Ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí ISWAP jẹ́wọ́ pé àwọn ló pa èèyàn 26 ní Borno, kí lèyí túmọ̀ sí fún àbò Nàìjíríà?

Aworan awọn agbebon to boju pẹlu ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Fun igba akọkọ lẹyin ọpọlọpọ ọdun, ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Islam, Islamic State's West Africa Province (ISWAP), ti jẹwọ pe awọn lawọn kọlu ipinlẹ Borno laipẹ yii, ti eeyan mẹrindinlọgbọn (26) fi dero ọrun.

Loju opo ayelujara Telegram wọn ni ISWAP ti jẹwọ pe ikọlu to pa awọn eeyan naa ko ṣẹyin awọn.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje ọsẹ yii ni ikọlu ọhun waye, nigba ti ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn kẹ ado oloro sinu rẹ bu gbamu lẹba ọna, lagbegbe Rann, ipinlẹ Borno.

Ọsẹ meji sẹyin ni ado oloro kan ti kọkọ bu gbamu lagbegbe naa, ti eeyan mẹjọ di oloogbe, awọn mọkanla si farapa.

Awọn ikọ Boko Haram ati ISWAP yii ni wọn ti n ṣọṣẹ lati nnkan bii ọdun mẹẹẹdogun sẹyin lapa Ila-Oorun Ariwa Naijiria.

Ọpọ igba ni wọn ti fi ado oloro pa araalu ati ẹṣọ alaabo, nigba ti wọn ba gbe ikọlu de.

Kí ló túmọ̀ sí lẹ́ka ààbò bí ISWAP ṣe jẹ́wọ́?

Nigba to n ṣalaye nipa bi ISWAP ṣe jẹwọ, Malam Kabiru Adamu, onimọ nipa eto aabo ni Naijiria ati lẹkun-un Sahel, sọ pe ikọlu naa ko jọ oun loju.

"Bi ikọlu yii ṣe lagbara to, ko jọ, nitori a ti ri bawọn ISWAP ati Boko Haram ṣe fi kun ikọlu wọn lọpọ agbegbe, titi kan lilo ado oloro ati ọna mi-in ti wọn n gba ṣiṣẹ wọn bayii "

"Koda, ikọlu to pa ọpọ eeyan yii jẹ iru eyi ti wọn maa ṣe ti wọn ba fẹẹ kọlu awọn ologun. 'Complex attacks', iyẹn ikọlu to lagbara ni wọn n pe e."

Malam Kabiru Adamu lo ṣalaye bẹẹ.

O ni ISWAP ati Boko Haram ti pada si Ariwa Borno, nibi ti wọn ti n ṣe ohun ti wọn fẹ ni ijọba ibilẹ mẹta.

Laipẹ yii ni Gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Umar Zulum, kọminu nipa ikọlu to n waye leralara bayii latọdọ awọn Boko Haram nipinlẹ naa.

Àwọn ológun Naijiria náà ti bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì

Ọga ologun tuntun, Abdusalam Abubakar

Oríṣun àwòrán, NDHQ/X

Lati koju awọn agbebọn yii, ileeṣẹ ologun Naijiria ti yan Ọgagun agba Abdulsalam Abubakar gẹgẹ bii olori ogun ikọ Operation Hadin-Kai, eyi to n koju ikọlu ni Ariwa-Ila-Oorun Naijiria.

Iyansipo Ọgagun Abubakar waye lẹyin ikọlu to n waye leralera lati nnkan bii oṣu mẹrin sẹyin.

Ki i ṣe pe ikọlu ọhun pa araalu rẹpẹtẹ nikan, ọpọ ṣọja lo tun ti ran lọ sọrun ojiji pẹlu.

Atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun Naijiria fi sita, ṣalaye pe Ọgagun Abdulsalam ni adari ẹlẹẹkẹẹdogun ti ikọ ologun Joint Task Force to n koju Boko Haram ati ISWAP yan ni ẹkun naa.

Ohun to foju han ni pe Boko Haram ati ISWAP ti tunra mu fun ikọlu to n waye leralera nibi ti wọn ti n ṣọṣẹ yii.

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa eto aabo sọ pe eyi ti mu ipaya ba awọn eeyan ibẹ.

Wọn ni o ṣee ṣe kawọn alakatakiti ti wọn n lo drone ati ado oloro ti wọn n kẹ si ẹgbẹ ọna yii tun pada wa.

Ṣé bí wọ́n ṣe yan olórí ogun tuntun lè yí nǹkan padà?

Malam Kabiru Adamu ninu alaye rẹ, sọ pe yiyan olori ogun tuntun ki i ṣe nnkan tuntun niru asiko yii.

Onimọ nipa aabo naa sọ pe ki eeyan too le yanju iṣoro kan, o gbọdọ mọ ipilẹ rẹ.

O rọ olori ogun tuntun naa lati mọ kulẹkulẹ ofin to n gbogun ti ikọlu ni Naijiria.

Mallam Kabiru rọ Ọgagun Abdulsalam Abubakar lati ko gbogbo awọn alẹnulọrọ ti ọrọ yii kan mọra.

O ni ki wọn jọ bẹrẹ igbesẹ ti yoo yanju ikọlu gbogbo igba naa.