Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ̀rùn tún ẹjọ́ Baba Ijesha dá

Ile ẹjọ Kotẹmilọrun, ẹka ti ipinlẹ Eko, ti fi idi idajọ ile ẹjọ giga, to ju gbajumọ oṣerekunrin, Olanrewaju James, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, si ẹwọn, mulẹ.
Bakan naa ni ile ẹjọ naa fagile awọn idajọ kan.
Ọdun 2022 ni ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ nipinlẹ Eko ju Baba Ijesha si ẹwọn, fun ẹsun pe o fi ipa ba ọmọbinrin, ọmọ ọdun mẹrinla lo pọ.
Oríṣi ẹsun mẹfa ni ijọba ipinlẹ Eko fi kan Ọgbẹni Olanrewaju.
Awọn ẹsun naa nii ṣe pẹlu:
- Hihu iwa ti ko tọọ si ọmọde
- Ibalopọ
- Igbiyanju lati ba ọmọde lo pọ ni oju ara rẹ
- Biba ọmọde lopọ loju ara rẹ
Ṣugbọn lẹyin idajọ naa ni Baba Ijesha pe ẹjọ Kotẹmilọrun, lati tako idajọ ti wọn fun.
Ọjọ Ẹti ni ile ẹjọ Kotẹmilọrun gbe idajọ rẹ kalẹ.
Adajọ to lewaju igbẹjọ Kotẹmilọrun naa lọjọ Ẹti, sọ pe Baba Ijesha jẹbi ẹsun kẹrin ati ikarun-un, eyi to nii ṣe pẹlu fifi ọwọ kan ọmọde lọna ti ko boju mu, to si tun fi ipa baa lopọ.
Onidajọ Oluwatoyin Taiwo, to gbọ ẹjọ Baba Ijesha lọdun 2022, da ẹjọ ẹwọn ọdun marun-un fun biba ọmọde lopọ, lọjọ kẹrinla, oṣu Keje, 2022.
Ile ẹjọ naa rii pe Baba Ijesha jẹbi hihu iwa ti ko boju mu si ọmọde, to si tun balopọ laarin ọdun 2013 si 2014. Eyi to tako ofin ipinlẹ Eko, ti ọdun 2015, lori iwa ọdaran.
Ṣugbọn ile ẹjọ ni ko jẹbi ẹsun fifi kọkọrọ ọkọ̀ rẹ sinu oju ara ọmọ naa lọdun 2013, ati igbiyanju lati baa lopọ lọdun lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021.
Adajọ sọ pe o jẹbi o gbe ọmọdebinrin naa sori itan rẹ, to si fi nnkan ọmọkunrin rẹ paa lara.
Idajọ ti wọn fun Baba Ijesha ko dun mọ ninu, eyi to mu ko lọ sile ẹjọ Kotẹmilọrun. O fẹ ki ile ẹjọ naa fagile igbẹjọ ati idajọ ẹwọn ti wọn fun.
Agbẹjọro fun Baba Ijesha, Kayode Olabiran sọ pe agbẹjọro ijọba ko ni ẹri to fidi rẹ mulẹ pe, onibara oun fi ipa ba ọmọbinrin naa lo pọ.
Olabiran sọ pe "wọn dẹ pakute silẹ fun ni.
" Oṣere ni (Baba Ijesha), iwe itan ti akẹẹgbẹ rẹ, Damilola Adekoya (ẹlẹri) pe e si lati kopa ninu rẹ, lo fi ṣe ere ti wọn sọ di ẹsun."
Ile ẹjọ Kotẹmilọrun fagile idajọ
Ninu idajọ to ṣe lọjọ Ẹti, Onidajọ Folashade Ojo, fagile idajọ ti ile ẹjọ akọkọ da fun Baba Ijesha lori ẹsun hihu iwa ti ko boju mu si ọmọde, ati fifi ipa ba ọmọde lo pọ, ti wọn lo waye laarin ọdun 2013 si 2014. Adajọ sọ pe gbọyi-sọyi, ahesọ ọrọ lasan-lasan ni ẹjọ ti ajẹri, Damilola Adekoya, ro nile ẹjọ. Amọ lori iṣẹlẹ to waye ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, Onidajọ Ojo sọ pe ẹri ti Damilola Adekoya fihan nile ẹjọ, wa latara pe iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ. O ni ẹri naa fidi mulẹ, o si jẹ ara ọna to tọ̀nà julọ lati fidi ẹsun mulẹ. Yatọ si eyi, adajọ tun sọ pe Baba Ijesha finu-findọ fi ẹnu ara rẹ jẹwọ lori iṣẹlẹ naa, ti ko si tun tako ọrọ ti Damilola Adekoya sọ nile ẹjọ. "Olujẹjọ tun fi ẹnu ara rẹ sọ ọrọ to ran igbẹjọ lọwọ, ni agọ ọlọpaa Sabo, Yaba, nipinlẹ Eko, lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021. " O tun sọ ọrọ mii ni ẹ̀ka ileeṣẹ ọlọpaa to n wadii iwa ọdaran, Panti, lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, eyi to duro gẹgẹ bi ẹri. Adajọ ṣalaye pe Baba Ijesha, nipasẹ àwọn nnkan to sọ, gba pe oun fi ọwọ kan ọmọbinrin naa lọna ti ko boju mu, to si tun balo pọ, lasiko ti wọn jọ da wa nile Damilola Adekoya.
Idajo tuntun
Lakootan, adajọ sọ pe ẹjọ Kotẹmilọrun ti Baba Ijesha pe, yọri lapa kan, ko si yọri lapa keji. Bi idajọ tuntun ṣe ri: Adajọ fagile idajọ ati ẹwọn ọdun marun-un ti ile ẹjọ akọkọ fun Baba Ijesha fun ẹsun fifi ọwọ kan ọmọdebinrin naa lọna ti ko boju mu. Eyi ni ẹsun keji. Adajọ fagile idajọ ẹwọn ọdun mẹta fun ẹsun fifi ipa ba ọmọde lo pọ (ẹsun kẹta). Adajọ fi ontẹ lu idajọ ati ẹwọn ọdun marun-un fun ẹsun hihu iwa ti ko tọ si ọmọde (ẹsun kẹrin) Adajọ fi ontẹ lu idajọ ati ẹwọn ọdun marun-un fun ifipa banilopọ. Onidajọ Ojo sọ pe Baba Ijesha yoo ṣe ẹwọn fun ẹsun kẹrin (ọdun marun-un) ati ẹsun karun-un (ọdun mẹta) papọ ni.












