Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọkùnrin tó 'gún ìyàwó rẹ̀ pa' tóun náà sì pa ara rẹ̀ l'Ogun

Oríṣun àwòrán, CP Monday Agbonipa/BBC
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ kan to waye ni ileegbe River Valley Estate to wa lagbegbe Ojodu Berger nibi ti a gbọ pe ọkunrin kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Ayoola Ayanwale ti gun iyawo rẹ, Ganiyat Ayobami Ayanwale pa.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fesi lori iṣẹlẹ naa tẹlẹ, iyalẹnu lo ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to n gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun.
Ojule kọkanlelogun, adugbo Olutayọ Alao, ninu ileegbe River Valley Estate, Ojodu-Berger ni ile ti tọkọ-taya naa n gbe wa, nibẹ si ni iṣẹlẹ aburu naa ti waye.
Akọbi awọn tọkọ-taya yii to jẹ obinrin ni wọn pe ni ọmọ ọdun mejila; ekeji to jẹ ọkunrin ni wọn pe ni ọmọ ọdun meje, nigba ti abigbẹyin wọn jẹ ọmọ ọdun mẹta.
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, l'Ọjọbọ ọsẹ to kọja yii, iyẹn ọjọ kẹjọ oṣu Kinni, ọdun 2026 ni wọn sọ pe aawọ bẹ silẹ laaarin awọn ọkọ ati iyawo naa to si mu ki Ayanwale lu iyawo rẹ lalu bami.
Gẹgẹ bi awọn alabagbe wọn ṣe ṣalaye, gbogbo bi Ayọọla ṣe n lu iyawo rẹ yii ni awọn ọmọ mẹtẹẹta to wa laaarin wọn n gbiyanju lati bẹ baba wọn, ṣugbọn ti ko gbọ.
A gbọ pe nigba to ya ni Ayanwale lọ fa ọbẹ yọ, to si fi gun iyawo rẹ lọna bii marun-un, ko to di pe ẹlẹmi gba a.
Ariwo ti awọn ara agbegbe naa gbọ ni wọn fi sare lọ sibẹ lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn debẹ, to jẹ pe oku Ganiyat ni wọn ba ninu agbara ẹjẹ.
Ọkan lara awọn alabagbe wọn ti ko fẹ ka darukọ rẹ sọ pe ki awọn ara adugbo to debẹ ni Ayọọla ti na papa bora, ti ko si sẹni to le sọ pato ibi to gba salọ.
Alabagbe naa ni o ṣee ṣe ki Ayanwale gba ẹyinkule fo fẹnsi salọ, ki ọwọ ma ba a tẹ ẹ.
Lara awọn ara agbegbe naa to ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe Ganiyat ko tii ku nigba ti wọn yoo fi debẹ, ti wọn si lo n beere fun omi lati mu.
Amọ, igba ti wọn yoo fi gbe e de ile iwosan to wa nitosi fun itọju, lawọn dokita sọ pe oku ni wọn gbe wa.
Awọn dokita ni ọbẹ ti Ayọbami fi gun iyawo rẹ ti ge ifun rẹ, bẹẹ si ni ko le mi daadaa mọ, eyi ni wọn si lo ṣokunfa bi iku rẹ ṣe tete ya.
BBC Yoruba ṣabẹwo sile oloogbe
BBC Yoruba ṣe abẹwo si ile naa laaarọ oni tii ṣe ọjọ Aje lati ba awọn ara ile naa sọrọ, ṣugbọn paro-paro ni agbegbe naa da.
Gbogbo awọn ti a gbiyanju lati ba sọrọ ni wọn sọ pe awọn ko le sọ ohunkohun.
Amọ, ọkan lara awọn ara inu ile ti wọn jọ n gbe, Ọgbẹni Philip lo pada ba BBC sọrọ, to si ṣalaye lẹkunrẹrẹ ohun to mọ nipa tọkọ-taya naa.
Ọgbẹni Philip lo jẹ ko di mimọ pe ọdun kẹta ataabọ ree toun ti n gbe ninu ile naa pẹlu idile ọhun, to si loun mọ iyale ile, ọlọmọ mẹta naa daadaa, koda, o ni gbogbo igba lo maa n wa si ọdọ iyawo oun lati ba wọn ṣere.
"Ohun ti mo mọ nipa awọn tọkọ taya yii ni pe akikanju obinrin ti a le pe ni abiyamọ toootọ ni Arabinrin Ganiyat Ayanwale.
Obinrin yii lo n tọju awọn ọmọ, to si n gbọ bukata inu ile. Iṣẹ alase ounjẹ igbalode lo n ṣe, o si ko awọn eeyan mọra lagbegbe yii. Kii baayan ja, o si maa n ṣere daadaa.
Ni ti ọkọ rẹ, kii ba ẹnikẹni sọrọ yatọ si 'kaarọ-kaalẹ, ti ẹ ko ba wa nita lasiko to ba wọle, ko sẹni to maa ri i.
