Ta làwọn ọmọ ilẹ̀ Africa mẹ́ta tó ti jẹ Póòpù ìjọ Àgùdà, kí lò dé tí aláwọ̀ dúdú kankan kò dépo náà mọ́ lẹ́yìn wọn?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Catherine Heathwood
- Role, BBC News Africa
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Iku to pa Poopu Francis ti jẹ ki awọn eeyan maa sọ pe ọmọ ilẹ Africa ni olori tuntun fun ijọ Aguda yoo jẹ.
Ṣugbọn ijọ naa ti ni awọn olori to jẹ ọmọ ilẹ Africa ri.
Gẹgẹ bawọn onpitan ṣe wi, poopu mẹta lo ti jẹ ri ti wọn ti orirun wọn jẹ ti Africa, eyi to sunmọ ju ninu wọn ni wọn ni iku rẹ ti le ni ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta (1,500 years ago.)
Ọmọ apa Ariwa Africa (North African) ni wọn. Aafin Romu naa tẹ pẹpẹ de Tunisia ode oni, Ariwa Algeria ati etikun Libya nigba naa.
Ki ẹsin Islam too de ni sẹnturi keje, ẹsin Kristẹni lo rẹsẹ walẹ ju ni gbogbo ẹkun naa.
Ọjọgbọn Christopher Bellitto, lati Yunifasiti Kean l'America, sọ fun BBC pe: "Ariwa Africa ni ọpakutẹlẹ ẹsin Kristẹni laye ọjọun."
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ko mọ nnkan pupọ nipa awọn poopu ọmọ Adulawọ yii, awọn onpitan gbagbọ pe wọn ṣiṣẹ takun-takun fun ijọ Aguda ti i ṣe Catholic .
Koda, awọn mẹtẹẹta ni wọn ka si ẹni mimọ (saints) ninu ijọ naa.
Victor I (AD189-199)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ibi ti a mọ si Berber ni igbagbọ wa pe Pope Victor I ti wa.
Oun lo n ṣakoso ṣọọṣi Katoliiki lasiko ti idaamu nla ba awọn Kristẹni ti wọn kọ lati maa bọ awọn oriṣa ilẹ Rome.
Ohun ti awọn eeyan mọ ọn fun ni pe o maa n ri i daju pe awọn Kristẹni ṣayẹyẹ Ajinde lọjọ Aiku.
Ni senturi keji, awọn ẹgbẹ Kristẹni kan lati Asia, sàmì Ajinde lọjọ kan naa ti awọn Jew n ṣayẹyẹ isin irekọja wọn, eyi ti wọn le ṣe lọjọ miran.
Awọn Kristẹni lapa Iwọ-Oorun gbagbọ pe ọjọ Aiku ni Jesu ji dide, fun idi eyi, ọjọ Sannde lo yẹ kawọn maa ṣe ọdun Ajinde.
Ọrọ naa di ariyanjiyan, Pope Victor I si pe awọn awọn olori ijọ.
O loun ko ni i jẹ ki ijọ ba awọn biṣọọbu to ba n tako ọjọ ajinde naa ṣe mọ.
"Ẹnikan to maa n fi aṣẹ ṣe ohun to ba fẹẹ ni."
Ọjọgbọn Bellitto lo sọ bẹẹ nipa poopu dudu naa.
O ni ohun iwuri leyi, nitori lasiko ti ẹsin Kristẹni jẹ eewọ ni Rome ni Pope Victor 1 n ṣakoso.
Nnkan pataki miran ti Victor I tun fi lele ti ko ṣee gbagbe, ni ti ede Latin to sọ di ede ajọlo awọn Katoliiki.
Tẹlẹ, ede Greek atijọ ni wọn n sọ ninu ijọ Aguda.
Victor I funra rẹ kọ o si sọ ede Latin, eyi ti wọn n sọ kari ni Ariwa Africa (North Africa).
Miltiades (AD311-314)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilẹ Africa ni igbagbọ wa pe wọn ti bi Pope Miltiades.
Lasiko rẹ, awọn eeyan tẹwọ gba ẹsin Kristẹni gan-an, to bẹẹ to fi di ẹsin ti wọn n ṣe kari.
Ṣaaju eyi, ifiyajẹni kekere kọ ni awọn Kristẹni ti koju ninu itan Rome.
Ṣugbọn Ọjọgbọn woye pe Militiades kọ lo mu ayipada wa, o ni poopu yii ri oju rere ilẹ Rome gba ni, oun kọ lo ja ija ominira.
Ọba Rome igba naa, Constantine, fun Miltiades ni aafin kan, eyi to sọ ọ di poopu akọkọ to ni ibugbe labẹ ofin.
Constantine tun fun un laye lati kọ ṣọọṣi Lateran, ile ijọsin naa lo si lọjọ lori julọ ni Rome lonii.
Nigba ti awọn poopu igbalode n ṣiṣẹ ti wọn si n gbe nibi ti a mọ si Vatican, wọn a maa pe ṣọọṣi Lateran yii ni " iya awọn ṣọọṣi " ninu ijọ Aguda.
