgbẹ oṣiṣẹ eleyi ti aarẹ ẹgbẹ NLC Joe Ajero naa jẹri si.

Ikede yi waye lẹyin wakati mẹfa ijiroro lori ọna ati yanju aawọ yi.

Idi ti a fi wọgile iyanṣẹlodi-NLC,TUC

Aworan Atẹjade ti NLC TUC buwọlu

Oríṣun àwòrán, NLC/TUC

Atẹjade kan lati ọwọ awọn olori ẹgbẹ NLC ati TUC salaye pe ọkan lara awọn idi tawọn fi wọgile iyanṣẹlodi ni lati faaye silẹ fun agbekalẹ igbimọ kan lati ọdọ ijọba eleyi ti yoo ṣagbeyẹwo afikun owo oṣu oṣiṣẹ.

Wọn yoo ṣagbeyẹwo asiko ati ilana ti wọn yoo fi ṣe eto yi.

Bakan naa ni wọn lawọn,ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ, yoo ṣagbeyẹwo eto owo iranwọ ti banki agbaye fẹ ṣe ati ọna ti owo yi yoo fi de ọwọ awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ.

Bẹẹ ni wọn lawọn fẹ ki ijọba ṣajinde eto yiyi ọkọ elepo pada si ti gaasi ti wọn ṣaaju ṣadehun pẹlu awọn aaye ikọṣẹ lọdun 2021.

Wọn tun lawọn fẹ ki ijọba wo ọna ti wọn yoo fi tete ṣatunṣe awọn ile iṣẹ ifọpo Naijiria ni kiakia.

Wọn tun lawọn fẹ ki ijọba ṣetolati tun awọn oju ọna ṣe ki wọn si tun mu atunto ba reluwee ju ti tẹlẹ lọ.

Lakotan ẹgbẹ oṣiṣẹ ni ipade mii yoo waye laarin ijọba ati ẹgbẹ oṣiṣẹ lọjọ Kọkandilogun oṣu yi nibi ti wọn yoo ti ṣetyo amuṣẹ gbogbọ awọn eto ti wọn la kalẹ.

Aarẹ Bola Tinubu lo kede pe koni si ẹunwo lori owo epo bẹntiroo mọ lasiko iburawọle sipo rẹ lọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Karun.

Ọrọ yi da wahala silẹ ni paapa lẹka karakata epo bẹntiroo.

Ni ilẹ oni to mọ, ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo ni Naijiria NNPCL ti kede iye owo epo to wa laarin 480-550.

Owo epo to wa ni nkan bi igba naira ti wa fo lọ soke di bi ẹẹdẹgbẹta Naira le.

Alekun yi lo mu ki ẹgbẹ oṣiṣẹ kede iyanṣẹlodi nitori owo oṣu oṣiṣẹ kere lati le kaju alekun yi.

Owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ni Naijiria lọwọlọwọ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira.

Afikun owo epo bẹntiroo lọpọ igba a si maa mu alekun ba iye owo ọja ni Naijiria.

Ilé ẹjọ́ gbé gidínà ìpinnu ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, TUC láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ nibi iwọde kan

Oríṣun àwòrán, stringer

Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye ọrọ oṣiṣẹ ati agbanisiṣẹ lorilẹede Naijiria, NIC ti da ẹgbẹ oṣiṣẹ lọwọ kọ pe wọn ko gbọdọ gunle iyanselodi kankan bayii lori ọrọ yiyọ owo iranwọ ori epo bẹntiro.

Ijọba apapọ gba aṣẹ ile ẹjọ naa lọjọ Aje lati gbegi dina ipinnu ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC lati gunle iyanṣẹlodi yoowu.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ lori ẹbẹ fun iyọnda ti wọn gbe ka iwaju ile ẹjọ ọhun, Onidajọ O.Y. Anuwe paṣẹ fun awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa lati maṣe gunle iyanṣẹlodi ti wọn n gbero rẹ tabi eyikeyi yoowu titi di igba ti wọn yoo fi ṣe idajọ lori ẹjọ to wa niwaju ile ẹjọ naa ni lọjọ karun un oṣu kẹfa ọdun 2023.

