Ìyàtọ̀ láàrin òfin owó orí tuntun tó wà lákọsílẹ̀ ìjọba àti èyí tílé aṣòfin buwọ́lù, ìdí táwọn aṣòfin fi figbe ta

Aarẹ Bola Tinubu wọ agbada alawọ buluu, o si tun de fila si i

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ ti ile igbimọ aṣofin l'Abuja sọ pe wi pe ofin owo ori tuntun ti ijọba apapọ ṣe akọsilẹ rẹ yatọ si eyi ti ile buwọlu ti jana bayii pẹlu ẹda ofin owo ori naa ti ile ti fi sita bayii.

Ẹda ofin owo ori tuntun naa, CTCs, lo ṣafihan ofin ti ile igbimọ aṣofin buwọlu ti wọn si gbe lọ siwaju Aarẹ Bola Tinubu fun ibuwọlu.

Lopin ọsẹ to kọja ni ile aṣoju-ṣofin l'Abuja fi ẹda ofin naa sita, eyi ti Aarẹ Tinubu buwọlu.

Eleyii waye lẹyin ti awọn kan ninu awọn aṣofin kọminu pe ijọba ti tọwọ bọ ofin owo ori ti ile gbe lọ siwaju aarẹ fun ibuwọlu.

Agbẹnusọ ile, Akin Rotimi, to fi ẹda ofin naa sita sọ pe adari ile aṣoju-ṣofin, Tajudeen Abbas ati Aarẹ ile igbimọ aṣofin l'Abuja, Godswill Akpabio lo paṣẹ wi pe koun fi ẹda ofin owo ori naa sita.

O ni awọn adari ile mejeeji sọ pe eyi ṣe pataki nitori oriṣiiriṣii ẹda ofin owo ori naa lo wa nita.

Ṣaaju ni aṣofin Abdulsamad Dasuki sọ pe kudiẹ-kudiẹ wa ninu ofin owo ori ti ijọba ṣe akọsilẹ rẹ, eyi to yatọ si ẹda ofin ti ile buwọlu.

Dasuki ni titọwọbọ ofin ti ile buwọlu tabuku agbara ile aṣofin agba niluu Abuja.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbeyẹwo ofin owo ori ti ijọba apapọ ṣe akọsilẹ rẹ fi han pe awọn kudiẹ-kudiẹ to wa ninu ẹda ofin owo ori to wa nita ni ko si ninu ofin ti ile aṣofin ṣiṣẹ le lori.

Lara ẹka ti kudiẹ-kudiẹ wa ni abala kẹta ofin naa, abala yii fun ajọ NRS lagbara lati ṣakoso owo ori ijọba apapọ to fi mọ owo ori lati ẹka epo rọbi ati VAT.

Abala yii ni wọn ṣakiyesi wi pe ko si ninu ofin owo ori ti ijọba apapọ ṣe akọsilẹ rẹ.

Ni ibomiran ti kudiẹ-kudiẹ tun wa ninu ofin naa ni abala mọkandinlọgbọn eyi to sọ nipa bawọn ile ifowopamọ yoo ṣe maa kede gbogbo owo to wọle fun wọn.

Ninu ẹda ofin naa ti ile aṣofin buwọlu, o yẹ kawọn ile ifowopamọ maa kede gbogbo owo to wọle fun wọn loṣooṣu.

Amọ, ọmọ ofin owo ori to wa ni akọsilẹ ijọba sọ pe ẹmẹrin lọdun ni awọn ile ifowopamọ gbọdọ maa kede owo to n wọle fun wọn.

Ni ibomiran ti iyatọ tun wa ni abala kọkandinlogoji eyi to da lori idi tawọn eeyan fi san owo ori.

Ẹda ofin ti ile igbimọ aṣofin ṣiṣẹ lori rẹ faye gba gbogbo owo ori to ni ṣe pẹlu epo rọbi wi pe ki wọn san an pẹlu irufẹ owo ti wọn fi ṣe okowo.

Amọ, ofin owo ori ti ijọba ṣe akọsilẹ rẹ sọ pe ki wọn maa san gbogbo owo ori lati ẹka epo rọbi pẹlu owo dọla.

Ofin owo ori ti ile buwọlu ni abala 64 fun ajọ to n ṣakoso owo ori lati ṣe iwadii ẹnikẹni to ba kọ lati sanwo ori rẹ.

Amọ, eyi to wa ni akọsilẹ ijọba fun ajọ to n ṣakoso owo lati lo awọn agbofinro lati mu ẹnikẹni to ba kọ lati sanwo ori.