NDIC bẹ̀rẹ̀ sísan owó fún àwọn tó fowópamọ́ sí Heritage Bank to kógbáwọlé

Aworan idanimọ Heritage Banki to kogba wọle pẹlu aworan idanimọ ileeṣẹ NDIC

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ adojutofo awọn banki lorilẹede NAijiria, NDIC ti kede pe awọn ti bẹrẹ sisan lara owo awọn eeyan ti owo wọn ṣi ha si inu bakni Heritage Bank to kogbawọle.

Owo ti ileeṣẹ adojutofo naa yoo san fun awọn onibara banki Heritage ti owo wọn ha to biliọnu mẹrindinlaadọta ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira 9N46.6b).

Atẹjade kan eyi to jade lati ileṣẹ NDIC sọ pe awọn ti owo ti wọn fi pamọ si banki naa ko ba ju miliọnu marun un Naira ni wọn ti I san owo fun.

Ni oṣu kẹfa ọdun 2024 ni banki apapọ Naijiria, CBN fagile iwe aṣẹ iṣiṣẹ Banki Heritage, o ni wọn tapa si ofin iṣuna lorilẹede NAijiria.

Gẹgẹbi atẹjade naa ṣe sọ, ni Ọjọ Ẹti to kọja ni ileeṣẹ NDIC bẹrẹ sisan owo naa " lati lee san owo pada fun gbogbo awọn to fi owo pamọ si banki naa."

Atẹjade naa ti Hawwau Gambo fọwọ si atẹjade kan to ṣalaye pe "ipele akọkọ sisan owo naa waye lẹyin ti wọn ta awọn dukia banki naa."