Wo ìdí tí iná mọ̀nàmọ́ná yóò fi lọ fún oṣù méjì l’Ondo àti Ekiti

Aworan oniṣẹ mọnamọna

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ajọ apinnaka lorilẹede yii ‘Transmission Company of Nigeria’ (TCN), ti kede pe ina mọnanọna ko ni i si ni ipinlẹ Ondo ati Ekiti fun awọn asiko kan, eyi yoo si ri bẹẹ fun oṣu meji gbako.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe ro o, TCN kede pe lati ọjọ kin-in-ni oṣu keje, si ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii ni ina ọba yoo fi mẹhẹ lawọn ipinlẹ mejeeji.

Ninu ikede naa ni wọn ti ṣalaye pe iṣẹ atunṣe ina mọnamọna to lagbara ni TCN fẹẹ ṣe loju opo amunawa Akure-Osogbo.

Wọn ni atunṣe naa ni i ṣe pẹlu riri waya kan ti wọn pe ni Optical Ground Wire (OPGW) ati awọn nnkan mi-in.

Ajọ naa tẹsiwaju pe bo tilẹ jẹ pe ai ni i si ina ọba yii yoo fa ọpọlọpọ nnkan sẹyin fun awọn ipinlẹ mejeeji, ṣugbọn yoo fun wọn ni anfaani lati ri ina lo daadaa si i lẹyin atunṣe ọhun.

Lori iye asiko ti ina yoo fi maa lọ fun oṣu meji yii, TCN sọ pe wakati mẹsan-an lojumọ ni yoo fi maa ri bẹẹ.

Wọn waa rọ awọn olugbe ipinlẹ to kan lati fọwọsowọpọ pẹlu ajọ naa, ki wọn si ri ikede to ṣiwaju igbesẹ naa bii ohun ti wọn yoo fi gbaradi de asiko ti ina ko fi ni i si.

TCN loun tọrọ aforiji lọwọ awọn onibaara, ki gbogbo ẹ le daa lawọn n ṣe.