Èrò aráàlú ṣọ̀tọ̀tọ̀ lẹ́yìn tí ìjọba Amẹrika fi ohun ìjà olóró ṣọwọ́ sí ìjọba Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFRICOM
Ijọba ilẹ Amẹrika ti fi awọn ohun ija oloro ṣowọ si Naijiria ninu igbiyanju rẹ lati ran ijọba apapọ lọwọ lati koju eto aabo to mẹhẹ.
Eyii lo jẹyọ ninu atẹjade kan loju opo X ileeṣẹ ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ ilẹ Afrika, United States Africa Command (AFRICOM).
AFRICOM sọ pe ibaṣepọ to dan mọran lo wa laarin ijọba orilẹede mejeji, Amẹrika si ṣẹtan lati ran Naijiria lọwọ lati koju iṣoro eto aabo.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika fi ado oloro ṣọwọ si ibuba awọn agbesunmọmi nipinlẹ Sokoto.
Lẹyin ikọlu naa ni Aarẹ Amẹrika, Donald Trump sọ pe oun tun le ṣe ikọlu mii si awọn agbesunmọmi ni Naijiria ti wọn ko ba dẹkun fifi ẹmi awọn ọmọlẹyin Kristi ṣofo.
Ẹwẹ, ijọba Amẹrika ko sọ ni pato irufẹ ohun ija oloro to fi ṣọwọ si Naijiria.
Wayi o, awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori igbesẹ Amẹrika lati fi ohun ija oloro ranṣẹ si Naijiria.
Ki ni awọn eeyan n sọ?
Sẹnetọ to n sọju aringbungbun ipinlẹ Kaduna nile aṣofin agba, Shehu Sanni ti sọ pe ohun to dara ni Amẹrika ṣe bo ṣe fi ohun ija ṣọwọ si Naijiria.
Nigba to n gboriyin fun Amẹrika loju opo X rẹ, Sanni sọ pe awọn orilẹede mii ti wọn ni awọn fẹran Naijiria gbọdọ wo awokọṣẹ Amẹrika lati ṣe iranlọwọ bẹẹ dipo ki wọn kan maa fi ohun ranṣẹ nikan.
O ni "A o tẹwọgba gbogbo igbesẹ lati gbẹmi awọn ọdaran bii Bello Turji, Adamu Aleru, Baleri atawọn ọdaran mii ni Zamfara."

Oríṣun àwòrán, X
Lojuo po X, awọn ọmọ Naijiria kan n gboriyin fun ijọba Amẹrika fun igbesẹ naa, bẹẹ lawọn kan n sọ pe a funni ni fila fi gba odidi ori lọwọ ẹni l'Amẹrika.
Awọn kan tilẹ sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ awọn agbesunmọmi ni yoo lo awọn ohun ija naa ni ikẹyin.
Awọn ọmọ Amẹrika mii tun sọ loju opo X naa pe ko tọ ki ijọba awọn maa fi owo ori awọn koju ija si agbesunmọmi ni Afrika nitori ija naa ko kan awọn.

Oríṣun àwòrán, X















