Ìdí rèé táwọn oníbàárà Báǹkì Heritage kò ṣe tíì rí owó wọn gbà - NDIC

Oríṣun àwòrán, Heritage bank/X
Àjọ tó ń mójútó owó tó wà ní akoto owó àwọn ilé ìfowópamọ́ ní Nàìjíríà ìyẹn Nigeria Deposit Insurance Corporation, NDIC ti ṣàlàyé ìdí tí àwọn kò ì tíì fi san owó àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ Heritage Bank kan.
NDIC ní nọ́ḿbà ìdánimọ̀ ilé ìfowópamọ́ báǹkì àwọn oníbàárà náà ìyẹn BVN wọn ní àwọn kùdìẹ̀kediẹ wà lórí rẹ̀ tó sì ń fa ìdádúrò sísan owó wọn.
Adarí àgbà NDIC, Bello Hassan ló ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fáwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Abuja lọ́jọ́ Àìkú.
Ó sọ pé láti ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹfà ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó àwọn oníbàárà náà padà fún wọn.
Hassan ní ọ̀pọ̀ àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ Heritage Bank tí kò ní ìṣòro pẹ̀lú BVN wọn ni àwọn ti san owó wọn padà fún.
Bello Hassan rọ gbogbo àwọn oníbàárà tó ní owó pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ Heritage Bank kí wọ́n tó kógbá sílé tí NDIC kò ì tíì san owó wọn sí akoto owó báǹkì wọn míì láti lọ sójú òpó NDIC lórí ayélujára láti lọ forúkọ sílẹ̀.
Bákan náà ló ní àwọn oníbàárà tí kò ní akoto owó pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ mìíràn náà gbọ́dọ̀ lọ forúkọ sílẹ̀ lórí ìtàkùn náà.
“BVN àwọn oníbàárà ni a ń lò láti fi san owó àwọn oníbàárà tí owó wọn wà pẹ̀lú ilé ìfowópamọ́ Heritage.
“A máa tọpinpin nọ́ḿbà BVN láti fi mọ ilé ìfowópamọ́ mìíràn tí wọn ń lò, a sì máa san owó wọn síbẹ̀.
“A gba àwọn oníbàárà tí kò ì tíì rí owó wọn gbà láti lọ forúkọ sílẹ̀ lórí ìtàkùn ayélujára wa kí a lè san owó wọn lásìkò.”
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn oníbàárà tó ní ju mílíọ̀nù márùn-ún náírà lọ pẹ̀lú ilé Jèhófà Heritage, Hassan ṣàlàyé pé tí àwọn bá ta àwọn dúkìá tí ilé ìfowópamọ́ Heritage ní, ni àwọn máa fi owó tí wọ́n bá pa níbẹ̀ san gbèsè wọn.
Hassan ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ta àwọn dúkìá náà, tí àwọn sì ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti láti gba àwọn owó tí àwọn èèyàn jẹ ilé ìfowópamọ́ náà gbà padà.
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn kò ní ní sùúrù kí àwọn ta gbogbo àwọn dúkìá náà kí àwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó àwọn oníbàárà ọ̀hún, ní kété tí àwọn bá ti ń tà á ni àwọn yóò máa san díẹ̀ díẹ̀.
Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹfà ni ile ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN gba ìwé àṣẹ ilé ìfowópamọ́ Heritage padà.
CBN ní ìgbésẹ̀ wáyé látàrí pé ilé ìfowópamọ́ Heritage kò ní agbára láti tẹ̀síwájú nídìí iṣẹ́ wọn.
Bákan náà ni wọ́n ní ìgbésẹ̀ ọ̀hún wáyé láti dá ààbò bo àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ náà.















