Ọ̀rọ̀ Soun Ogbomoso àtí Ìmáàmù Àgbà tún ṣẹ́yọ, Iléẹjọ́ so Ìmáàmù lọ́wọ́kọ́ lórí ìfinjoyè, Soun ní ìkọjá-àyè ni

Oríṣun àwòrán, Imaamu Agba Ogbomoso/Facebook, Oba Ghandi Afolabi Olaoye/faceook
Ileẹjọ giga kan niluu Ibadan ti paṣẹ pe Imaamu Agba Ogbomoso, Alhaji Shekh Toliat Ayilara, ko le fi Sẹnẹtọ Hamzat Ayoade Adeseun ati Shaykh Idris Ibrahim Alao jẹ oye musulumi niluu Ogbomoso.
Lọsẹ to kọja ni Sheikh Ayilara fi oye Asiwaju/Baba Isale Adini ilẹ Ogbomoso da Sẹnẹtọ Adeseun to ṣoju ẹkun aarin gbungbun Oyo laarin ọdun 2011 si 2015 nile aṣofin agba l'Abuja lọla.
Bakan naa ni Imaamu Agba Ogbomoso tun foye Safīrul 'Ulama' ilẹ Ogbomoso da Shaykh Alao lọla.
Laipẹ yii ni Sheikh Ayilara sọ loju opo Facebook rẹ pe ''lẹyin ti a kirun Jimọh tan ni mo we lawani fun Sẹnẹtọ Hamzat Ayoade Adeseun gẹgẹ bii Asiwaju/Baba Isale Adini ilẹ Ogbomoso ati Shaykh Idris Ibrahim Alao gẹgẹ bii Safīrul 'Ulama' ilẹ Ogbomoso.
Mo gbadura pe ki Ọlọrun Allah ṣe ni irọrun fun wọn bi wọn ti bẹrẹ iṣẹ nipo tuntun yii l'Ogbomoso.''
Oni Ọjọbọ ọjọ kinni oṣu Karun un ọdun yii ni wọn fi ayẹyẹ idawọọ oye naa si.
Ṣugbọn lana Ọjọru ọgbọnjọ oṣu Kẹrin ni Adajọ K.A. Adedokun paṣẹ pe Imaamu Agba Ogbomoso ko le fi ẹnikan joye titi ti ẹjọ to pe Kabiyesi Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba Oba Ghandi Afolabi Olaoye Orumogege III yoo fi pari.
Adajọ ni fun idi eyi ni oun ṣe fagile oye ti Imaamu Ayilara fi Sẹnẹtọ Adeseun ati Shaykh Alao jẹ.
Ṣaaju ni Sheikh Ayilara atawọn mẹjọ mii gbe Soun atawọn mẹsan an kan lọ ileẹjọ wi pe ori ade naa fẹ yọ oun nipo.
Agbẹjọro awọn olujẹjọ kẹfa si ẹkẹẹwa, Kola Fatoye, lo rọ ile ẹjọ lati paṣẹ wi pe ki gbogbo awọn tọrọ kan ma ṣe gbe igbesẹ kankan titi ti igbẹjọ yoo fi pari.
Ẹbẹ yii ni adajọ gba ti o si fi paṣẹ pe Imaamu Ogbomoso ko le yan ẹnikankan sipo niwọn igba ti ẹjọ to pe Soun ko tii pari.
Soun fesi lori aṣẹ ileẹjọ

Oríṣun àwòrán, Imaamu Agba Ogbomoso/Facebook
Ẹwẹ, Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye, ti sọ pe aṣẹ ileẹjọ ko le jẹ ajoji si Sheikh Ayilara tori nnkan to mọ nipa rẹ ni.
Soun sọ fun iwe iroyin ogbomosoinsightonline.com wi pe ''oun ko fẹ sọrọ lọ titi lori aṣẹ ileẹjọ tori ọrọ si wa nileẹjọ.
Amọ, ohun to dara ni ileẹjọ ṣe nipa bo ti sọ fun Sheikh Toliat pe ko le fi ẹnikankan joye titi ti ẹjọ to wa nile ẹjọ yoo fi pari.
''Imaamu gan an funra rẹ mọ pe oun ko le fi eeyan joye lai gbaṣẹ lọwọ Soun.
Eyi wa ninu adehun to tọwọ bọ nigba to jẹ oye Imaamu Agba Ogbomoso.
Oloye ni o jẹ gẹgẹ bii Imaamu Agba, Soun lo si yan an sipo, nitori naa, idajọ ile ẹjọ gbọdọ ye e yekeyeke.''
Imaamu tabi ẹnikankan ko lagbara lati fi ẹnikẹni jẹ oye to ni ṣe pẹlu ''ilẹ Ogbomoso,'' ikọja aye ni.
Soun nikan lo lagbara lati fi ẹnikẹni jẹ iru oye bẹẹ, yala to ba ni ṣe pẹlu tabi oye ibilẹ,'' Ọba Ghandi lo sọ bẹẹ.















