Kóòtù pàṣẹ kí ìjọba àpapọ̀ gbésẹ̀ lé dúkìá ₦213.2bn tí wọ́n tọpinpin kan Abubakar Malami fún ìgbà díẹ̀ ná

Oríṣun àwòrán, Abubakar Malami (SAN)
Ile ẹjọ giga ilu Abuja ti paṣẹ pe ki ijọba apapọ ṣi gbẹsẹ le dukia ti owo rẹ to ₦213.2bn, eyi ti wọn ni Abubakar Malami, Minisita eto idajọ ati adajọ agba ilẹ wa tẹlẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ ọkunrin meji, fi eru ko jọ.
Mẹtadinlaadọta (57) ni awọn dukia naa ti wọn jẹ ile nla nla bi ile ẹjọ ṣe wi. Abubakar Malami, Abdulaziz ati Abiru—Rahman ti wọn jẹ ọmọ rẹ ni wọn si jọ fi ẹsun kiko dukia naa jọ lọna eru kan.
Olori ẹka ikede fun ajọ EFCC, Dele Oyewale, lo sọ eyi di mimọ l'Ọjọru ana, ninu atẹjade to fi sita.
Apapọ owo awọn dukia olowo iyebiye naa ni wọn lo jẹ ₦213,234,120,000, ti wọn si wa ni Abuja, Kebbi, Kano, ati ipinlẹ Kaduna.
Gbogbo rẹ pata ni ijọba apapọ yoo gbesẹ le na bi igbẹjọ ṣe n lọ lọwọ, gẹgẹ bi ile ẹjọ ṣe paṣẹ.
Adajọ Emeka Nwite paṣẹ naa lẹyin ti agbẹjọrọ fun ajọ EFCC, Ekele Iheanacho,(SAN), rọ kootu naa lati gbe igbesẹ yii.
Lẹyin to gba ipẹ naa wọle, Adajọ Nwite tun paṣẹ pe ki wọn kede igbesẹle yii ninu iwe iroyin ilẹ wa eyikeyi, lati jẹ ki ẹnikẹni to ba ni ohun kan tabi meji lati ṣe pẹlu awọn dukia naa le yọju laarin ọjọ mẹrinla si asiko ikede naa.
Ṣugbọn ko ni i si ikede igbẹyin nigba ti ijọba ba gbẹsẹ le dukia naa patapata gẹgẹ bi Adajọ Nwite ṣe wi.
Igbẹjọ mi-in di ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026, fun abọ ti yoo fi han pe aṣẹ naa ti ri bẹẹ gẹlẹ.
Díẹ̀ lára àwọn dúkìá náà rèé
Ti ipinlẹ Kano ti apapọ owo rẹ jẹ: N16,011,800,000.00:
Zeennoor Hotel: N11,200,000,000.00
Zeennoor Mosque: N84,000,000.00
Zeennoor Old Hotel Building: N280,000,000.00
Rayhaan Hotel Kano: N2,240,000,000.00
Rayhaan Gym Kano: N1,225,000,000.00
Ile iyawo rẹ (Ahmadu Bello Way, Kano): N982,800,000.00
Abuja : N34,685,000,000.00
Duplex : Amazon Street, Maitama: N5,950,000,000.00
Meethaq Hotel (Jabi Branch): N8,400,000,000.00
Meethaq Hotel (Maitama Branch): N12,950,000,000.00
42 Units Bungalow ni Efab Estate: N385,000,000.00
Harmonia Hotels, Area 11 Garki: N7,000,000,000.00
Ti ipinlẹ Kebbi ti apapọ owo rẹ jẹ: N162,195,950,000.00:
Rayhaan University and Education
Rayhaan University Permanent Site: N56,000,000,000.00
Rayhaan University Temporary Site: N37,800,000,000.00
Rayhaan University Third Site: N2,450,000,000.00
Rayhaan University Vice Chancellor House: N490,000,000.00
Rayhaan Model Academy: N11,200,000,000.00
Rayhaan Primary and Secondary School: N8,750,000,000.00
Rayhaan Agro Allied Factory & Commercial
Factory Buildings: N4,200,000,000.00
Factory Machines and Plants Units: N10,500,000,000.00
Factory Mosque: N2,450,000,000.00
Ati bẹẹ bẹẹ lọ
Ilé ẹjọ́ gba béèlì agbẹjọ́rò àgbà Naijiria tẹ́lẹ̀ Malami pẹ̀lú ₦500m àti onídùró méjì

Ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja ti gba beeli agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ Naijiria tẹlẹ, Abubakar Malami, pẹlu ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira (N500m) ati oniduro meji.
Adajọ Emeka Nwite to fun Malami ni beeli naa sọ pe awọn onuduro meji ọhun gbọdọ ni ilẹ lagbegbe Asokoro, Maitama tabi lagbegbe Gwarinpa l'Abuja.
Adajọ tun paṣẹ pe awọn ti yoo ṣe oniduro Malami gbọdọ mu iwe irinna wa sile ẹjọ.
Ẹsun onikoko mẹrindinlogun to da lori jiji owo ilu ko lọ silẹ okeere ni ajọ EFCC fi kan Malami ati ẹbi rẹ.
Dukia to to N8.7bn ni EFCC fẹsun kan Malami wi pe o fi owo ilu ra.
Ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje ni Abubakar Malami agbẹjọ́rò àgbà Naijiria tẹ́lẹ̀ ti ṣọdún tuntun 2026
Ọgba ẹwọn Kuje l'Abuja ni agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ Naijiria tẹlẹ, Abubakar Malami, ti ṣe ọdun tuntun 2026, lẹyin ti ile ẹjọ paṣẹ pe ko wa lahamọ lori ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan an.
Ajọ EFCC gbe Malami ati ọmọkunrin rẹ, Abubakar Malami Jnr ati arabinrin kan, Bashir Asabe, lọ ile ẹjọ lori ẹsun onikoko mẹrindinlogun to da lori jiji owo ilu ko lọ soke okun ati aṣilo ọfiisi.
EFCC fẹsun kan Malami pe o lo ọfiisi rẹ nigba to wa nipo agbẹjọro agba lati ji owo ilu ko eyi ti wọn lo fi ra oriṣiiriṣii dukia bii ilẹ, ile ati ile itura kaakiri orilẹede Naijiria to fi mọ Abuja, ipinlẹ Kebbi ati Kano.
Amọ, awọn eeyan mẹtẹẹta sọ fun ile ẹjọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti EFCC fi kan awọn.
Lẹyin naa ni Adajọ Emeka Nwite paṣẹ wi pe ki wọn ko wọn lọ si ahamọ lọgba ẹwọn Kuje, titi di asiko ti ile ẹjọ yoo fi ṣe agbeyẹwo beeli ti wọn n beere fun.
Lasiko ijọba Muhammadu Buhari ni Malami jẹ agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ ni Naijiria.
Adajọ Nwite paṣẹ wi pe ọjọ keji oṣu Kinni ọdun 2026 ni ile ẹjọ yoo gbọ awijare Malami atawọn meji yooku fun beeli.
Adajọ ni olujẹjọ kini ati ekeji yoo wa ni ahamọ lọgba ẹwọn Kuje, nigba ti olujẹjọ kẹta yoo wa lahamọ lọgba ẹwọn Suleja.















