Àlàyé lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Edo tó sọ akẹ́kọ̀ọ́ àti èèyàn 52 dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Edo

Oríṣun àwòrán, Edo State Police Command

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn akẹkọọ fasiti Ambrose Alli wa lara awọn eeyan mejilelaadọta ti ọlọpaa ko lọ sile ẹjọ lẹyin ifẹhonuhan kan to waye ni ijọba Esan West, nipinlẹ Edo.

Ṣaaju iṣẹlẹ naa lawọn olugbe ilu Ekpoma ti gunle ifẹhonuhan lori iṣẹlẹ ijinigbe to n waye nibẹ lemọlemọ.

Amọ asiko ti ifẹhonuhan ọhun n lọ lọwọ ni nnkan yiwọ, ti awọn kan si bẹrẹ si n ja ṣọọbu oniṣọbu lati ji ọja inu rẹ ko lọ.

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ

Gẹgẹ bii ohun ti awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa sọ fun awọn akọroyin, lemọlemọ lawọn ajinigbe n ji araalu ati ọmọ ile ẹkọ gbe lọ ni Ekpoma ti ijọba ko si ṣe nnkankan nipa rẹ.

Wọn ni bi wọn ṣe n ji awọn akẹkọọ gbe ni wọn n gbẹmi wọn.

Awọn akẹkọọ naa tilẹ sọ pe nigba mi, wọn le ji ẹgbọn gbe lọjọ kan, ki wọn ji aburo rẹ gbe lẹyin ọjọ ti awọn mọlẹbi ẹni naa ba ti san owo itusilẹ rẹ tan.

Amọ ṣa, wọn ni o fẹ farajọ pe awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun lọwọ ninu awọn ijinigbe ọhun.

Gẹge bii awọn akẹkọọ naa ṣe sọ, ijọba ipinlẹ Edo tabi awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ko sọ nnkankan nipa iṣẹlẹ naa, wọn ko si bikita eyii to mu ki wọn ya si igboro ki ọrọ lati fẹhonuhan.

Lẹyinorẹyin, ọrọ naa yiwọ, ọlọpaa si ko ọpọ eeyan ti ọmọ ile ẹkọ AAU wa lara wọn.

Ọlọpaa ipinlẹ Edo

Oríṣun àwòrán, Edo State Police Command

Ki lo ṣẹlẹ nile ẹjọ?

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, inu yara ibusun ni pupọ awọn akẹkọọ ti ọlọpaa mu wa ki wọn to lọ ji wọn, ti wọn si ko wọn sinu ọkọ Black Maria lọ agọ ọlọpaa.

Pupọ ninu awọn obi awọn akẹkọọ naa lo yi ile ẹjọ ka lasiko ti ọlọpaa ko wọn dele ẹjọ pẹlu ipaya.

Ọkunrin kan to pe orukọ ara rẹ ni Abdulsalam sọ fun awọn akọroyin pe awọn ọmọ oun wa lara awọn ti ọlọpaa mu amọ wọn ko kopa ninu ifẹhonuhan kankan.

Agbẹjọro ọlọpaa, P. O Odion to pe awọn akẹkọọ naa atawọn akẹgbẹ wọn lẹjọ fi oniruru ẹsun bii idaluru, idigunjalẹ ati iwa ipa kan wọn.

Amọ nigba to n gbọ ẹjọ naa, adajọ Wlliam Aziegbemi, sọ pe oun ko lagbara lati gbọ ẹjọ ọhun, o si rọ agbẹjọro awọn olujẹjọ pe ko bẹbẹ fun beeli nile ẹjọ giga Ubiaja.

Lẹyin naa lo ni ki wọn fi awọn akẹkọọ naa si ọgba ẹwọn Ubiaja titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2026 yii.

Tu awọn akẹgbẹ wa silẹ tabi ki o ri ija wa – Ẹgbẹ awọn akẹkọọ NANS

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ, NANS, ti ke si ileeṣẹ ọlọpaa ko tu awọn akẹkọọ naa silẹ lai fọta pe.

Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Adeyemi Ajasa, sọ ninu atẹjade kan pe ijọba gbọdọ ṣe ojuṣe rẹ, eyii tii ṣe idaabobo ẹmi ati dukia araalu, dipo ko maa gbe wọn lọ sọgba ẹwọn.

NANS sọ pe iwa ti ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo n wu si awọn akẹkọọ naa ko tọ o si jẹ titẹ etọ araalu loju mọlẹ.