Niṣe lo n wọle, jade bi ọrọ inu igi. Ko sẹni to le sọ iru iṣẹ to n ṣe, kii sii da si bi awọn ọmọ ṣe n jẹun.
Lati igba ti mo ti de adugbo yii, n ko ri ibi ọkunrin yii ti lu iyawo rẹ ri, ṣugbọn mo maa n gbọ pe o maa n lu obinrin naa daadaa tẹlẹ.
Ati pe mo ti ri apẹẹrẹ lilu lẹẹmeji lara obinrin yii, ṣugbọn n ko ri wọn nibi ti wọn ti n ja.
Igbe aye 'ko kan mi' ni ọkunrin yii n gbe, idi ree to fi jẹ pe iyawo rẹ lo n gbọ bukata ile,'' Ọgbẹni Phillip ṣalaye.
Nigba to n ṣalaye siwaju sii lori ohun to ṣẹlẹ lọjọ naa, o sọ pe oun ko si nile lasiko iṣẹlẹ naa, to si nibi toun lọ loun ti n gba ipe loriṣiriṣi.
O sọ pe nnkan bi agogo mẹfa irọlẹ loun jade, ati pe nigba toun maa fi pada si ile, agogo mẹwaa alẹ ti kọja, to si loun lọ sun ni nitori to ti rẹ oun.
Ọgbẹni Philip jẹ ko di mimọ pe ṣadede loun ri ipe lati ọdọ ọkan lara awọn ti wọn jọ n gbe ni nnkan bi agogo kan our.
O sọ pe ẹni naa lo ṣalaye fun oun pe Iya Ade, iyẹn Ganiyat ti ku.
"Igba ti mo jade sita ni mo n gbọ pe Iya Ade, nitori orukọ ọmọ rẹ la maa fi n pe, ti ku.
O si jẹ iyalẹnu fun mi, igba naa ni wọn too ṣẹṣẹ ṣalaye bi gbogbo iṣẹlẹ naa ṣe lọ."
''Ayanwale lo ran ọmọ rẹ ni oogun apẹfọn''
Ọgbẹni Philip ṣalaye siwaju pe otitọ ni Ayanwale ran ọkan lara awọn ọmọ rẹ lati lọ ra oogun apẹfọn 'sniper' wa, ṣugbọn ti ọmọ naa ko ri ra.
O ni bo ya ogun sniper lo fẹẹ lo fun iyawo rẹ tẹlẹ, ko to di pe o lọ yọ ọbẹ.
Bakan naa lo sọ pe awọn ko mọ igba to pada wa sile, nitori to sọ pe awọn ko kofiri rẹ rara.
O nigba ti awọn yoo fi wo inu yara ati ayika wọn, kayeefi lo jẹ pe wọn ko ri apa ẹjẹ kankan nilẹ.
Aburo rẹ ni Ganiyat kọkọ pe ko too ku
Philip tun ṣalaye pe ko to di pe Ganiyat ku, aburo rẹ lo kọkọ pe lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun un, ati pe bo ṣe n sọrọ naa ni ẹjẹ n da ni ara rẹ.
"Bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ, niṣe lo sare bọ sita, to si jokoo lori aga to wa niwaju ile.
Ko pe awọn to wa ninu ile fun iranlọwọ, aburo rẹ lo n pe lori foonu lati sọ ohun to ṣẹlẹ fun un.
"Ka ni pe o tete sọ fun awọn araale ni, o ṣee ṣe ki wọn tete gbe e lọ sile iwosan fun itọju, ko ma si gbabẹ ku.
Bo ya ohun to n ro ni pe ko nii ba iṣẹlẹ naa lọ, ni ko jẹ ko sọ fun ara inu ile, lai mọ pe ohun to ṣẹlẹ kọja agbara."
Alabagbe awọn lọkọ laya naa sọ pe iyalẹnu nla lo tun jẹ fun wọn nigba ti awọn bẹrẹ sii gbọ pe ọkunrin to gun iyawo rẹ pa ti pa ara rẹ si agbegbe miran.
O ni awọn ko ri oku naa, lati mọ bo ya otitọ ni.
"Mo kan pada gbọ ni wi pe ọkunrin naa ti lọ gba ẹmi ara rẹ, n ko mọ ibi to ti ṣẹlẹ.
Nko ṣe iwadii siwaju nitori pe ohun gbogbo ye Ọlọrun.
Aburo obinrin naa wa lalẹ ọjọ naa, oun lo si wa ṣeto to yẹ," Philip kadi ọrọ rẹ nilẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Oluṣeyi Babaṣeyi jẹ ko di mimọ pe ọjọ kẹsan, oṣu Kinni, ọdun 2026 ni Ayọọla gbẹmi ara rẹ.
Babaṣeyi ṣalaye pe otitọ ni iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa iku awọn mejeeji.















