Ìjọba ilẹ̀ òkèrè dá $9.5m tí àwọn kan jí kó lọ sílẹ̀ wọn padà fún Naijiria

Aarẹ Tinubu pẹlu aṣọ funfun ati fila idanimọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ilẹ Jersey, to wa ni erekusu Channel Islands laarin ilẹ Gẹẹsi ati orilẹede France ti kede pe awọn ti ṣetan lati da owo ti iye rẹ to $9.5 miliọnu (£7 tabi N13.6b) fun ijọba Naijiria.

Owo ọhun ni iroyin sọ pe awọn kọlọrọsi ẹda ji ko lọ silẹ naa lọpọ ọdun sẹyin.

Gẹgẹ biii ohun ti a gbọ, ijọba Naijiria yoo lo owo naa lati gbọ bukata awọn ohun amayedẹrun laarin ilu.

Igbesẹ dida owo yii pada lo waye lẹyin adehun, MoU, to waye laarin adajọ agba Jersey, ọgbẹni Mark Temple KC ati ijọba apapọ Naijiria.

MoU naa ni ijọba orilẹede mejeji tọwọ bọ lati da owo ti iye rẹ to $300m pada si Naijiria.

Nigba to n sọrọ lori owo naa, adajọ agba Naijiria, Lateef Fagbemi, sọ pe ijọba apapọ yoo lo owo ọhun fun awọn ohun ti wọn fẹnuko le lori ninu adehun ti wọn tọwọ bọ.

Fagbemi ni "Aṣeyọri wa lati gba owo yii pada n fi han pe ibaṣepọ ijọba Naijiria atawọn ojugba rẹ nilẹ okere lati ri pe awọn kan ko ko ọrọ wa lọ silẹ okere mọ n so eso rere."

O ni owo naa wa lara eyii ti ijọba yoo lo lati pari opopona to so ilu Abuja pọ mọ ilu Eko.

Nigba ti Temple n sọrọ ni tirẹ, o sọ pe igbesẹ ọhun fi han pe ilẹ Jersey ko faye gba, bẹẹ ni ko ni faye gba iwa ajẹbanu kankan.

Lọdun 2024 ni ile ẹjọ giga ilẹ naa sọ pe oun gbagbọ pe owo ọhun wa lara eyii ti awọn agbaṣẹse kan ko kuro ni Naijiria lorukọ awọn ọga agba nileeṣẹ ijọba Naijiria lati fi pamọ silẹ awọn.

Ẹwẹ, asiko ijọba Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan ni wọn ṣawari owo naa amọ igbesẹ lati da pada si Naijiria falẹ titi di asiko yii.

Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba ilẹ okere yoo da owo gọbọi ti awọn alaṣẹ ji ko ni Naijiria lọ silẹ wọn pada si Naijiria.

Lọpọ igba ni Aarẹ Naijiria nigba kan ri, ọgagun Sani Abacha to ti di oloogbe ti fi owo ranṣẹ si Naijiria lati ode ọrun lẹyin ti awọn orilẹede to ji owo naa ko lọ da a pada fun ijọba Naijiria.