Ibi tí ìgbésẹ̀ yíyan Awujale tuntun dé dúró rèé

Ẹnu ọna to wọle si aafin Awujale

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lonii ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu Kinni, ọdun 2026 ni idilẹ ti oye Awujale kan niluu Ijebu Ode yoo korajọ lati bẹrẹ igbesẹ yiyan ọmọ oye tuntun.

Lẹyin eyi ni wọn yo ko gbogbo orukọ awọn ọmọ oye naa tọ awọn Afobaje lọ fun igbesẹ to kan.

Igbesẹ yii ni yoo maa waye lẹyin ti ijọba ibilẹ Ijebu-Ode kede pe wọn le bẹrẹ igbeṣe naa ni ibẹrẹ ọdun yii.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu lẹta kan ti Oke Abiodun Adebanjo, to jẹ akọwe ijọba ibilẹ naa buwọlu lọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2026.

Lẹta ọhun sọ pe awọn idile ọhun ni ọjọ mẹrinla pere lẹyin ti wọn gba lẹta naa lati gbe igbesẹ ki wọn si bun ijọba ibilẹ ọhun gbọ nipa ọjọ, akoko ati gbagede ti fifa ọmọ oye kalẹ naa yoo ti waye.

Lẹta ijọba ibilẹ Ijede-Ode si idi ti oye Awujale kan

Oríṣun àwòrán, Oke Abiodun Adebanjo

Ṣe lootọ ni pe idile Fusengbuwa ti kede ọmọ oye?

Ẹwẹ, idile Fusengbuwa ti sọ pe iroyin ofege ni iroyin kan to ni awọn ti yan ọmọ oye tuntun lati di Awujale tuntun fun Ijebu Ode.

Ninu atẹjade kan to de sọwọ BBC News Yoruba, Idile Fusegbuwa ni ọjọ Aje, ọjọ Kejila oṣu kinni ọdun 2026 ni ipade yoo waye lati yan ọmọ oye tuntun.

Idile naa fikun pe ijoko ipade ti yoo waye ni ọjọ Aje ni awọn yoo ti yan awọn ọmọ oye ti wọn yoo fi orukọ wọn ransẹ si awọn Afọbajẹ.

Atẹjade naa sọ pe "Ni bayii, a ko ti yan Awujalẹ kankan, lẹyin ipade ọjọ Aje la o fi orukọ ransẹ si awọn Afobajẹ lati tun ṣe ayẹwo siwaju."

Saaju ni ijọba ipinlẹ Ogun ti kọkọ da gbogbo eto ati ilana yiyan ojulowo ọmọ oye fun ipo Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, eyi ti mọlẹbi Fsengbuwa n ṣakoso rẹ duro fun igba diẹ.

Aṣẹ ti ijọba ipinlẹ Ogun pa, la gbọ pe o waye lati le ṣabojuto ilana to yẹ, eyi ti ko nii si ojusaaju ninu eto lati yan ọmọ oye, ati nipa titẹle ofin ti ko nii pada gbe wọn de ile-ẹjọ.

Ki lo ti sẹlẹ ṣaaju lori oye Awujale Ijebu Ode?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin ipapode Oba Sikiru Adetona, ọpọ eeyan lo ti erongba wọn lati di Awujale tuntun, ṣugbọn eyi to mi lẹ titi ni ti Gbajumọ Olorin Fuji, Wasiu Ayinde.

Wasiu Ayinde Omogbolahan (K1), kede erongba rẹ lati du ipo ọba Awujalẹ ilẹ Ijebu ninu lẹta kan tí Wasiu Ayinde fi ranṣẹ si Alaga ile ọmọ oye Fusengbuwa lo ti kede erongba rẹ lati di Awujalẹ tuntun.

"Emi, Otunba Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe, MON, fi asiko yii kede fun ile ọmọ oye Fusengbuwa, erongba mi lati jẹ ki wọn wo mi ṣe fun itẹ Awujale ilẹ Ijebu to ṣófo, ni ibamu pẹlu ofin ilẹ Ijebu ati ti oye jijẹ ipinlẹ Ogun."

Idíle Fusengbuwa ti ìlú Ijebu Ode kede pe gbajumọ olorin Fuji nnì Wasiu Ayinde kii ṣe ọmọ idile awọn ati pe ko le díje du oye Awujale ilẹe Ijebu labẹ ìdíle naa.

Ikede yii lo n waye nibi ipade awọn olori idile naa ti wọn ṣe ni Ile Nla lọjọbọ, ọjọ Kọkanla, oṣù Kejila, ọdun 2025.

Agbẹnusọ idíle Fusengbuwa, Abiodun Ogidan ninu atẹjade kan to gbori ayelujara lọjọbọ sọ pe awọn ti ṣe agbeyẹwo ìwe ti Wasiu Ayinde gbe kalẹ lati fìdi rẹ mulẹ pe ọmọ idíle naa loun.

Ó ní ìwé náà ṣàfihàn rẹ̀ pé K1 kìí ṣe ara àwọn ní ìdílé oyè Fusengbuwa.