Ìkọlù agbéṣùmọ̀mí gbẹ̀mí èèyàn mẹ́jọ, ọ̀pọ̀ èèyàn farapa níbi ìkọlù tuntun ní Borno

Awon omo ogu to n gbogunti igbesumomi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kò dín ní ènìyàn mẹ́jọ tó pàdánù ẹ̀mí wọn, tí àwọn ọgbọ̀n míì sì tún farapa báwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ṣèkọlù síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó ní ìpínlẹ̀ Borno.

Ọ̀kan lára àwọn afurasí agbéṣùmọ̀mí náà ni ìròyìn ní ó ṣokùnfà ikú ènìyàn mẹ́fà níbi ètò ìgbéyàwó kan lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà, ọdún 2024.

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Borno ṣàlàyé pé àwọn afurasí agbéṣùmọ̀mí náà ṣèkọlù síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, ìsìnkú àti ilé ìwòsàn ní ìlú Gwoza.

Láti bíi ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn ni ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram ti ń bá ìpínlẹ̀ Borno fínra.

Èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí náà, táwọn tó lé ní mílíọ̀nù méjì sì ti di aláìnílé lórí mọ́.

Agbenusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno, Nahum Daso sọ fún BBC News Pidgin pé àwọn obìnrin kan tó gbé ọmọdé lọ́wọ́ ló fi àdó olóró pa ara rẹ̀ àtàwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ní agbègbè Mararaba T Junction ní Gwoza.

Daso ṣàlàyé pé nǹkan bíi aago mẹ́ta ọ̀sán ni ìkọlù náà wáyé lásìkò tí àwọn èèyàn tó lọ ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan ń bọ̀ láti ibi ètò náà.

Ó ní obìnrin náà àti ọmọ tó gbé dání, tó fi mọ́ èèyàn márùn-ún míì ló pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìkọlù ọ̀hún.

Ó fi kun pé ìkọlù mìíràn wáyé níbi ètò ìsìnkú tí wọ́n ń ṣe fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù àkọ́kọ́.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ṣàlàyé pé ní nǹkan bíi wákàtí méjì tí ìkọlù àkọ́kọ́ wáyé ni afurasí agbéṣùmọ̀mí míì tún ṣe ìkọlù sáwọn tó ń ṣètò ìsìnkú fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù àkọ́kọ́.

Ó ní èèyàn kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìkọlù kejì tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì farapa.