Nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Tomiwa Omolewa, alága PMS tuntun nípìnlẹ̀ Oyo tó rọ́pò Auxilliary

Oríṣun àwòrán, Screenshot/BCOS
Alaga tuntun fun igbimọ to n mojuto ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀ èrò nipinlẹ Oyo, ti ṣapejuwe iyansipo rẹ gẹgẹ bi ayipada ọtun.
Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ iroyin BCOS sọ, Alhaji Tomiwa Omolewa ni òun ṣe ileri fun Gomina Seyi Makinde pe "wahala kankan ko ni sẹlẹ ni ipinlẹ Oyo.
" Gbogbo ohun ti wọn ba fẹ, ni a maa ba wọn fẹ; ibi ti wọn ba fi ọwọ́ wa si, ni ọwọ́ wa yoo wa; nǹkan ti wọn ba ni ka ṣe, la o ṣe."
O ni àwọn yoo fọwọsowọpọ pẹlu ìjọba.
Bákan naa lo ṣapejuwe ìgbésẹ̀ gomina, lati yan igbimọ PMS gẹgẹ bi awokọṣe kaakiri awọn ipinlẹ ni Naijiria.
Ọjọ Aiku ni Gomina Makinde kéde Alhaji Omolewa gẹ́gẹ́ bi alaga tuntun fun igbimọ Park Management System, PMS.
Iyansipo rẹ waye lẹyin ti gomina yọ alaga tẹlẹ, Ọgbẹni Mukaila Lamidi, ti ọpọ mọ si Auxiliary, kuro nipo lọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣù Karùn-ún.
Ṣaaju Ìyànsípò rẹ, Alhaji Tomiwa Omolewa, ti ọpọ mọ si 'Tommy' ti fi igba kan jẹ́ akọ̀wé igbimọ PMS.
O ti n ṣiṣẹ́ awakọ̀ fun ọpọ ọdun.
Bakan naa lo jẹ ọmọ ẹgbẹ́ NURTW tó kógbá wọlé.
Ki lo ti ṣẹlẹ̀ sẹyin?

Oríṣun àwòrán, Others
Lẹ́yìn ikede gomina ni iroyin jade pe wahala sẹlẹ ni awọn agbegbe kan nílùú Ibadan.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa yabo ile ìtura kan to jẹ ti alaga nigba kan ri ọ̀hún, Auxiliary, níbi ti wọn ni awọn ti ba ọpọlọpọ nnkan ija oloro bi ìbọn, àdá, òògùn, miliọnu mẹta Naira, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn ọlọpaa ni eeyan mejidinlọgọrin ni awọn ko nile 'Auxiliary' lasiko ti wọn ya wọ ibẹ.
Iroyin ni bi o tilẹ jẹ pe Auxiliary ti na papa bora, ẹmi eeyan kan ba iṣẹlẹ lọ lasiko ti wọn kọju ija si awọn agbofinro. Lẹyin naa ni wọn kede pe awọn n wa Ọgbẹni Mukaila Lamidi fúnra rẹ.
Sugbọn ninu ọrọ kan to sọ lori eto ileeṣẹ redio kan nílùú Ibadan, Ọgbẹni Lamidi sọ pe ile oun kọ ni ọlọpaa ti ko awọn nnkan ija naa.
O ni olóore oun ni Gomina Makinde.
Ninu oṣu karun ọdun 2019 ni Makinde fi ofin de ẹgbẹ awakọ NURTW ati RTEAN nitori wahala ti wọn fa lori ipo adari.
Lẹyin eyii si ni o ṣe idasilẹ ajọ PMS to n mojuto igbokegbodo ọkọ eleyii ti Auxiliary ati igbimọ rẹ n ṣe akoso fun.












