NCC fẹ máa da owó padà fáwọn oníbàárà tí kò bá rí káàdí ìpé lẹ́yín ìṣẹ́jú àáyá ọgbọ̀n tí wọ́n yọ owó wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ Nigerian Communications Commission (NCC) to n ri si ikansira ẹni lori aago, ti kede igbesẹ tuntun, eyi ti wọn ni awọn yoo maa da owo onibaara to ba fẹ ra kaadi ipe tabi data, pada fun wọn laaarin iṣẹju aaya ọgbọn (30 seconds) bi kaadi naa ko ba wọle sori foonu wọn ti wọn si ti yọ owo naa ninu akanti wọn.
Itumọ eyi ni pe nigba ti wọn ba ti yọ owo ẹni to fẹẹ ra kaadi, ṣugbọn ti ko ri kaadi, ko ni i ju iṣẹju aaya ọgbọ̀n (30 seconds) lọ ti wọn yoo fi da owo naa pada si akanti rẹ.
Fun awọn idunaa-dura ti ko ba tete wọle, ti ko de ọdọ ontaja ati ẹni to fẹ ra kaadi, wakati mẹrinlelogun ti i ṣe ọjọ kan ni NCC ni awọn yoo fi yanju eyi.
Gẹgẹ bi ajọ yii ṣe wi ninu atẹjade ti Adari ẹka ikede NCC Nnenna Ukoha, fi sita, agbekalẹ tuntun yii n waye pẹlu ajọṣepọ banki agba ilẹ wa (CBN).
Ukoha ṣalaye pe ẹka ibaraẹnisọrọ ati banki apapọ mejeeji panupọ lati gbe igbesẹ yii, ki wọn le jọ koju iṣoro ti awọn onibaara maa n ba pade ti wọn si maa n fi sun nigba ti kaadi ipe ko ba ṣee ra.
Iṣoro miran ti wọn tun sọ ni ti network ko ba si, tabi ti iṣoro yowu ba koju wọn.
Bakan naa ni eto yii yoo tun maa fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si onibaara lati mọ boya kaadi to fẹ ra kẹsejari tabi bẹẹ kọ.
O tun wa fun bi eeyan ba ṣesi tẹ ẹka oju opo miran yatọ si eyi to fẹ ra, ati bi eeyan ba ṣeṣi tẹ nọmba to yatọ si eyi to fẹ ra kaadi si.
''Abajade ipade apero pẹlu CBN ati awọn alẹnulọrọ miran ni eyi, yoo si gbera sọ lọjọ akọkọ ninu ọṣu Kẹta ọdun 2026''
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi:
" Igbesẹ yii jẹ abajade ọpọ ipade oloṣu pupọ ti NCC, CBN, Mobile Network Operators (MNOs), Value Added Service (VAS) providers, Deposit Money Banks (DMBs) ati awọn alẹnulọrọ miran jọ ṣe.
"O wa fun awọn iṣoro bii ki eeyan ma ri kaadi ipe tabi data lẹyin ti wọn ti yọ owo, ti onibaara ko si gbọ nnkan kan lati yanju iṣoro naa."
Adari ẹka to n ri si ọrọ awọn onibaara ni NCC, Abilekọ Freda Bruce-Bennett, ṣalaye pe igbesẹ yii yoo tun jẹ ko ṣee ṣe fun NCC ati CNB lati jọ ni opo kan naa ti yoo maa ri si ohun to ba n ṣẹlẹ.
O ni eyi yoo jẹ ki ẹka mejeeji mọ onibaara to fẹẹ ra kaadi ṣugbọn ti ko kẹsẹjari, wọn yoo si jọ ri si idapada owo onibaara bẹẹ lasiko.
"Ni bayii, ki ẹka mejeeji too buwọlu u, awọn ẹka MNO ati banki ti da owo to le ni biliọnu mẹwaa, (N10 billion) pada fun awọn onibaara, fun idunaa-dura ti ko bọ si i."
Abilekọ Bruce-Bennett lo sọ bẹẹ.
O fi kun un pe ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta ọdun 2026 ni ireti wa pe eto idapada yii yoo bẹrẹ.
Ni kete ti ajọ mejeeji ba ti pari ibuwọlu wọn, ti awọn ẹka to kan naa si ti pari eto.