Ọjọru lẹgbẹ oṣiṣẹ NLC n gbero lati gunle iyanṣẹlodi tẹlẹ

Adajo naa tun paṣẹ pe ki wọn fi iwe ipẹjọ lati ile ẹjọ naa ṣọwọ si awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ fun igbẹjọ naa ti yoo waye ni ọjọ kokandinlogun oṣu kẹfa.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC n gbaradi lati bẹrẹ iyanṣẹlodi l’Ọjọru ki ile ẹjọ to pa aṣẹ yii.

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC , Joe Ajaero kede gbendeke Ọjọru fun ijọba apapọ, paapaajulọ ileeṣẹ epo rọbi Naijiria, NNPCL lati da owo epo pada si iye to wa tẹlẹ

Ajaero fi kun un pe bi ijọba apapọ ba kuna lati ṣe eyi, iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ lẹgbẹ oṣiṣẹ yoo gunle

Ẹgbẹ́ òsìṣẹ́ NLC fárígá lórí àfikún owó epo bẹntirol tí NNPC kéde

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, NLC ti kede aidunnu wọn lori ikede ileeṣẹ epo bẹntirol ni Naijiria, NNPC pe afikun ti de ba iye ti wọn n ta jaala epo ni Naijiria.

Ninu atẹjade ti aarẹ NLC, Joe Ajaero fi lede lo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa ti o ni o waye lasiko ti ijiroro ṣi n lọ lọwọ lori ọna abayọ si Subsidy ti wọn yọ naa.

Ajaẹro ni ko tọ si NNPC lati kede iye tuntun naa lai fun awọn laaye lati pari ijiroro pẹlu ijọba nitori inira ti igbesẹ naa yoo muba awọn araalu.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ naa wa kesi ijọba apapọ lati paṣẹ fun NNPC lati fagile igbeṣẹ wọn nitori inira, iya ati iṣẹ ni yoo mu ba awọn araalu ni asiko yii.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Wọn ni eyi yoo fun wọn laaye lati jiroro pẹlu ijọba lori igbeṣẹ naa ati ọna ti yoo fi rọrun fun awọn araalu.

Amọ wọn ni o dabi ẹni pe ijọba ti pa ọkan wọn pọ lori igbeṣẹ ati yọ iranwọ epo ni Naijiria lai fi aaye silẹ fun ijiroro pẹlu awọn aṣoju awọn araalu.

NLC ni ohun ti awọn n bere fun lasiko yii ni ki ijọba fi aaye fun ijiroro lati wa ọna ti igbeṣẹ naa ko fi ni nira fun awọn eniyan

Ọ̀wọ́ngógó gbòde kan! NNPC ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ta jáálá epo bẹntirol ní N488 ní ìpínlẹ̀ Eko.

Aworan

Ọ̀wọ́ngógó gbòde kan! NNPC ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ta jáálá epo bẹntirol ní N488 ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ileeṣẹ epo bẹntirol lorilẹede Naijiria, NNPC ti kede afikun owo epo bẹntirol lorilẹede Naijiria.

NNPC fi lede ninu atẹjade ti wọn fi lede loju opo Twitter wọn lati kede iye owo tuntun ti wọn ta epo bayii.

NNPC ni bi oju ọja ṣe ri bayii lo mu ki awọn ṣe afikun iye ti wọn n ta epo bayii.

Bakan naa ni wọn fikun un pe epo naa yoo wa ni yanturu fun awọn araalu lati ra.

Amọ wọn tọrọ aforiji lọwọ awọn araalu ti iye owo ti wọn n ta jaala epo naa le fa inira fun.

Bio tilẹ jẹpe wọn ko sọ oye tuntun ti wọn yoo ma ta epo naa, saaju ni iroyin ti gbe pe epo bẹntirol ti di ọwọngogo bayii lẹyin ti awọn ileepọ gbe owo gọbọi le iye owo ti wọn n ta jaala epo.

Ni awọn ileepo NNPC ni wọn ti ri ibi ti wọn ti n ta jaala epo ni N488, ti awọn miran si n ta ni N511 ati bẹẹ bẹẹ lọ!