Gelasius I (AD492-496)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gelasius I nikan ni poopu ilẹ Africa tawọn eeyan gbagbọ pe wọn ko bi silẹ Africa.
"Wọn maa n sọ pe ọmọ Roman ni, Fun idi eyi, a ko le sọ boya o gbe ni Africa, ṣugbọn o tun farahan pe ọmọ ilẹ Ariwa Africa ni"
Ọjọgbọn Bellitto lo ṣalaye bẹẹ.
Oun lo ṣe pataki ju ninu awọn poopu Adulawọ mẹta naa, bi Ọjọgbọn Bellitto ṣe sọ.
Gelasius I ni wọn n pe ni aṣoju Jesu.
Oun naa lo bẹrẹ ilana ida meji, eyi to n ṣafihan agbara ṣọọṣi ati ilu.
Gelasius I jẹ ko di mimọ pe Oluwa ti fun ṣoọṣi lagbara meji, ijọ ni yoo si pin in. Fun idi eyi, ijọ ju ilu lọ.
Poopu Gelasius naa lawọn eeyan tun mọ fun ayẹyẹ ọjọ ololufẹ ti wọn ṣi n ṣe laye di oni, eyi to maa n waye lọjọ kẹrinla, oṣu Keji ọdun.
Awọn akọsilẹ kan sọ pe alufaa ni Valentine, wọn ni oun lo maa n so awọn tọkọ-taya pọ ni kọrọ, nigba ti Emperor Claudius II ti fagile e.
Awọn onpitan gbagbọ pe ọjọ ololufẹ yii ni nnkan lati ṣe pẹlu pẹlu ọdun ọlọmọwẹwẹ, wọn lo kan awọn aboriṣa pẹlu.
Báwo ni awọn poopu Africa ṣe ri?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọgbọn Bellitto sọ pe ko si ọna kan gboogi ti eeyan fi le ṣalaye bi awọn poopu mẹta ilẹ Africa naa ṣe ri.
"O ye ka ranti aafin Rome, ati awọn asiko ọdun pipẹ ti wọn ko wo àwọ̀ bii ti ode oni ki wọn too yan poopu"
"Awọn eeyan Roman ko wo ti ẹya , wọn koju rẹ daadaa.
Ninu ọrọ Ọjọgbọn Philomena Mwaura, lati Yunifasiti Kenyatta, ni Nairobi, o ni aṣa pọ lapa Africa to tan mọ Rome.
Awọn ẹru ti wọn ti di ominira naa wa pẹlu.
O ni awọn eeyan to ba ti tan mọ apa Rome naa maa n ri ara wọn bii ọmọ Rome ni.
Kí ló dé tí kò sí póòpù Africa mọ́ látìgbà náà?
Lẹyin Gelasius I, ko tun si poopu kankan mọ ti itan rẹ jẹ mọ ti ilẹ Africa.
" Agbara bọ lọwọọ ṣọọṣi to wa ni Ariwa Africa nitori ọpọ ogun to dide si i, titi to fi mọ iparun agbala Rome, pẹlu bawọn Musulumi ṣe de si North Africa ni sẹnturi keje." Ọjọgbọn Mwaura lo sọ eyi.
Ṣugbọn awọn onimọ kan ṣalaye pe bi Islam ṣe pada gbilẹ ni ẹkun naa kọ lo fa a ti ko fi si poopu ọmọ ilẹ Africa mọ lati bii ẹgbẹrun meji ọdun sẹyin.
Ọjọgbọn Bellitto sọ pe awọn Italy lo sọ yiyan biṣọọbu di ohun ti awọn nikan n ṣe.
O ni ki poopu jade lati Asia tabi Africa ṣee ṣe bi a ba maa fi ri ọdun mẹwaa mi-in, nitori awọn ọmọ ijọ Aguda pọ ni Guusu pọ ju ti Ariwa lọ.
Koda, o ni ijọ Katoliiki n gbooro si i ni ẹkun-un Sahara ilẹ Africa ju ibikibi lọ.
Akọsilẹ tuntun fi han pe awọn ọmọ ijọ Aguda 281 miliọnu lo wa l'Africa ni 2023
Eyi si jẹ ida ogun ninu awọn ọmọ ijọ naa lagbaaye.
Gẹgẹ bo ṣe wi, Ọjọgbọn Mwaura sọ pe bo tilẹ jẹ pe ẹsin Kristẹni fi ẹsẹ mulẹ daadaa l'Africa, agbara ijọ naa ṣi wa ni Ariwa Africa, nibi ti nnkan amuṣorọ rẹ wa."
"Boya bo ṣe n lagbara si i laaarin awọn ẹka ile aye mi-in to tun wa to si n ran awọn rẹ lọwọ, boya igba kan yoo de ti poopu ọmọ ilẹ Africa yoo jade wa."
Ọjọgbọn Mwaura lo ṣalaye bẹẹ.














