Boko Haram fi àdò olóró gbẹ̀mí èèyàn 26, yìnbọn pa méje míràn ní Borno

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin tojade lati ẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria ti fi idi iṣẹlẹ ibugbamu to gba ẹmi eeyan mẹrindinlọgbọn ni ipinlẹ Borno lalẹ ọjọ Aje, mulẹ.
Ibugbamu naa waye nigba ti ọkọ wọn gun ori ado oloro kan to wa lẹgbẹ opopona ti wọn gba nitosi aala orilẹede Naijiria pẹlu Cameroun.
Ileeṣẹ akoroyinjọ Reuters ati AFP ni awọn eeyan kan lagbegbe naa ṣalaye pe awọn ọkunrin mẹrindinlogun, obinrin mẹrin atawọn ọmọde mẹfa lo wa lara awọn to fara kaasa iṣẹlẹ naa. Iroyin sọ pe ilu Rann ni ọkọ naa ti n bọ, to si n lọ si Gamboru Ngala lasiko to fi kọlu ado oloro naa.
Awọn olugbe agbegbe naa ti ko awọn to ṣeṣe lọ si ile iwosan, bi o tilẹ jẹ wi pe ikọ agbesunmọmi boko Haram lawọn olugbe agbegbe naa n na ika si pe wọn ṣe ọṣẹ naa. Amọṣa, ko tii si atẹjade kankan lati ọdọ ileeṣẹ alaabo kankan nipa iṣẹlẹ ibugbamu naa.
- Afurasí darandaran jí akẹ́kọ̀ọ́ fásítì mẹ́wàá tó ń lọ fún ìpàdé Ajinde gbé lọ, méjì fara gbọta, wọn ń bèèrè N15m lọ́wọ́ ẹbí
- "Kò sí ẹnìkankan tó ń gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ kan mọ́ torí Boko Haram, a kò le lọ ra oúnjẹ láì sí ológun lẹ́yìn wa, inú ìbẹ̀rù là ń gbé"
- Èèyàn mẹ́jọ kú, ọ̀pọ̀ farapa, bí ọkọ̀ wọn ṣe kọlù àdó olóró ní òpópónà márosẹ̀
- Àwọn afurasí agbébọn tún ṣekú pa èèyàn 40 míì ní Plateau nínú ìkọlù tuntun
Ni ọdun 2017, ọkọ baluu kan ṣeṣi ju ado oloro si ibudo ifiniwọsi awọn ogunlende kan ni ilu Rann yii kan naa, eyi to ran nnkan bii aadọta eeyan lọ sọrun., ti ọgọfa miran si tun farapa. Ilu Rann jẹ ibudo kan ti wọn n ko awọn ti ipenija ọrọ abo lẹkun ila oorun ariwa Naijiria ti sọ diatipo si ni agbegbe aala orilẹede NAijiria pẹlu Cameroun.
Ileeṣẹ ọmọogun ofurufu ni Naijiria fi idi rẹ mulẹ nigba naa pe awọn ọmọogun BokoHaram ni baluu ogun oun n wa lọ to fi ṣeṣi ju ado oloro si ilu naa lasiko ti awọn oṣiṣẹ ajọ aṣeranwọ n pin ounjẹ fun awọn aṣatipo nibẹ.
Ipinlẹ Borno ni ibuba awọn agbesunmọmi atawọn ẹgbẹ alakatakiti miran lorilẹede nAijiria. Ko si din ni ẹgbẹrun lọna ogoji eeyan ti wọn ti da ẹmi wọn legbodo laarin nnkan bi ọdun marundinlogun ti igbesunmọmi wọn ti bẹẹrẹ, eleyi to si ti sọ eeyan to le ni miliọnu meji di aṣatipo.
Boko Haram tun pa eeyan meje miran ni Borno

Oríṣun àwòrán, boko Haram
Bakan naa ninu ikọlu miran, awọn agbebọn Boko Haram tun pa awọn eeyan meje lasiko ti wọn kọlu ilu kan ti orukọ rẹ n jẹ Koful ni ijọba ibilẹ Chibok ni ipinlẹ Borno kan naa.
Lasiko ti awọn eeyan ilu naa n ṣe ọfọ eeyan kan ti wọn ṣẹṣẹ sin oku rẹ tan lawọn agbebọn naa ṣina ibọn bo awọn eeyan ilu naa ti wọn si tun da ina sun awọn ile ijọsin kan atawọn ile nibẹ.
Alaga ijọba ibilẹ Chibok, Mallam Modu Mustapha fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ pe nnkan bii agogo marun un ọirọlẹ ọjọ Aje ni ikọlu naa waye.
O ni o ti le ni oṣu meji ti awọn agbebọn Boko Haram ṣe ikọlu si agbegbe naa kẹyin, ki o to tun kọlu agbegbe naa lọjọ Aje.















